Ojúewé ìbẹ̀rẹ̀ › Àwọn Súrà › Súrà At-Taghaabun
Súrà At-Taghaabun التغابن
18 verses · Medina · revelation order 108
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ يُسَبِّحُ لِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ لَهُ ٱلْمُلْكُ وَلَهُ ٱلْحَمْدُ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ قَدِيرٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu. TiRẹ̀ ni ìjọba. TiRẹ̀ sì ni ẹyìn. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
See all translations of this verse →
هُوَ ٱلَّذِى خَلَقَكُمْ فَمِنكُمْ كَافِرٌ وَمِنكُم مُّؤْمِنٌ وَٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín. Aláìgbàgbọ́ wà nínú yín. Onígbàgbọ́ òdodo sì wà nínú yín. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ بِٱلْحَقِّ وَصَوَّرَكُمْ فَأَحْسَنَ صُوَرَكُمْ وَإِلَيْهِ ٱلْمَصِيرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ya àwòrán yín. Ó sì ṣe àwọn àwòrán yín dáradára. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
See all translations of this verse →
يَعْلَمُ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَيَعْلَمُ مَا تُسِرُّونَ وَمَا تُعْلِنُونَ وَٱللَّهُ عَلِيمٌۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ó mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
See all translations of this verse →
أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَبَؤُا۟ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ مِن قَبْلُ فَذَاقُوا۟ وَبَالَ أَمْرِهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ṣé ìró àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ìṣáájú kò tí ì dé ba yín ni? Nítorí náà, wọ́n tọ́ ìyà ọ̀ràn wọn wò. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
See all translations of this verse →
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُۥ كَانَت تَّأْتِيهِمْ رُسُلُهُم بِٱلْبَيِّنَٰتِ فَقَالُوٓا۟ أَبَشَرٌ يَهْدُونَنَا فَكَفَرُوا۟ وَتَوَلَّوا۟ وَّٱسْتَغْنَى ٱللَّهُ وَٱللَّهُ غَنِىٌّ حَمِيدٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. Wọ́n sì wí pé: “Ṣé abara l’ó máa fi ọ̀nà mọ̀ wá?” Nítorí náà, wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Wọ́n sì pẹ̀yìndà (sí òdodo). Allāhu sì rọrọ̀ láì sí àwọn. Àti pé Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
See all translations of this verse →
زَعَمَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ أَن لَّن يُبْعَثُوا۟ قُلْ بَلَىٰ وَرَبِّى لَتُبْعَثُنَّ ثُمَّ لَتُنَبَّؤُنَّ بِمَا عَمِلْتُمْ وَذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé A ò níí gbé wọn dìde. Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, mo fi Olúwa mi búra, dájúdájú Wọn yóò gbe yín dìde. Lẹ́yìn náà, Wọn yóò fún yín ní ìró ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.”
See all translations of this verse →
فَـَٔامِنُوا۟ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَٱلنُّورِ ٱلَّذِىٓ أَنزَلْنَا وَٱللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ tí A sọ̀kalẹ̀. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
يَوْمَ يَجْمَعُكُمْ لِيَوْمِ ٱلْجَمْعِ ذَٰلِكَ يَوْمُ ٱلتَّغَابُنِ وَمَن يُؤْمِنۢ بِٱللَّهِ وَيَعْمَلْ صَٰلِحًا يُكَفِّرْ عَنْهُ سَيِّـَٔاتِهِۦ وَيُدْخِلْهُ جَنَّٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدًا ذَٰلِكَ ٱلْفَوْزُ ٱلْعَظِيمُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ní ọjọ́ tí (Allāhu) yóò ko yín jọ fún ọjọ́ àkójọ. Ìyẹn ni ọjọ́ èrè àti àdánù.[1] Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Allāhu gbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (Allāhu) yóò pa àwọn àṣìṣe rẹ̀ rẹ́ fún un. Ó sì máa mú un wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
See all translations of this verse →
وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَكَذَّبُوا۟ بِـَٔايَٰتِنَآ أُو۟لَٰٓئِكَ أَصْحَٰبُ ٱلنَّارِ خَٰلِدِينَ فِيهَا وَبِئْسَ ٱلْمَصِيرُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìkángun náà sì burú.
