Súrà Al-Bayyina البينة
8 verses · Medina · revelation order 100
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ لَمْ يَكُنِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مِنْ أَهْلِ ٱلْكِتَٰبِ وَٱلْمُشْرِكِينَ مُنفَكِّينَ حَتَّىٰ تَأْتِيَهُمُ ٱلْبَيِّنَةُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn kò níí kúrò nínú àìgbàgbọ́ wọn títí di ìgbà tí ẹ̀rí tó yanjú yó fi máa dé ọ̀dọ̀ wọn.
See all translations of this verse →
رَسُولٌ مِّنَ ٱللَّهِ يَتْلُوا۟ صُحُفًا مُّطَهَّرَةً
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÒjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu yó (sì) máa ké àwọn tákàdá mímọ́.
See all translations of this verse →
فِيهَا كُتُبٌ قَيِّمَةٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ìwé òfin tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ sì wà nínú rẹ̀.
See all translations of this verse →
وَمَا تَفَرَّقَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَٰبَ إِلَّا مِنۢ بَعْدِ مَا جَآءَتْهُمُ ٱلْبَيِّنَةُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tí A fún ní tírà kò sì di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ẹ̀rí tó yanjú dé bá wọn.
See all translations of this verse →
وَمَآ أُمِرُوٓا۟ إِلَّا لِيَعْبُدُوا۟ ٱللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ حُنَفَآءَ وَيُقِيمُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤْتُوا۟ ٱلزَّكَوٰةَ وَذَٰلِكَ دِينُ ٱلْقَيِّمَةِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwa kò sì pa wọ́n ní àṣẹ kan bí kò ṣe pé kí wọ́n jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn fún Un,[1] lẹ́ni tí yóò dúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn. Kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì yọ Zakāh. Ìyẹn sì ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.
See all translations of this verse →
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مِنْ أَهْلِ ٱلْكِتَٰبِ وَٱلْمُشْرِكِينَ فِى نَارِ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أُو۟لَٰٓئِكَ هُمْ شَرُّ ٱلْبَرِيَّةِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (wọ̀nyí) nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn yóò wà nínú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹ̀dá tó burú jùlọ.
See all translations of this verse →
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ أُو۟لَٰٓئِكَ هُمْ خَيْرُ ٱلْبَرِيَّةِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo (ìyẹn, àwọn mùsùlùmí), tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹ̀dá tó dára jùlọ.
See all translations of this verse →
جَزَآؤُهُمْ عِندَ رَبِّهِمْ جَنَّٰتُ عَدْنٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدًا رَّضِىَ ٱللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا۟ عَنْهُ ذَٰلِكَ لِمَنْ خَشِىَ رَبَّهُۥ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀san wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Allāhu yọ́nú sí wọn. Àwọn náà yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ìyẹn wà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá páyà Olúwa rẹ̀.
See all translations of this verse →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→