caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Muhammad محمد

38 verses · Medina · revelation order 95

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَصَدُّوا۟ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ أَضَلَّ أَعْمَٰلَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà Allāhu, (Allāhu) máa sọ iṣẹ́ wọn di òfò.

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَءَامَنُوا۟ بِمَا نُزِّلَ عَلَىٰ مُحَمَّدٍ وَهُوَ ٱلْحَقُّ مِن رَّبِّهِمْ كَفَّرَ عَنْهُمْ سَيِّـَٔاتِهِمْ وَأَصْلَحَ بَالَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n tún gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, òhun sì ni òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (Allāhu) máa pa àwọn (iṣẹ́) aburú wọn rẹ́, Ó sì máa ṣe àtúnṣe ọ̀rọ̀ wọn sí dáadáa.

See all translations of this verse →

ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ ٱتَّبَعُوا۟ ٱلْبَٰطِلَ وَأَنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ٱتَّبَعُوا۟ ٱلْحَقَّ مِن رَّبِّهِمْ كَذَٰلِكَ يَضْرِبُ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ أَمْثَٰلَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí pé, dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ tẹ̀lé irọ́. Àti pé dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ tẹ̀lé òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi àpèjúwe wọn lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn.

See all translations of this verse →

فَإِذَا لَقِيتُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ فَضَرْبَ ٱلرِّقَابِ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَثْخَنتُمُوهُمْ فَشُدُّوا۟ ٱلْوَثَاقَ فَإِمَّا مَنًّۢا بَعْدُ وَإِمَّا فِدَآءً حَتَّىٰ تَضَعَ ٱلْحَرْبُ أَوْزَارَهَا ذَٰلِكَ وَلَوْ يَشَآءُ ٱللَّهُ لَٱنتَصَرَ مِنْهُمْ وَلَٰكِن لِّيَبْلُوَا۟ بَعْضَكُم بِبَعْضٍ وَٱلَّذِينَ قُتِلُوا۟ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ فَلَن يُضِلَّ أَعْمَٰلَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, nígbà tí ẹ bá pàdé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (lójú ogun ẹ̀sìn), ẹ máa bẹ́ wọn lọ́rùn ǹsó títí di ìgbà tí ẹ máa fi rí wọn pa dáadáa. (Nígbà tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n tán), ẹ dè wọ́n mọ́lẹ̀ sórí ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, ẹ lè tú wọn sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ tàbí kí ẹ tú wọn sílẹ̀ pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀ títí kò fi níí sí ogun ẹ̀sìn mọ́.1 Ìyẹn (wà bẹ́ẹ̀). Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá gbẹ̀san fúnra Rẹ̀ (láì níí la ogun lọ), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dán apá kan yín wò lára apá kan ni. Àwọn mùsùlùmí tí wọ́n sì pa sí ojú-ọ̀nà Allāhu, Allāhu kò níí sọ iṣẹ́ wọn dòfo.

See all translations of this verse →

سَيَهْدِيهِمْ وَيُصْلِحُ بَالَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ máa fi ọ̀nà (Ọgbà Ìdẹ̀ra) mọ̀ wọ́n. Ó sì máa tún ọ̀rọ̀ wọn ṣe sí dáadáa.

See all translations of this verse →

وَيُدْخِلُهُمُ ٱلْجَنَّةَ عَرَّفَهَا لَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ máa fi wọ́n wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí Ó ti fi mọ̀ wọ́n.[1]

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِن تَنصُرُوا۟ ٱللَّهَ يَنصُرْكُمْ وَيُثَبِّتْ أَقْدَامَكُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá ran (ẹ̀sìn) Allāhu lọ́wọ́, (Allāhu) máa ràn ẹ̀yin náà lọ́wọ́. Ó sì máa mú ẹsẹ̀ yín dúró ṣinṣin (nínú ẹ̀sìn).

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ فَتَعْسًا لَّهُمْ وَأَضَلَّ أَعْمَٰلَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ṣàì gbàgbọ́, ìparun ni fún wọn. (Allāhu) sì máa sọ iṣẹ́ wọn di òfò.

See all translations of this verse →

ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَرِهُوا۟ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فَأَحْبَطَ أَعْمَٰلَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n kórira ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, (Allāhu) sì ba iṣẹ́ wọn jẹ́.

