Ojúewé ìbẹ̀rẹ̀ › Àwọn Súrà › Súrà Al-Munaafiqoon
Súrà Al-Munaafiqoon المنافقون
11 verses · Medina · revelation order 104
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِذَا جَآءَكَ ٱلْمُنَٰفِقُونَ قَالُوا۟ نَشْهَدُ إِنَّكَ لَرَسُولُ ٱللَّهِ وَٱللَّهُ يَعْلَمُ إِنَّكَ لَرَسُولُهُۥ وَٱللَّهُ يَشْهَدُ إِنَّ ٱلْمُنَٰفِقِينَ لَكَٰذِبُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí bá wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n á wí pé: “À ń jẹ́rìí pé dájúdájú ìwọ, Òjíṣẹ́ Allāhu ni ọ́.” Allāhu sì mọ̀ pé dájúdájú ìwọ, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ọ́. Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, òpùrọ́ ni wọ́n.
See all translations of this verse →
ٱتَّخَذُوٓا۟ أَيْمَٰنَهُمْ جُنَّةً فَصَدُّوا۟ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ إِنَّهُمْ سَآءَ مَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n fi àwọn ìbúra wọn ṣe ààbò (fún ẹ̀mí ara wọn), wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu; dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
See all translations of this verse →
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ ءَامَنُوا۟ ثُمَّ كَفَرُوا۟ فَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَفْقَهُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael (Wọ́n ṣe) ìyẹn nítorí pé, wọ́n gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, A ti fi èdídí dí ọkàn wọn; wọn kò sì níí gbọ́ àgbọ́yé.
See all translations of this verse →
وَإِذَا رَأَيْتَهُمْ تُعْجِبُكَ أَجْسَامُهُمْ وَإِن يَقُولُوا۟ تَسْمَعْ لِقَوْلِهِمْ كَأَنَّهُمْ خُشُبٌ مُّسَنَّدَةٌ يَحْسَبُونَ كُلَّ صَيْحَةٍ عَلَيْهِمْ هُمُ ٱلْعَدُوُّ فَٱحْذَرْهُمْ قَٰتَلَهُمُ ٱللَّهُ أَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Nígbà tí o bá rí wọn, ìrísí wọn yóò jọ ọ́ lójú. Tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, ìwọ yóò tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n sì dà bí igi tí wọ́n gbé ti ògiri.[1] Wọ́n sì ń lérò pé gbogbo igbe (ìbòsí) ń bẹ lórí wọn (nípa ìṣọ̀bẹ-ṣèlu wọn).² Ọ̀tá ni wọ́n. Nítorí náà, ṣọ́ra fún wọn. Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
See all translations of this verse →
وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا۟ يَسْتَغْفِرْ لَكُمْ رَسُولُ ٱللَّهِ لَوَّوْا۟ رُءُوسَهُمْ وَرَأَيْتَهُمْ يَصُدُّونَ وَهُم مُّسْتَكْبِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àti pé nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ wá kí Òjíṣẹ́ ba yín tọrọ àforíjìn.” Wọ́n á gbúnrí. O sì máa rí wọn tí wọn yóò máa gbúnrí lọ, tí wọn yóò máa ṣègbéraga.
See all translations of this verse →
سَوَآءٌ عَلَيْهِمْ أَسْتَغْفَرْتَ لَهُمْ أَمْ لَمْ تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ لَن يَغْفِرَ ٱللَّهُ لَهُمْ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهْدِى ٱلْقَوْمَ ٱلْفَٰسِقِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Bákan náà ni fún wọn; yálà o bá wọn tọrọ àforíjìn tàbí o ò bá wọn tọrọ àforíjìn.[1] Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Dájúdájú Allāhu kò nií fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
See all translations of this verse →
هُمُ ٱلَّذِينَ يَقُولُونَ لَا تُنفِقُوا۟ عَلَىٰ مَنْ عِندَ رَسُولِ ٱللَّهِ حَتَّىٰ يَنفَضُّوا۟ وَلِلَّهِ خَزَآئِنُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَلَٰكِنَّ ٱلْمُنَٰفِقِينَ لَا يَفْقَهُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Àwọn ni àwọn tó ń wí pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ ná owó fún àwọn tó wà lọ́dọ̀ Ójíṣẹ́ Allāhu títí wọn yóò fi fọ́nká. Ti Allāhu sì ni àwọn ilé ọrọ̀ sánmọ̀ àti ilẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò gbọ́ àgbọ́yé.
See all translations of this verse →
يَقُولُونَ لَئِن رَّجَعْنَآ إِلَى ٱلْمَدِينَةِ لَيُخْرِجَنَّ ٱلْأَعَزُّ مِنْهَا ٱلْأَذَلَّ وَلِلَّهِ ٱلْعِزَّةُ وَلِرَسُولِهِۦ وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَلَٰكِنَّ ٱلْمُنَٰفِقِينَ لَا يَعْلَمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Wọ́n ń wí pé: “Dájúdájú tí a bá padà dé sínú ìlú Mọdīnah, ńṣe ni àwọn alágbára (ìlú) yóò yọ àwọn ẹni yẹpẹrẹ jáde kúrò nínú ìlú.” Agbára sì ń jẹ́ ti Allāhu, àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò mọ̀.
See all translations of this verse →
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تُلْهِكُمْ أَمْوَٰلُكُمْ وَلَآ أَوْلَٰدُكُمْ عَن ذِكْرِ ٱللَّهِ وَمَن يَفْعَلْ ذَٰلِكَ فَأُو۟لَٰٓئِكَ هُمُ ٱلْخَٰسِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín kó àìrójú ba yín níbi ìrántí Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kó sínú (àìrójú) yẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.
See all translations of this verse →
وَأَنفِقُوا۟ مِن مَّا رَزَقْنَٰكُم مِّن قَبْلِ أَن يَأْتِىَ أَحَدَكُمُ ٱلْمَوْتُ فَيَقُولَ رَبِّ لَوْلَآ أَخَّرْتَنِىٓ إِلَىٰٓ أَجَلٍ قَرِيبٍ فَأَصَّدَّقَ وَأَكُن مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Ẹ ná nínú ohun tí A pèsè fún yín ṣíwájú kí ikú tó dé bá ẹnì kan yín, kí ó wá wí pé: “Olúwa mi, kí ó sì jẹ́ pé O lọ́ mi lára sí i títí di ìgbà kan tó súnmọ́, èmi ìbá sì lè máa tọrẹ, èmi ìbá sì wà lára àwọn ẹni rere.”
See all translations of this verse →
وَلَن يُؤَخِّرَ ٱللَّهُ نَفْسًا إِذَا جَآءَ أَجَلُهَا وَٱللَّهُ خَبِيرٌۢ بِمَا تَعْمَلُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael Allāhu kò sì níí lọ́ ẹ̀mí kan lára nígbà tí ọjọ́ ikú rẹ̀ bá dé. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
See all translations of this verse →
← Súrà Al-Jumu'a
Súrà At-Taghaabun →
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
→
Arabic text and translations via Tanzil and QuranEnc — verbatim, unmodified · Translations belong to their translators and are not the Qur'an itself
This is a research aid, not a source of religious rulings.