caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà An-Nisaa النساء

176 verses · Medina · revelation order 92

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُوا۟ رَبَّكُمُ ٱلَّذِى خَلَقَكُم مِّن نَّفْسٍ وَٰحِدَةٍ وَخَلَقَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَبَثَّ مِنْهُمَا رِجَالًا كَثِيرًا وَنِسَآءً وَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ ٱلَّذِى تَسَآءَلُونَ بِهِۦ وَٱلْأَرْحَامَ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَيْكُمْ رَقِيبًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan (ìyẹn, Ànábì Ādam). Ó sì ṣẹ̀dá aya rẹ̀ (Hawā’) láti ara rẹ̀. Ó fọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin jáde láti ara àwọn méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀ ń fi bẹ ara yín. (Ẹ ṣọ́) okùn-ìbí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí yín.

See all translations of this verse →

وَءَاتُوا۟ ٱلْيَتَٰمَىٰٓ أَمْوَٰلَهُمْ وَلَا تَتَبَدَّلُوا۟ ٱلْخَبِيثَ بِٱلطَّيِّبِ وَلَا تَأْكُلُوٓا۟ أَمْوَٰلَهُمْ إِلَىٰٓ أَمْوَٰلِكُمْ إِنَّهُۥ كَانَ حُوبًا كَبِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ fún àwọn ọmọ òrukàn ní dúkìá wọn.[1] Ẹ má ṣe fi n̄ǹkan dáadáa pààrọ̀ n̄ǹkan burúkú.² Ẹ sì má ṣe jẹ dúkìá wọn mọ́ dúkìá yín; dájúdájú ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó tóbi.

See all translations of this verse →

وَإِنْ خِفْتُمْ أَلَّا تُقْسِطُوا۟ فِى ٱلْيَتَٰمَىٰ فَٱنكِحُوا۟ مَا طَابَ لَكُم مِّنَ ٱلنِّسَآءِ مَثْنَىٰ وَثُلَٰثَ وَرُبَٰعَ فَإِنْ خِفْتُمْ أَلَّا تَعْدِلُوا۟ فَوَٰحِدَةً أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَٰنُكُمْ ذَٰلِكَ أَدْنَىٰٓ أَلَّا تَعُولُوا۟

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé nípa (fífẹ́) ọmọ òrukàn,[1] ẹ fẹ́ ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ si yín nínú àwọn obìnrin; méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin.² Ṣùgbọ́n tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé, (ẹ fẹ́) ẹyọ kan tàbí ẹrúbìnrin yín. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ pé ẹ ò níí ṣàbòsí.

See all translations of this verse →

وَءَاتُوا۟ ٱلنِّسَآءَ صَدُقَٰتِهِنَّ نِحْلَةً فَإِن طِبْنَ لَكُمْ عَن شَىْءٍ مِّنْهُ نَفْسًا فَكُلُوهُ هَنِيٓـًٔا مَّرِيٓـًٔا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ fún àwọn obìnrin ní sọ̀daàkí wọn tó jẹ́ ọ̀ran-anyàn ní tọkàn-tọkàn. Tí wọ́n bá sì fi inú dídùn yọ̀ǹda kiní kan fún yín nínú rẹ̀, ẹ jẹ ẹ́ pẹ̀lú ìrọ̀rùn àti ìgbádùn.

See all translations of this verse →

وَلَا تُؤْتُوا۟ ٱلسُّفَهَآءَ أَمْوَٰلَكُمُ ٱلَّتِى جَعَلَ ٱللَّهُ لَكُمْ قِيَٰمًا وَٱرْزُقُوهُمْ فِيهَا وَٱكْسُوهُمْ وَقُولُوا۟ لَهُمْ قَوْلًا مَّعْرُوفًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ má ṣe kó dúkìá yín tí Allāhu fí ṣe gbẹ́mìíró fún yín lé àwọn aláìlóye lọ́wọ́. Ẹ pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn nínú rẹ̀, kí ẹ sì raṣọ fún wọn. Kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ dáadáa fún wọn.

See all translations of this verse →

وَٱبْتَلُوا۟ ٱلْيَتَٰمَىٰ حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغُوا۟ ٱلنِّكَاحَ فَإِنْ ءَانَسْتُم مِّنْهُمْ رُشْدًا فَٱدْفَعُوٓا۟ إِلَيْهِمْ أَمْوَٰلَهُمْ وَلَا تَأْكُلُوهَآ إِسْرَافًا وَبِدَارًا أَن يَكْبَرُوا۟ وَمَن كَانَ غَنِيًّا فَلْيَسْتَعْفِفْ وَمَن كَانَ فَقِيرًا فَلْيَأْكُلْ بِٱلْمَعْرُوفِ فَإِذَا دَفَعْتُمْ إِلَيْهِمْ أَمْوَٰلَهُمْ فَأَشْهِدُوا۟ عَلَيْهِمْ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ حَسِيبًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ dán àwọn ọmọ òrukàn wò[1] títí wọn yóò fi dàgbà wọ ẹni tí ò lè ṣe ìgbéyàwó.² Tí ẹ bá sì ti rí òye lára wọn, kí ẹ dá dúkìá wọn padà fún wọn. Ẹ ò gbọdọ̀ jẹ dúkìá wọn ní ìjẹ àpà àti ìjẹkújẹ kí wọ́n tó dàgbà. Ẹni tí ó bá jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí ó mójú kúrò (níbẹ̀). Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìní, kí ó jẹ nínú rẹ̀ ní ọ̀nà tó dára. Nítorí náà, tí ẹ bá fẹ́ dá dúkìá wọn padà fún wọn, ẹ pe àwọn ẹlẹ́rìí sí wọn. Allāhu sì tó ní Olùṣírò.

