caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-An'aam, ẹsẹ 151

Mecca · revelation order 55 · 6:151

قُلْ تَعَالَوْا۟ أَتْلُ مَا حَرَّمَ رَبُّكُمْ عَلَيْكُمْ أَلَّا تُشْرِكُوا۟ بِهِۦ شَيْـًٔا وَبِٱلْوَٰلِدَيْنِ إِحْسَٰنًا وَلَا تَقْتُلُوٓا۟ أَوْلَٰدَكُم مِّنْ إِمْلَٰقٍ نَّحْنُ نَرْزُقُكُمْ وَإِيَّاهُمْ وَلَا تَقْرَبُوا۟ ٱلْفَوَٰحِشَ مَا ظَهَرَ مِنْهَا وَمَا بَطَنَ وَلَا تَقْتُلُوا۟ ٱلنَّفْسَ ٱلَّتِى حَرَّمَ ٱللَّهُ إِلَّا بِٱلْحَقِّ ذَٰلِكُمْ وَصَّىٰكُم بِهِۦ لَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ẹ wá kí n̄g ka ohun tí Olúwa yín ṣe ní èèwọ̀ fún yín pé; kí ẹ má ṣe fí n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I, (kí ẹ sì ṣe) dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì, kí ẹ sì má ṣe pa àwọn ọmọ yín nítorí (ìbẹ̀rù) òṣì, - Àwa ni À ń pèsè fun ẹ̀yin àti àwọn - kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ àwọn ìwà ìbájẹ́ - èyí tó hàn nínú rẹ̀ àti èyí tó pamọ́, - àti pé kí ẹ sì má ṣe pa ẹ̀mí (ènìyàn) tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fún yín nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70