See all translations of this verse →

أَفَلَمْ يَسِيرُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ فَيَنظُرُوا۟ كَيْفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ دَمَّرَ ٱللَّهُ عَلَيْهِمْ وَلِلْكَٰفِرِينَ أَمْثَٰلُهَا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Allāhu pa wọ́n rẹ́. Irú rẹ̀ tún wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.

See all translations of this verse →

ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ مَوْلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَأَنَّ ٱلْكَٰفِرِينَ لَا مَوْلَىٰ لَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́, kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱللَّهَ يُدْخِلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ جَنَّٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَٰرُ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ يَتَمَتَّعُونَ وَيَأْكُلُونَ كَمَا تَأْكُلُ ٱلْأَنْعَٰمُ وَٱلنَّارُ مَثْوًى لَّهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Allāhu yóò fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn ń gbádùn, wọ́n sì ń jẹ (kiri) gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹran-ọ̀sìn ṣe ń jẹ (kiri). Iná sì ni ibùgbé fún wọn.

See all translations of this verse →

وَكَأَيِّن مِّن قَرْيَةٍ هِىَ أَشَدُّ قُوَّةً مِّن قَرْيَتِكَ ٱلَّتِىٓ أَخْرَجَتْكَ أَهْلَكْنَٰهُمْ فَلَا نَاصِرَ لَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMélòó mélòó nínú àwọn (ará) ìlú tí ó lágbára ju (ará) ìlú rẹ, tí ó lé ọ jáde, tí A sì ti pa wọ́n rẹ́. Kò sì sí alárànṣe kan fún wọn.

See all translations of this verse →

أَفَمَن كَانَ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِّن رَّبِّهِۦ كَمَن زُيِّنَ لَهُۥ سُوٓءُ عَمَلِهِۦ وَٱتَّبَعُوٓا۟ أَهْوَآءَهُم

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelǸjẹ́ ẹni tí ó wà lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀, ṣé ó dà bí ẹni tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn?

See all translations of this verse →

مَّثَلُ ٱلْجَنَّةِ ٱلَّتِى وُعِدَ ٱلْمُتَّقُونَ فِيهَآ أَنْهَٰرٌ مِّن مَّآءٍ غَيْرِ ءَاسِنٍ وَأَنْهَٰرٌ مِّن لَّبَنٍ لَّمْ يَتَغَيَّرْ طَعْمُهُۥ وَأَنْهَٰرٌ مِّنْ خَمْرٍ لَّذَّةٍ لِّلشَّٰرِبِينَ وَأَنْهَٰرٌ مِّنْ عَسَلٍ مُّصَفًّى وَلَهُمْ فِيهَا مِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ وَمَغْفِرَةٌ مِّن رَّبِّهِمْ كَمَنْ هُوَ خَٰلِدٌ فِى ٱلنَّارِ وَسُقُوا۟ مَآءً حَمِيمًا فَقَطَّعَ أَمْعَآءَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀpèjúwe Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí wọ́n ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (nìyí): àwọn omi odò wà nínú rẹ̀ tí kò níí yí padà àti àwọn odò wàrà tí adùn rẹ̀ kò níí yí padà àti àwọn odò ọtí dídùn fún àwọn tó máa mu ún àti àwọn odò oyin mímọ́. Gbogbo èso wà fún wọn nínú rẹ̀ àti àforíjìn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. (Ṣé ẹni tí ó wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra yìí) dà bí olùṣegbére nínú Iná bí, tí wọ́n ń fún wọn ní omi tó gbóná parí mu, tí ó sì máa já àwọn ìfun wọn pútupùtu?

See all translations of this verse →

وَمِنْهُم مَّن يَسْتَمِعُ إِلَيْكَ حَتَّىٰٓ إِذَا خَرَجُوا۟ مِنْ عِندِكَ قَالُوا۟ لِلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْعِلْمَ مَاذَا قَالَ ءَانِفًا أُو۟لَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ طَبَعَ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ وَٱتَّبَعُوٓا۟ أَهْوَآءَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ wà nínú wọn, ẹni tí ó ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ títí di ìgbà tí wọ́n bá jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ tán, wọn yó sì wí fún àwọn onímọ̀-ẹ̀sìn pé: “Kí l’ó sọ lẹ́ẹ̀ẹ̀ kan ná?” Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti dí ọkàn wọn pa. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn.

