caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Maaida, ẹsẹ 4

Medina · revelation order 112 · 5:4

يَسْـَٔلُونَكَ مَاذَآ أُحِلَّ لَهُمْ قُلْ أُحِلَّ لَكُمُ ٱلطَّيِّبَٰتُ وَمَا عَلَّمْتُم مِّنَ ٱلْجَوَارِحِ مُكَلِّبِينَ تُعَلِّمُونَهُنَّ مِمَّا عَلَّمَكُمُ ٱللَّهُ فَكُلُوا۟ مِمَّآ أَمْسَكْنَ عَلَيْكُمْ وَٱذْكُرُوا۟ ٱسْمَ ٱللَّهِ عَلَيْهِ وَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلْحِسَابِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń bi ọ́ léèrè pé: “Kí ni wọ́n ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn?” Sọ pé: “Wọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fún yín àti (ẹran tí ẹ pa nípasẹ̀) èyí tí ẹ kọ́ ní ẹ̀kọ́ (ìdọdẹ) nínú àwọn ẹranko àti ẹyẹ tí ń dọdẹ. Ẹ kọ́ àwọn ajá lẹ́kọ̀ọ́ ìdọdẹ, kí ẹ kọ́ wọn nínú ohun tí Allāhu fi mọ̀ yín. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí wọ́n bá pa fún yín, kí ẹ sì ṣe bismillāh sí i[1]. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70