See all translations of this verse →

لِّلرِّجَالِ نَصِيبٌ مِّمَّا تَرَكَ ٱلْوَٰلِدَانِ وَٱلْأَقْرَبُونَ وَلِلنِّسَآءِ نَصِيبٌ مِّمَّا تَرَكَ ٱلْوَٰلِدَانِ وَٱلْأَقْرَبُونَ مِمَّا قَلَّ مِنْهُ أَوْ كَثُرَ نَصِيبًا مَّفْرُوضًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ọkùnrin ní ìpín nínú ohun tí òbí méjèèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Àti pé àwọn obìnrin náà ní ìpín nínú ohun tí òbí méjéèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Nínú ohun tó kéré nínú rẹ̀ tàbí tó pọ̀; (ó jẹ́) ìpín tí wọ́n ti pín (tí wọ́n ti ṣàdáyanrí rẹ̀ fún wọn).

See all translations of this verse →

وَإِذَا حَضَرَ ٱلْقِسْمَةَ أُو۟لُوا۟ ٱلْقُرْبَىٰ وَٱلْيَتَٰمَىٰ وَٱلْمَسَٰكِينُ فَٱرْزُقُوهُم مِّنْهُ وَقُولُوا۟ لَهُمْ قَوْلًا مَّعْرُوفًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù bá wà ní (ìjókòó) ogún pípín, ẹ fún wọn nínú rẹ̀ (ṣíwájú kí ẹ tó pín ogún), kí ẹ sì sọ̀rọ̀ dáadáa fún wọn.

See all translations of this verse →

وَلْيَخْشَ ٱلَّذِينَ لَوْ تَرَكُوا۟ مِنْ خَلْفِهِمْ ذُرِّيَّةً ضِعَٰفًا خَافُوا۟ عَلَيْهِمْ فَلْيَتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَلْيَقُولُوا۟ قَوْلًا سَدِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn (olùpíngún àti alágbàwò-ọmọ-òrukàn) tí ó bá jẹ́ pé àwọn náà máa fi ọmọ wẹ́wẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì ń páyà lórí wọn, kí wọ́n yáa bẹ̀rù Allāhu. Kí wọ́n sì máa sọ̀rọ̀ dáadáa (fún ọmọ òrukàn).

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ يَأْكُلُونَ أَمْوَٰلَ ٱلْيَتَٰمَىٰ ظُلْمًا إِنَّمَا يَأْكُلُونَ فِى بُطُونِهِمْ نَارًا وَسَيَصْلَوْنَ سَعِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó ń jẹ dúkìá ọmọ òrukàn pẹ̀lú àbòsí, Iná kúkú ni wọ́n ń jẹ sínú ikùn wọn. Wọ́n sì máa wọ inú Iná tó ń jó.

See all translations of this verse →

يُوصِيكُمُ ٱللَّهُ فِىٓ أَوْلَٰدِكُمْ لِلذَّكَرِ مِثْلُ حَظِّ ٱلْأُنثَيَيْنِ فَإِن كُنَّ نِسَآءً فَوْقَ ٱثْنَتَيْنِ فَلَهُنَّ ثُلُثَا مَا تَرَكَ وَإِن كَانَتْ وَٰحِدَةً فَلَهَا ٱلنِّصْفُ وَلِأَبَوَيْهِ لِكُلِّ وَٰحِدٍ مِّنْهُمَا ٱلسُّدُسُ مِمَّا تَرَكَ إِن كَانَ لَهُۥ وَلَدٌ فَإِن لَّمْ يَكُن لَّهُۥ وَلَدٌ وَوَرِثَهُۥٓ أَبَوَاهُ فَلِأُمِّهِ ٱلثُّلُثُ فَإِن كَانَ لَهُۥٓ إِخْوَةٌ فَلِأُمِّهِ ٱلسُّدُسُ مِنۢ بَعْدِ وَصِيَّةٍ يُوصِى بِهَآ أَوْ دَيْنٍ ءَابَآؤُكُمْ وَأَبْنَآؤُكُمْ لَا تَدْرُونَ أَيُّهُمْ أَقْرَبُ لَكُمْ نَفْعًا فَرِيضَةً مِّنَ ٱللَّهِ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu ń sọ àsọọ́lẹ̀ (òfin) fún yín nípa (ogún tí ẹ máa pín fún) àwọn ọmọ yín; ti ọkùnrin ni irú ìpín ti obìnrin méjì. Tí wọ́n bá sì jẹ́ obìnrin (nìkan), méjì sókè, tiwọn ni ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ohun tí (òkú) fi sílẹ̀. Tí ó bá jẹ́ obìnrin kan ṣoṣo, ìdajì ni tirẹ̀. Ti òbí rẹ̀ méjèèjì, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì nínú ohun tí òkú fi sílẹ̀, tí ó bá ní ọmọ láyé. Tí kò bá sì ní ọmọ láyé, tí ó sì jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì l’ó máa jogún rẹ̀, ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ni ti ìyá rẹ̀. Tí ó bá ní arákùnrin (tàbí arábìnrin), ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìyá rẹ̀, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ó sọ tàbí gbèsè. Àwọn bàbá yín àti àwọn ọmọkùnrin yín; ẹ̀yin kò mọ èwo nínú wọn ló máa mú àǹfààní ba yín jùlọ. (Ìpín) ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