See all translations of this verse →
مَآ أَصَابَ مِن مُّصِيبَةٍ إِلَّا بِإِذْنِ ٱللَّهِ وَمَن يُؤْمِنۢ بِٱللَّهِ يَهْدِ قَلْبَهُۥ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àdánwò kan kò lè ṣẹlẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu ní òdodo, Allāhu máa fi ọkàn rẹ̀ mọ̀nà.[1] Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
See all translations of this verse →
وَأَطِيعُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُوا۟ ٱلرَّسُولَ فَإِن تَوَلَّيْتُمْ فَإِنَّمَا عَلَىٰ رَسُولِنَا ٱلْبَلَٰغُ ٱلْمُبِينُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Kí ẹ tẹ̀lé ti Allāhu. Kí ẹ sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá gbúnrí, ìkede ẹ̀sìn tó yanjú ni ojúṣe Òjíṣẹ́ Wa.
See all translations of this verse →
ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ ٱلْمُؤْمِنُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
See all translations of this verse →
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِنَّ مِنْ أَزْوَٰجِكُمْ وَأَوْلَٰدِكُمْ عَدُوًّا لَّكُمْ فَٱحْذَرُوهُمْ وَإِن تَعْفُوا۟ وَتَصْفَحُوا۟ وَتَغْفِرُوا۟ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọ̀tá wà fún yín nínú àwọn ìyàwó yín àti àwọn ọmọ yín. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra fún wọn. Tí ẹ bá ṣàmójúkúrò, tí ẹ ṣàfojúfò, tí ẹ sì ṣàforíjìn (fún wọn), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
See all translations of this verse →
إِنَّمَآ أَمْوَٰلُكُمْ وَأَوْلَٰدُكُمْ فِتْنَةٌ وَٱللَّهُ عِندَهُۥٓ أَجْرٌ عَظِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ìfòòró ni àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín. Allāhu sì ni ẹ̀san ńlá wà ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
See all translations of this verse →
فَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ مَا ٱسْتَطَعْتُمْ وَٱسْمَعُوا۟ وَأَطِيعُوا۟ وَأَنفِقُوا۟ خَيْرًا لِّأَنفُسِكُمْ وَمَن يُوقَ شُحَّ نَفْسِهِۦ فَأُو۟لَٰٓئِكَ هُمُ ٱلْمُفْلِحُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ẹ bá ṣe lágbára mọ. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ (Allāhu), ẹ tẹ̀lé e, kí ẹ sì náwó (fún ẹ̀sìn Rẹ̀) lóore jùlọ fún ẹ̀mí yín. Ẹnikẹ́ni tí A bá ṣọ́ níbi ahun àti ọ̀kánjúà inú ẹ̀mí rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè.
See all translations of this verse →
إِن تُقْرِضُوا۟ ٱللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا يُضَٰعِفْهُ لَكُمْ وَيَغْفِرْ لَكُمْ وَٱللَّهُ شَكُورٌ حَلِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Tí ẹ bá yá Allāhu ní dúkìá tó dára, Ó máa ṣàdìpèlé rẹ̀ fún yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Ọlọ́pẹ́[1], Aláfaradà,
See all translations of this verse →
عَٰلِمُ ٱلْغَيْبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ ٱلْعَزِيزُ ٱلْحَكِيمُ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
See all translations of this verse →
← Súrà Al-Munaafiqoon
Súrà At-Talaaq →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→
Arabic text and translations via Tanzil and QuranEnc — verbatim, unmodified · Translations belong to their translators and are not the Qur'an itself
This is a research aid, not a source of religious rulings.