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ ٱهْتَدَوْا۟ زَادَهُمْ هُدًى وَءَاتَىٰهُمْ تَقْوَىٰهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó sì tẹ̀lé ìmọ̀nà, (Allāhu) ṣàlékún ìmọ̀nà fún wọn. Ó sì máa fún wọn ní ìbẹ̀rù wọn (nínú Allāhu).

See all translations of this verse →

فَهَلْ يَنظُرُونَ إِلَّا ٱلسَّاعَةَ أَن تَأْتِيَهُم بَغْتَةً فَقَدْ جَآءَ أَشْرَاطُهَا فَأَنَّىٰ لَهُمْ إِذَا جَآءَتْهُمْ ذِكْرَىٰهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe Àkókò náà, tí ó máa dé bá wọn ní òjijì? Àwọn àmì rẹ̀ kúkú ti dé. Nítorí náà, báwo ni ìrántí (yó ṣe wúlò fún) wọ́n nígbà tí ó bá dé bá wọn?

See all translations of this verse →

فَٱعْلَمْ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا ٱللَّهُ وَٱسْتَغْفِرْ لِذَنۢبِكَ وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَٱلْمُؤْمِنَٰتِ وَٱللَّهُ يَعْلَمُ مُتَقَلَّبَكُمْ وَمَثْوَىٰكُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, mọ̀ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu. Kí o sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ[1] àti fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu mọ lílọ-bíbọ̀ yín àti ibùgbé yín.

See all translations of this verse →

وَيَقُولُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَوْلَا نُزِّلَتْ سُورَةٌ فَإِذَآ أُنزِلَتْ سُورَةٌ مُّحْكَمَةٌ وَذُكِرَ فِيهَا ٱلْقِتَالُ رَأَيْتَ ٱلَّذِينَ فِى قُلُوبِهِم مَّرَضٌ يَنظُرُونَ إِلَيْكَ نَظَرَ ٱلْمَغْشِىِّ عَلَيْهِ مِنَ ٱلْمَوْتِ فَأَوْلَىٰ لَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ń sọ pé: “Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n sọ sūrah kan kalẹ̀?” Nígbà tí wọ́n bá sọ sūrah aláìnípọ́n-na kalẹ̀,[1] tí wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ ogun ẹ̀sìn nínú rẹ̀, ìwọ yóò rí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn, tí wọn yóò máa wò ọ́ ní wíwò bí ẹni pé wọ́n ti dákú lọ pọnrangandan. Ohun tí ó sì dára jùlọ fún wọn

See all translations of this verse →

طَاعَةٌ وَقَوْلٌ مَّعْرُوفٌ فَإِذَا عَزَمَ ٱلْأَمْرُ فَلَوْ صَدَقُوا۟ ٱللَّهَ لَكَانَ خَيْرًا لَّهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelni ìtẹ̀lé àṣẹ (Allāhu) àti (sísọ) ọ̀rọ̀ rere. Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà (ìyẹn ogun ẹ̀sìn) sì ti di dandan, wọn ìbá gbà pé Allāhu sọ òdodo, ìbá dára jùlọ fún wọn.

See all translations of this verse →

فَهَلْ عَسَيْتُمْ إِن تَوَلَّيْتُمْ أَن تُفْسِدُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ وَتُقَطِّعُوٓا۟ أَرْحَامَكُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ súnmọ́ pé tí ẹ̀yin bá kọ̀yìn sí ogun ẹ̀sìn, (ẹ̀ ń lọ sí oko ìparun nìyẹn, ẹ sì máa padà síbi ìwà ìgbà àìmọ̀kan) tí ẹ̀yin yóò máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí ẹ óò sì máa já okùn-ìbí yín?[1]

See all translations of this verse →

أُو۟لَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَعَنَهُمُ ٱللَّهُ فَأَصَمَّهُمْ وَأَعْمَىٰٓ أَبْصَٰرَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti ṣẹ́bi lé. Nítorí náà, Ó di wọ́n létí pa. Ó sì fọ́ ìríran wọn.