وَلَكُمْ نِصْفُ مَا تَرَكَ أَزْوَٰجُكُمْ إِن لَّمْ يَكُن لَّهُنَّ وَلَدٌ فَإِن كَانَ لَهُنَّ وَلَدٌ فَلَكُمُ ٱلرُّبُعُ مِمَّا تَرَكْنَ مِنۢ بَعْدِ وَصِيَّةٍ يُوصِينَ بِهَآ أَوْ دَيْنٍ وَلَهُنَّ ٱلرُّبُعُ مِمَّا تَرَكْتُمْ إِن لَّمْ يَكُن لَّكُمْ وَلَدٌ فَإِن كَانَ لَكُمْ وَلَدٌ فَلَهُنَّ ٱلثُّمُنُ مِمَّا تَرَكْتُم مِّنۢ بَعْدِ وَصِيَّةٍ تُوصُونَ بِهَآ أَوْ دَيْنٍ وَإِن كَانَ رَجُلٌ يُورَثُ كَلَٰلَةً أَوِ ٱمْرَأَةٌ وَلَهُۥٓ أَخٌ أَوْ أُخْتٌ فَلِكُلِّ وَٰحِدٍ مِّنْهُمَا ٱلسُّدُسُ فَإِن كَانُوٓا۟ أَكْثَرَ مِن ذَٰلِكَ فَهُمْ شُرَكَآءُ فِى ٱلثُّلُثِ مِنۢ بَعْدِ وَصِيَّةٍ يُوصَىٰ بِهَآ أَوْ دَيْنٍ غَيْرَ مُضَآرٍّ وَصِيَّةً مِّنَ ٱللَّهِ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَلِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTiyín ni ìlàjì ohun tí àwọn ìyàwó yín fi sílẹ̀, tí wọn kò bá ní ọmọ. Tí wọ́n bá sì ní ọmọ, tiyín ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí wọ́n fi sílẹ̀, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè. Tiwọn sì ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí ẹ fi sílẹ̀, tí ẹ̀yin kò bá ní ọmọ láyé. Tí ẹ bá ní ọmọ láyé, ìdá kan nínú ìdá mẹ́jọ ni tiwọn nínú ohun tí ẹ fi sílẹ̀ lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ẹ sọ tàbí gbèsè. Tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan tí wọ́n fẹ́ jogún rẹ̀ kò bá ní òbí àti ọmọ, tí ó sì ní arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì. Tí wọ́n bá sì pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ, wọn yóò dìjọ pín ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè, tí kò níí jẹ́ ìpalára. Àsọọ́lẹ̀ (òfin) kan ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Aláfaradà.

See all translations of this verse →

تِلْكَ حُدُودُ ٱللَّهِ وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ يُدْخِلْهُ جَنَّٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَا وَذَٰلِكَ ٱلْفَوْزُ ٱلْعَظِيمُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌyẹn ni àwọn ẹnu-ààlà (tí) Allāhu (gbékalẹ̀ fún ogún pípín). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.

See all translations of this verse →

وَمَن يَعْصِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَيَتَعَدَّ حُدُودَهُۥ يُدْخِلْهُ نَارًا خَٰلِدًا فِيهَا وَلَهُۥ عَذَابٌ مُّهِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá sì yapa (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ó sì ń tayọ àwọn ẹnu-ààlà tí Allāhu gbékalẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú Iná kan. Olùṣegbére ni nínú rẹ̀. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì ń bẹ fún un.[1]

See all translations of this verse →

وَٱلَّٰتِى يَأْتِينَ ٱلْفَٰحِشَةَ مِن نِّسَآئِكُمْ فَٱسْتَشْهِدُوا۟ عَلَيْهِنَّ أَرْبَعَةً مِّنكُمْ فَإِن شَهِدُوا۟ فَأَمْسِكُوهُنَّ فِى ٱلْبُيُوتِ حَتَّىٰ يَتَوَفَّىٰهُنَّ ٱلْمَوْتُ أَوْ يَجْعَلَ ٱللَّهُ لَهُنَّ سَبِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ń ṣe sìná nínú àwọn obìnrin yín, ẹ wá ẹlẹ́rìí mẹ́rin nínú yín tí ó máa jẹ́rìí lé wọn lórí. Tí wọ́n bá jẹ́rìí lé wọn lórí, kí ẹ dè wọ́n mọ́ inú ilé títí ikú yóò fi pa wọ́n tàbí (títí) Allāhu yóò fi gbé ọ̀nà (ìjìyà) kan kalẹ̀ fún wọn.[1]

