caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Maaida, ẹsẹ 5

Medina · revelation order 112 · 5:5

ٱلْيَوْمَ أُحِلَّ لَكُمُ ٱلطَّيِّبَٰتُ وَطَعَامُ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَٰبَ حِلٌّ لَّكُمْ وَطَعَامُكُمْ حِلٌّ لَّهُمْ وَٱلْمُحْصَنَٰتُ مِنَ ٱلْمُؤْمِنَٰتِ وَٱلْمُحْصَنَٰتُ مِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَٰبَ مِن قَبْلِكُمْ إِذَآ ءَاتَيْتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ مُحْصِنِينَ غَيْرَ مُسَٰفِحِينَ وَلَا مُتَّخِذِىٓ أَخْدَانٍ وَمَن يَكْفُرْ بِٱلْإِيمَٰنِ فَقَدْ حَبِطَ عَمَلُهُۥ وَهُوَ فِى ٱلْـَٔاخِرَةِ مِنَ ٱلْخَٰسِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fún yín lónìí. Àti oúnjẹ àwọn tí A fún ní tírà, ẹ̀tọ́ ni fún yín.[1] Oúnjẹ tiyín náà, ẹ̀tọ́ ni fún wọn. (Ẹ̀tọ́ ni fún yín láti fẹ́) àwọn olómìnira nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin àti àwọn olómìnira lóbìnrin nínú àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín, nígbà tí ẹ bá ti fún wọn ní ṣọ̀daàkí wọn; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ (bí ’Islām ṣe ní kí ẹ fẹ́ ìyàwó), láì níí máa bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì) láì sì níí máa yàn wọ́n lálè.² Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí ìgbàgbọ́ òdodo³, iṣẹ́ rẹ̀ ti bàjẹ́. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70