فَإِنْ عُثِرَ عَلَىٰٓ أَنَّهُمَا ٱسْتَحَقَّآ إِثْمًا فَـَٔاخَرَانِ يَقُومَانِ مَقَامَهُمَا مِنَ ٱلَّذِينَ ٱسْتَحَقَّ عَلَيْهِمُ ٱلْأَوْلَيَٰنِ فَيُقْسِمَانِ بِٱللَّهِ لَشَهَٰدَتُنَآ أَحَقُّ مِن شَهَٰدَتِهِمَا وَمَا ٱعْتَدَيْنَآ إِنَّآ إِذًا لَّمِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí wọ́n bá sì mọ̀ pé àwọn méjèèjì dá ẹ̀ṣẹ̀ (nípa yíyí àsọọ́lẹ̀ padà tàbí jíjí dúkìá aláìsí), kí àwọn méjì mìíràn nínú ẹbí òkú tí àsọọ́lẹ̀ lẹ́tọ̀ọ́ sì jùlọ,[1] (ìyẹn) ènìyàn méjì tí ó súnmọ́ òkú jùlọ rọ́pò àwọn méjèèjì àkọ́kọ́ (níbi mímú àsọọ́lẹ̀ mìíràn wá fún òkú). Kí àwọn náà sì fi Allāhu búra pé: “Dájúdájú ẹ̀rí jíjẹ́ tiwa jẹ́ òdodo ju ẹ̀rí jíjẹ́ ti àwọn méjèèjì (àkọ́kọ́). A ò sì níí tayọ ẹnu-ààlà. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú a ti wà nínú àwọn alábòsí.”