See all translations of this verse →

وَٱلَّذَانِ يَأْتِيَٰنِهَا مِنكُمْ فَـَٔاذُوهُمَا فَإِن تَابَا وَأَصْلَحَا فَأَعْرِضُوا۟ عَنْهُمَآ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ تَوَّابًا رَّحِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn méjì tí wọ́n ṣe sìná nínú yín, kí ẹ (fi ẹnu tàbí ọwọ́) bá wọn wí.[1] Tí wọ́n bá sì ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣàtúnṣe, kí ẹ mójú kúrò lára wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́- ọ̀run.

See all translations of this verse →

إِنَّمَا ٱلتَّوْبَةُ عَلَى ٱللَّهِ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ ٱلسُّوٓءَ بِجَهَٰلَةٍ ثُمَّ يَتُوبُونَ مِن قَرِيبٍ فَأُو۟لَٰٓئِكَ يَتُوبُ ٱللَّهُ عَلَيْهِمْ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌronúpìwàdà tí Allāhu yóò gbà ni ti àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan.[1] Lẹ́yìn náà, wọ́n ronú pìwàdà láìpẹ́ (ìyẹn ṣíwájú ọjọ́ ikú wọn). Àwọn wọ̀nyí ni Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

وَلَيْسَتِ ٱلتَّوْبَةُ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِ حَتَّىٰٓ إِذَا حَضَرَ أَحَدَهُمُ ٱلْمَوْتُ قَالَ إِنِّى تُبْتُ ٱلْـَٰٔنَ وَلَا ٱلَّذِينَ يَمُوتُونَ وَهُمْ كُفَّارٌ أُو۟لَٰٓئِكَ أَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí ìronúpìwàdà fún àwọn tó ń ṣe aburú títí ikú fi dé bá ọ̀kan nínú wọn, kí ó wá wí pé: “Dájúdájú èmi ronú pìwàdà nísisìnyìí.” (Kò tún sí ìronúpìwàdà) fún àwọn tó kú sípò aláìgbàgbọ́. Àwọn wọ̀nyẹn, A ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta eléro sílẹ̀ dè wọ́n.

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا يَحِلُّ لَكُمْ أَن تَرِثُوا۟ ٱلنِّسَآءَ كَرْهًا وَلَا تَعْضُلُوهُنَّ لِتَذْهَبُوا۟ بِبَعْضِ مَآ ءَاتَيْتُمُوهُنَّ إِلَّآ أَن يَأْتِينَ بِفَٰحِشَةٍ مُّبَيِّنَةٍ وَعَاشِرُوهُنَّ بِٱلْمَعْرُوفِ فَإِن كَرِهْتُمُوهُنَّ فَعَسَىٰٓ أَن تَكْرَهُوا۟ شَيْـًٔا وَيَجْعَلَ ٱللَّهُ فِيهِ خَيْرًا كَثِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti jẹ àwọn obìnrin mógún pẹ̀lú ipá (bíi ṣíṣú obìnrin lópó.) Ẹ má ṣe fúnlẹ̀ mọ́ wọn nítorí kí ẹ le gba apá kan n̄ǹkan tí ẹ fún wọn àyàfi tí wọ́n bá hùwà ìbàjẹ́ tó fojú hàn. Ẹ bá wọn lòpọ̀ pẹ̀lú dáadáa. Tí ẹ bá kórira wọn, ó lè jẹ́ pé ẹ kórira kiní kan, kí Allāhu sì ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ oore sínú rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَإِنْ أَرَدتُّمُ ٱسْتِبْدَالَ زَوْجٍ مَّكَانَ زَوْجٍ وَءَاتَيْتُمْ إِحْدَىٰهُنَّ قِنطَارًا فَلَا تَأْخُذُوا۟ مِنْهُ شَيْـًٔا أَتَأْخُذُونَهُۥ بُهْتَٰنًا وَإِثْمًا مُّبِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ẹ bá sì fẹ́ fi ìyàwó kan pààrọ̀ àyè ìyàwó kan, tí ẹ sì ti fún ọ̀kan nínú wọn ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá, ẹ ò gbọdọ̀ gba n̄ǹkan kan nínú rẹ̀ mọ́. Ṣé ẹ̀yin yóò gbà á ní ti àdápa irọ́ (tí ẹ̀ ń pa mọ́ wọn) àti ẹ̀ṣẹ̀ tó fojú hàn(tí ẹ̀ ń dá nípa wọn)?[1]

See all translations of this verse →

وَكَيْفَ تَأْخُذُونَهُۥ وَقَدْ أَفْضَىٰ بَعْضُكُمْ إِلَىٰ بَعْضٍ وَأَخَذْنَ مِنكُم مِّيثَٰقًا غَلِيظًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáwo ni ẹ̀yin ṣe lè gbà á padà nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ ti wọlé tọ’ra yín, tí wọ́n sì ti gba àdéhùn tó nípọn lọ́wọ́ yín![1]

