caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Baqara, ẹsẹ 258

Medina · revelation order 87 · 2:258

أَلَمْ تَرَ إِلَى ٱلَّذِى حَآجَّ إِبْرَٰهِـۧمَ فِى رَبِّهِۦٓ أَنْ ءَاتَىٰهُ ٱللَّهُ ٱلْمُلْكَ إِذْ قَالَ إِبْرَٰهِـۧمُ رَبِّىَ ٱلَّذِى يُحْىِۦ وَيُمِيتُ قَالَ أَنَا۠ أُحْىِۦ وَأُمِيتُ قَالَ إِبْرَٰهِـۧمُ فَإِنَّ ٱللَّهَ يَأْتِى بِٱلشَّمْسِ مِنَ ٱلْمَشْرِقِ فَأْتِ بِهَا مِنَ ٱلْمَغْرِبِ فَبُهِتَ ٱلَّذِى كَفَرَ وَٱللَّهُ لَا يَهْدِى ٱلْقَوْمَ ٱلظَّٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ìwọ kò wòye sí ẹni tó bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jiyàn nípa Olúwa rẹ̀, nítorí pé Allāhu fún un ní ìjọba? Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú.” Ó wí pé: “Èmi náà ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Mo sì ń sọ ẹ̀dá di òkú.” (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ń mú òòrùn wá láti ibùyọ. Mú un wa nígbà náà láti ibùwọ̀.” Wọ́n sì pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹni tó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́nu. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70