See all translations of this verse →

أَفَلَا يَتَدَبَّرُونَ ٱلْقُرْءَانَ أَمْ عَلَىٰ قُلُوبٍ أَقْفَالُهَآ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé wọn kò níí ronú nípa al-Ƙur’ān ni tàbí àwọn àgádágodo ti wà lórí ọkàn wọn ni?

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ ٱرْتَدُّوا۟ عَلَىٰٓ أَدْبَٰرِهِم مِّنۢ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ ٱلْهُدَى ٱلشَّيْطَٰنُ سَوَّلَ لَهُمْ وَأَمْلَىٰ لَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó pẹ̀yìn dà (sí ’Islām) lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú hàn sí wọn, aṣ-Ṣaetọ̄n ló ṣe ìṣìnà ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó sì fún wọn ní ìrètí asán nípa ẹ̀mí gígùn.

See all translations of this verse →

ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا۟ لِلَّذِينَ كَرِهُوا۟ مَا نَزَّلَ ٱللَّهُ سَنُطِيعُكُمْ فِى بَعْضِ ٱلْأَمْرِ وَٱللَّهُ يَعْلَمُ إِسْرَارَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyẹn nítorí pé (àwọn aláìsàn ọkàn) ń sọ fún àwọn tó kórira ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ (ìyẹn àwọn yẹhudi) pé: “Àwa yóò tẹ̀lé yin nínú apá kan ọ̀rọ̀ náà.”[1] Allāhu sì mọ àṣírí wọn.

See all translations of this verse →

فَكَيْفَ إِذَا تَوَفَّتْهُمُ ٱلْمَلَٰٓئِكَةُ يَضْرِبُونَ وُجُوهَهُمْ وَأَدْبَٰرَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáwo ni (ó ṣe máa rí fún wọn) nígbà tí àwọn mọlāika bá gba ẹ̀mí wọn, tí wọn yó sì máa lù wọ́n lójú, lù wọ́n lẹ́yìn?

See all translations of this verse →

ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ ٱتَّبَعُوا۟ مَآ أَسْخَطَ ٱللَّهَ وَكَرِهُوا۟ رِضْوَٰنَهُۥ فَأَحْبَطَ أَعْمَٰلَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n tẹ̀lé ohun tí ó bí Allāhu nínú. Wọ́n sì kórira ìyọ́nú Rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu ba àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́.

See all translations of this verse →

أَمْ حَسِبَ ٱلَّذِينَ فِى قُلُوبِهِم مَّرَضٌ أَن لَّن يُخْرِجَ ٱللَّهُ أَضْغَٰنَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn ń lérò pé Allāhu kò níí ṣe àfihàn àdìsọ́kàn burúkú wọn ni?

See all translations of this verse →

وَلَوْ نَشَآءُ لَأَرَيْنَٰكَهُمْ فَلَعَرَفْتَهُم بِسِيمَٰهُمْ وَلَتَعْرِفَنَّهُمْ فِى لَحْنِ ٱلْقَوْلِ وَٱللَّهُ يَعْلَمُ أَعْمَٰلَكُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé tí A bá fẹ́ Àwa ìbá fi wọ́n hàn ọ́, ìwọ ìbá sì mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Dájúdájú ìwọ yóò mọ̀ wọ́n níbi pé wọ́n máa ń pẹ́kọrọ ọ̀rọ̀.[1] Allāhu sì mọ àwọn iṣẹ́ (ọwọ́) yín.

See all translations of this verse →

وَلَنَبْلُوَنَّكُمْ حَتَّىٰ نَعْلَمَ ٱلْمُجَٰهِدِينَ مِنكُمْ وَٱلصَّٰبِرِينَ وَنَبْلُوَا۟ أَخْبَارَكُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú A máa dan yín wò títí A fi máa ṣàfi hàn àwọn olùjagun-ẹ̀sìn àti àwọn onísùúrù nínú yín. A sì máa gbìdánwò àwọn ìró yín wò.[1]

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَصَدُّوا۟ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَشَآقُّوا۟ ٱلرَّسُولَ مِنۢ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ ٱلْهُدَىٰ لَن يَضُرُّوا۟ ٱللَّهَ شَيْـًٔا وَسَيُحْبِطُ أَعْمَٰلَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí wọ́n tún yapa Òjíṣẹ́ Allāhu lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú hàn sí wọn, wọn kò lè kó ìnira kiní kan bá Allāhu. (Allāhu) yó sì ba iṣẹ́ wọn jẹ́.