See all translations of this verse →

وَلَا تَنكِحُوا۟ مَا نَكَحَ ءَابَآؤُكُم مِّنَ ٱلنِّسَآءِ إِلَّا مَا قَدْ سَلَفَ إِنَّهُۥ كَانَ فَٰحِشَةً وَمَقْتًا وَسَآءَ سَبِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ má ṣe fẹ́ ẹni tí àwọn bàbá yín ti fẹ́ nínú àwọn obìnrin àyàfi èyí tí ó ti ré kọjá. Dájúdájú ó jẹ́ ìwà ìbàjẹ́ àti ohun ìkórira. Ó sì burú ní ọ̀nà.

See all translations of this verse →

حُرِّمَتْ عَلَيْكُمْ أُمَّهَٰتُكُمْ وَبَنَاتُكُمْ وَأَخَوَٰتُكُمْ وَعَمَّٰتُكُمْ وَخَٰلَٰتُكُمْ وَبَنَاتُ ٱلْأَخِ وَبَنَاتُ ٱلْأُخْتِ وَأُمَّهَٰتُكُمُ ٱلَّٰتِىٓ أَرْضَعْنَكُمْ وَأَخَوَٰتُكُم مِّنَ ٱلرَّضَٰعَةِ وَأُمَّهَٰتُ نِسَآئِكُمْ وَرَبَٰٓئِبُكُمُ ٱلَّٰتِى فِى حُجُورِكُم مِّن نِّسَآئِكُمُ ٱلَّٰتِى دَخَلْتُم بِهِنَّ فَإِن لَّمْ تَكُونُوا۟ دَخَلْتُم بِهِنَّ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ وَحَلَٰٓئِلُ أَبْنَآئِكُمُ ٱلَّذِينَ مِنْ أَصْلَٰبِكُمْ وَأَن تَجْمَعُوا۟ بَيْنَ ٱلْأُخْتَيْنِ إِلَّا مَا قَدْ سَلَفَ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورًا رَّحِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA ṣe é ní èèwọ̀ fún yín (láti fẹ́) àwọn ìyá yín àti àwọn ọmọbìnrin yín àti àwọn arábìnrin yín àti àwọn arábìnrin bàbá yín àti àwọn arábìnrin ìyá yín àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin yín àti àwọn ìyá yín tí ó fún yín ní ọyàn mu àti àwọn arábìnrin yín nípasẹ̀ ọyàn àti àwọn ìyá ìyàwó yín àti àwọn ọmọbìnrin ìyàwó yín tí ẹ gbà tọ́, èyí tó wà nínú ilé yín,[1] tí ẹ sì ti wọlé tọ àwọn ìyá wọn, - tí ẹ̀yin kò bá sì tí ì wọlé tọ̀ wọ́n, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín (láti fẹ́ ọmọbìnrin wọn), - àti àwọn ìyàwó ọmọ yín, èyí tí ó ti ìbàdí yín jáde. (Ó tún jẹ́ èèwọ̀) láti fẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò papọ̀ àyàfi èyí tí ó ti ré kọjá. Dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

وَٱلْمُحْصَنَٰتُ مِنَ ٱلنِّسَآءِ إِلَّا مَا مَلَكَتْ أَيْمَٰنُكُمْ كِتَٰبَ ٱللَّهِ عَلَيْكُمْ وَأُحِلَّ لَكُم مَّا وَرَآءَ ذَٰلِكُمْ أَن تَبْتَغُوا۟ بِأَمْوَٰلِكُم مُّحْصِنِينَ غَيْرَ مُسَٰفِحِينَ فَمَا ٱسْتَمْتَعْتُم بِهِۦ مِنْهُنَّ فَـَٔاتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ فَرِيضَةً وَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ فِيمَا تَرَٰضَيْتُم بِهِۦ مِنۢ بَعْدِ ٱلْفَرِيضَةِ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ó tún jẹ́ èèwọ̀ láti fẹ́) àwọn abilékọ nínú àwọn obìnrin àyàfi àwọn ẹrúbìnrin yín. Òfin Allāhu nìyí lórí yín. Wọ́n sì ṣe ẹni tó ń bẹ lẹ́yìn àwọn wọ̀nyẹn (àwọn obìnrin yòókù) ní ẹ̀tọ́ fún yín pé kí ẹ wá wọn fẹ́ pẹ̀lú dúkìá yín; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ ìyàwó, láì nìí bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì síso). Ẹni tí ẹ bá sì fẹ́ ní fífẹ́ ìyàwó nínú wọn, tí ẹ sì ti jẹ ìgbádùn oorun ìfẹ́ lára wọn[1] (àmọ́ tí ẹ fẹ́ kọ̀ wọ́n sílẹ̀), ẹ fún wọn ní sọ̀daàkí wọn tí ó jẹ́ ìpín ọ̀ran-anyàn.² Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín nípa ohun tí ẹ dìjọ yọ́nú sí (láti fojúfò láààrin ara yín) lẹ́yìn sọ̀daàkí (tó jẹ́ ìpín ọ̀ran-anyàn)³. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

