يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ شَهَٰدَةُ بَيْنِكُمْ إِذَا حَضَرَ أَحَدَكُمُ ٱلْمَوْتُ حِينَ ٱلْوَصِيَّةِ ٱثْنَانِ ذَوَا عَدْلٍ مِّنكُمْ أَوْ ءَاخَرَانِ مِنْ غَيْرِكُمْ إِنْ أَنتُمْ ضَرَبْتُمْ فِى ٱلْأَرْضِ فَأَصَٰبَتْكُم مُّصِيبَةُ ٱلْمَوْتِ تَحْبِسُونَهُمَا مِنۢ بَعْدِ ٱلصَّلَوٰةِ فَيُقْسِمَانِ بِٱللَّهِ إِنِ ٱرْتَبْتُمْ لَا نَشْتَرِى بِهِۦ ثَمَنًا وَلَوْ كَانَ ذَا قُرْبَىٰ وَلَا نَكْتُمُ شَهَٰدَةَ ٱللَّهِ إِنَّآ إِذًا لَّمِنَ ٱلْـَٔاثِمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, (ẹ wá) ẹ̀rí jíjẹ́ láààrin yín nígbà tí (ìpọ́kàkà) ikú bá dé bá ẹnì kan nínú yín tí ó fẹ́ sọ àsọọ́lẹ̀. (Ẹ wá) onídéédé méjì nínú yín.[1] Tàbí àwọn méjì mìíràn yàtọ̀ si yín tí ẹ̀yin bá wà lórí ìrìn-àjò tí àjálù ikú bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ si yín.² Ẹ dá àwọn méjèèjì dúró lẹ́yìn ìrun, kí wọ́n fi Allāhu búra, tí ẹ bá ṣeyèméjì (sí òdodo wọn, kí wọ́n sì sọ pé:) “A ò níí ta ìbúra wa ní iye kan kan, kódà kó jẹ́ ẹbí. A ò sì níí fi ẹ̀rí jíjẹ́ tí Allāhu (pa láṣẹ) pamọ́. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú àwa wà nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”