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ أَطِيعُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُوا۟ ٱلرَّسُولَ وَلَا تُبْطِلُوٓا۟ أَعْمَٰلَكُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé (ọ̀rọ̀) Allāhu, ẹ tẹ̀lé (ọ̀rọ̀) Òjíṣẹ́ náà, kí ẹ sì má ṣe ba àwọn iṣẹ́ yín jẹ́.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَصَدُّوا۟ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ ثُمَّ مَاتُوا۟ وَهُمْ كُفَّارٌ فَلَن يَغْفِرَ ٱللَّهُ لَهُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, lẹ́yìn náà tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, Allāhu kò níí foríjìn wọ́n.

See all translations of this verse →

فَلَا تَهِنُوا۟ وَتَدْعُوٓا۟ إِلَى ٱلسَّلْمِ وَأَنتُمُ ٱلْأَعْلَوْنَ وَٱللَّهُ مَعَكُمْ وَلَن يَتِرَكُمْ أَعْمَٰلَكُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ má ṣe káàárẹ̀, kí ẹ sì má ṣe pèpè fún kòsógunmọ́, nígbà tí ẹ bá ń lékè lọ́wọ́. Allāhu wà pẹ̀lú yín; kò sì níí kó àdínkù bá ẹ̀san àwọn iṣẹ́ yín.[1]

See all translations of this verse →

إِنَّمَا ٱلْحَيَوٰةُ ٱلدُّنْيَا لَعِبٌ وَلَهْوٌ وَإِن تُؤْمِنُوا۟ وَتَتَّقُوا۟ يُؤْتِكُمْ أُجُورَكُمْ وَلَا يَسْـَٔلْكُمْ أَمْوَٰلَكُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelEré àti ìranù ni ìṣẹ̀mí ayé. (Àmọ́) tí ẹ bá gbàgbọ́ (nínú Allāhu), tí ẹ sì bẹ̀rù (Rẹ̀), Ó máa fún yín ní àwọn ẹ̀san yín. Kò sì níí bèèrè àwọn dúkìá yín (pé kí ẹ fi gbogbo rẹ̀ yọ Zakāh).

See all translations of this verse →

إِن يَسْـَٔلْكُمُوهَا فَيُحْفِكُمْ تَبْخَلُوا۟ وَيُخْرِجْ أَضْغَٰنَكُمْ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí (Allāhu) bá bèèrè rẹ̀ ní ọwọ́ yín (pé, kí ẹ fi gbogbo rẹ̀ yọ Zakāh), tí Ó sì won̄koko mọ yín, ẹ máa ṣahun. Ó sì máa mú àrùn ọkàn yín jadé (àṣírí yín yó sì tú síta).

See all translations of this verse →

هَٰٓأَنتُمْ هَٰٓؤُلَآءِ تُدْعَوْنَ لِتُنفِقُوا۟ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ فَمِنكُم مَّن يَبْخَلُ وَمَن يَبْخَلْ فَإِنَّمَا يَبْخَلُ عَن نَّفْسِهِۦ وَٱللَّهُ ٱلْغَنِىُّ وَأَنتُمُ ٱلْفُقَرَآءُ وَإِن تَتَوَلَّوْا۟ يَسْتَبْدِلْ قَوْمًا غَيْرَكُمْ ثُمَّ لَا يَكُونُوٓا۟ أَمْثَٰلَكُم

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin náà mà nìwọ̀nyí tí wọ́n ń pè láti náwó sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Ṣùgbọ́n ẹni tó ń ṣahun wà nínú yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣahun, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Allāhu ni Ọlọ́rọ̀. Ẹ̀yin sì ni aláìní. Tí ẹ bá gbúnrí, (Allāhu) máa fi ìjọ mìíràn pààrọ̀ yín. Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí dà bí irú yín.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70