وَمَن لَّمْ يَسْتَطِعْ مِنكُمْ طَوْلًا أَن يَنكِحَ ٱلْمُحْصَنَٰتِ ٱلْمُؤْمِنَٰتِ فَمِن مَّا مَلَكَتْ أَيْمَٰنُكُم مِّن فَتَيَٰتِكُمُ ٱلْمُؤْمِنَٰتِ وَٱللَّهُ أَعْلَمُ بِإِيمَٰنِكُم بَعْضُكُم مِّنۢ بَعْضٍ فَٱنكِحُوهُنَّ بِإِذْنِ أَهْلِهِنَّ وَءَاتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ بِٱلْمَعْرُوفِ مُحْصَنَٰتٍ غَيْرَ مُسَٰفِحَٰتٍ وَلَا مُتَّخِذَٰتِ أَخْدَانٍ فَإِذَآ أُحْصِنَّ فَإِنْ أَتَيْنَ بِفَٰحِشَةٍ فَعَلَيْهِنَّ نِصْفُ مَا عَلَى ٱلْمُحْصَنَٰتِ مِنَ ٱلْعَذَابِ ذَٰلِكَ لِمَنْ خَشِىَ ٱلْعَنَتَ مِنكُمْ وَأَن تَصْبِرُوا۟ خَيْرٌ لَّكُمْ وَٱللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸni tí kò bá lágbára ọrọ̀ nínú yín láti fẹ́ àwọn olómìnira onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, kí ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúbìnrin yín onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ yín, ara kan náà sì ni yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda àwọn olówó wọn (àwọn ọ̀gá wọn). Kí ẹ sì fún wọn ní sọ̀daàkí wọn ní ọ̀nà tó dára, (ìyẹn) àwọn ọmọlúàbí (ẹrúbìnrin), yàtọ̀ sí àwọn onísìná obìnrin àti àwọn obìnrin tí ń yan àlè[1]. Nígbà tí wọ́n bá sì di abilékọ, tí wọ́n bá (tún) lọ ṣe sìná, ìlàjì ìyà tí ń bẹ fún àwọn olómìnira obìnrin ni ìyà tí ń bẹ fún wọn.² (Fífẹ́ ẹrúbìnrin), ìyẹn wà fún ẹni tó ń páyà ìnira (sìná) nínú yín. Àti pé kí ẹ ṣe sùúrù lóore jùlọ fún yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيُبَيِّنَ لَكُمْ وَيَهْدِيَكُمْ سُنَنَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِكُمْ وَيَتُوبَ عَلَيْكُمْ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fẹ́ ṣàlàyé (òfin) fún yín, Ó fẹ́ tọ yín sí ọ̀nà àwọn tó ṣíwájú yín, Ó sì fẹ́ gba ìronúpìwàdà yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

وَٱللَّهُ يُرِيدُ أَن يَتُوبَ عَلَيْكُمْ وَيُرِيدُ ٱلَّذِينَ يَتَّبِعُونَ ٱلشَّهَوَٰتِ أَن تَمِيلُوا۟ مَيْلًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé Allāhu fẹ́ gba ìronúpìwàdà yín. Àwọn tó sì ń tẹ̀lé ìfẹ́-adùn ara sì ń fẹ́ kí ẹ yẹ̀ kúrò (nínú ẹ̀sìn) ní yíyẹ̀ tó tóbi pátápátá.

See all translations of this verse →

يُرِيدُ ٱللَّهُ أَن يُخَفِّفَ عَنكُمْ وَخُلِقَ ٱلْإِنسَٰنُ ضَعِيفًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu fẹ́ gbé e fúyẹ́ fún yín; A sì ṣẹ̀dá ènìyàn ní ọ̀lẹ.[1]

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَأْكُلُوٓا۟ أَمْوَٰلَكُم بَيْنَكُم بِٱلْبَٰطِلِ إِلَّآ أَن تَكُونَ تِجَٰرَةً عَن تَرَاضٍ مِّنكُمْ وَلَا تَقْتُلُوٓا۟ أَنفُسَكُمْ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِكُمْ رَحِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe fi èrú jẹ dúkìá yín láààrin ara yín àyàfi kí ó jẹ́ òwò ṣíṣe pẹ̀lú ìyọ́nú láààrin ara yín. Ẹ má ṣe para yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú si yín.

See all translations of this verse →

وَمَن يَفْعَلْ ذَٰلِكَ عُدْوَٰنًا وَظُلْمًا فَسَوْفَ نُصْلِيهِ نَارًا وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe ìyẹn láti fi tayọ ẹnu-ààlà àti láti fi ṣe àbòsí, láìpẹ́ A máa mú un wọ inú Iná. Ìrọ̀rùn sì ni ìyẹn jẹ́ fún Allāhu.

