ٱللَّهُ وَلِىُّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ يُخْرِجُهُم مِّنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ أَوْلِيَآؤُهُمُ ٱلطَّٰغُوتُ يُخْرِجُونَهُم مِّنَ ٱلنُّورِ إِلَى ٱلظُّلُمَٰتِ أُو۟لَٰٓئِكَ أَصْحَٰبُ ٱلنَّارِ هُمْ فِيهَا خَٰلِدُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu ni Alárànṣe àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó ń mú wọn jáde kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn òrìṣà ni aláfẹ̀yìntì wọn. Àwọn òrìṣà ń mú wọn jáde kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ wá sínú àwọn òkùnkùn. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.