See all translations of this verse →

إِن تَجْتَنِبُوا۟ كَبَآئِرَ مَا تُنْهَوْنَ عَنْهُ نُكَفِّرْ عَنكُمْ سَيِّـَٔاتِكُمْ وَنُدْخِلْكُم مُّدْخَلًا كَرِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ẹ bá jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá tí A kọ̀ fún yín, A máa pa àwọn ìwà àìdáa yín rẹ́ fún yín, A sì máa mu yín wọ àyè alápọ̀n-ọ́nlé.

See all translations of this verse →

وَلَا تَتَمَنَّوْا۟ مَا فَضَّلَ ٱللَّهُ بِهِۦ بَعْضَكُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ لِّلرِّجَالِ نَصِيبٌ مِّمَّا ٱكْتَسَبُوا۟ وَلِلنِّسَآءِ نَصِيبٌ مِّمَّا ٱكْتَسَبْنَ وَسْـَٔلُوا۟ ٱللَّهَ مِن فَضْلِهِۦٓ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ má ṣe jẹ̀rankàn ohun tí Allāhu fi ṣ’oore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan.[1] Ìpín (ẹ̀san) ń bẹ fún àwọn ọkùnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, ìpín (ẹ̀san) sì ń bẹ fún àwọn obìnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Kí ẹ sì tọrọ lọ́dọ̀ Allāhu nínú àlékún oore Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

See all translations of this verse →

وَلِكُلٍّ جَعَلْنَا مَوَٰلِىَ مِمَّا تَرَكَ ٱلْوَٰلِدَانِ وَٱلْأَقْرَبُونَ وَٱلَّذِينَ عَقَدَتْ أَيْمَٰنُكُمْ فَـَٔاتُوهُمْ نَصِيبَهُمْ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ شَهِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÌkọ̀ọ̀kan (nínú yín) ni A ti ṣe àdáyanrí àwọn ẹbí tí ó máa jogún rẹ̀ nínú ohun tí àwọn òbí àti ẹbí fi sílẹ̀. Àwọn tí ẹ sì búra fún (pé ẹ máa fún ní n̄ǹkan), ẹ fún wọn ní ìpín wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.

See all translations of this verse →

ٱلرِّجَالُ قَوَّٰمُونَ عَلَى ٱلنِّسَآءِ بِمَا فَضَّلَ ٱللَّهُ بَعْضَهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ وَبِمَآ أَنفَقُوا۟ مِنْ أَمْوَٰلِهِمْ فَٱلصَّٰلِحَٰتُ قَٰنِتَٰتٌ حَٰفِظَٰتٌ لِّلْغَيْبِ بِمَا حَفِظَ ٱللَّهُ وَٱلَّٰتِى تَخَافُونَ نُشُوزَهُنَّ فَعِظُوهُنَّ وَٱهْجُرُوهُنَّ فِى ٱلْمَضَاجِعِ وَٱضْرِبُوهُنَّ فَإِنْ أَطَعْنَكُمْ فَلَا تَبْغُوا۟ عَلَيْهِنَّ سَبِيلًا إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيًّا كَبِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ọkùnrin ni òpómúléró[1] fún àwọn obìnrin nítorí pé, Allāhu ṣ’oore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan² àti nítorí ohun tí wọ́n ń ná nínú dúkìá wọn.³ Àwọn obìnrin rere ni àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ (Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà àṣẹ ọkọ), àwọn olùṣọ́-ẹ̀tọ́ ọkọ ní kọ̀rọ̀ fún wí pé Allāhu ṣọ́ (ẹ̀tọ́ tiwọn náà fún wọn lọ́dọ̀ ọkọ wọn). Àwọn tí ẹ sì ń páyà oríkunkun wọn⁴, ẹ ṣe wáàsí fún wọn, ẹ takété sí ibùsùn wọn, ẹ lù wọ́n (láì níí kó ìnira bá wọn). Tí wọ́n bá sì tẹ̀lé àṣẹ yín, ẹ má ṣe fí ọ̀nà kan kan wá wọn níjà⁵. Dájúdájú Allāhu ga, Ó tóbi.⁶

See all translations of this verse →

وَإِنْ خِفْتُمْ شِقَاقَ بَيْنِهِمَا فَٱبْعَثُوا۟ حَكَمًا مِّنْ أَهْلِهِۦ وَحَكَمًا مِّنْ أَهْلِهَآ إِن يُرِيدَآ إِصْلَٰحًا يُوَفِّقِ ٱللَّهُ بَيْنَهُمَآ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا خَبِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ẹ bà sì mọ̀ pé ìyapa wà láààrin àwọn méjèèjì, ẹ gbé olóye kan dìde láti inú ẹbí ọkọ àti olóye kan láti inú ẹbí ìyàwó. Tí àwọn (tọkọ tìyàwó) méjèèjì bá ń fẹ́ àtúnṣe, Allāhu yóò fi àwọn (olóye méjèèjì) ṣe kòǹgẹ́ àtúnṣe lórí ọ̀rọ̀ ààrin wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alámọ̀tán.

See all translations of this verse →

وَٱعْبُدُوا۟ ٱللَّهَ وَلَا تُشْرِكُوا۟ بِهِۦ شَيْـًٔا وَبِٱلْوَٰلِدَيْنِ إِحْسَٰنًا وَبِذِى ٱلْقُرْبَىٰ وَٱلْيَتَٰمَىٰ وَٱلْمَسَٰكِينِ وَٱلْجَارِ ذِى ٱلْقُرْبَىٰ وَٱلْجَارِ ٱلْجُنُبِ وَٱلصَّاحِبِ بِٱلْجَنۢبِ وَٱبْنِ ٱلسَّبِيلِ وَمَا مَلَكَتْ أَيْمَٰنُكُمْ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ مَن كَانَ مُخْتَالًا فَخُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ jọ́sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I. Ẹ ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì àti ẹbí àti àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù àti aládùúgbò tó súnmọ́ àti aládùúgbò tó jìnnà àti ọ̀rẹ́ alábàárìn àti onírìn-àjò (tí agara dá) àti àwọn ẹrú yín. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ onígbèéraga onífáàrí.

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ يَبْخَلُونَ وَيَأْمُرُونَ ٱلنَّاسَ بِٱلْبُخْلِ وَيَكْتُمُونَ مَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضْلِهِۦ وَأَعْتَدْنَا لِلْكَٰفِرِينَ عَذَابًا مُّهِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ń ṣahun, (àwọn) tó ń pa ènìyàn láṣẹ ahun ṣíṣe àti (àwọn) tó ń fi ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ pamọ́; A ti pèsè ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمْوَٰلَهُمْ رِئَآءَ ٱلنَّاسِ وَلَا يُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ وَلَا بِٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ وَمَن يَكُنِ ٱلشَّيْطَٰنُ لَهُۥ قَرِينًا فَسَآءَ قَرِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ń ná dúkìá wọn pẹ̀lú ṣekárími, tí wọn kò sì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn; ẹnikẹ́ni tí aṣ-Ṣaetọ̄n bá jẹ́ ọ̀rẹ́ fún, ó burú ní ọ̀rẹ́.

See all translations of this verse →

وَمَاذَا عَلَيْهِمْ لَوْ ءَامَنُوا۟ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ وَأَنفَقُوا۟ مِمَّا رَزَقَهُمُ ٱللَّهُ وَكَانَ ٱللَّهُ بِهِمْ عَلِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ni ìpalára tí ó máa ṣe fún wọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí wọ́n sì ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún wọn? Allāhu sì jẹ́ Onímọ̀ nípa wọ́n.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَظْلِمُ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ وَإِن تَكُ حَسَنَةً يُضَٰعِفْهَا وَيُؤْتِ مِن لَّدُنْهُ أَجْرًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí òdíwọ̀n ọmọ iná-igún. Tí ó bá jẹ iṣẹ́ rere, Ó máa ṣàdìpèlé (ẹ̀san) rẹ̀. Ó sì máa fún (olùṣe rere) ní ẹ̀san ńlá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

See all translations of this verse →

فَكَيْفَ إِذَا جِئْنَا مِن كُلِّ أُمَّةٍۭ بِشَهِيدٍ وَجِئْنَا بِكَ عَلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِ شَهِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáwo ni ọ̀rọ̀ wọn yóò ti rí nígbà tí A bá mú ẹlẹ́rìí jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan, tí A sì mú ìwọ jáde ní ẹlẹ́rìí lórí àwọn wọ̀nyí?

See all translations of this verse →

يَوْمَئِذٍ يَوَدُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَعَصَوُا۟ ٱلرَّسُولَ لَوْ تُسَوَّىٰ بِهِمُ ٱلْأَرْضُ وَلَا يَكْتُمُونَ ٱللَّهَ حَدِيثًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ọjọ́ yẹn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì yapa Òjíṣẹ́ náà, wọ́n á fẹ́ kí àwọn bá ilẹ̀ dọ́gba (kí wọ́n di erùpẹ̀). Wọn kò sì lè fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́ fún Allāhu.

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَقْرَبُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنتُمْ سُكَٰرَىٰ حَتَّىٰ تَعْلَمُوا۟ مَا تَقُولُونَ وَلَا جُنُبًا إِلَّا عَابِرِى سَبِيلٍ حَتَّىٰ تَغْتَسِلُوا۟ وَإِن كُنتُم مَّرْضَىٰٓ أَوْ عَلَىٰ سَفَرٍ أَوْ جَآءَ أَحَدٌ مِّنكُم مِّنَ ٱلْغَآئِطِ أَوْ لَٰمَسْتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَلَمْ تَجِدُوا۟ مَآءً فَتَيَمَّمُوا۟ صَعِيدًا طَيِّبًا فَٱمْسَحُوا۟ بِوُجُوهِكُمْ وَأَيْدِيكُمْ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَفُوًّا غَفُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe súnmọ́ ìrun kíkí nígbà tí ọtí bá ń pa yín títí ẹ máa fi mọ ohun tí ẹ̀ ń sọ[1] àti àwọn oníjánnábà, àfi àwọn olùkọjá nínú mọ́sálásí, títí ẹ máa fi wẹ̀ (ìwẹ̀ jánnábà). Tí ẹ bá sì jẹ́ aláìsàn tàbí ẹ wà lórí ìrìn-àjò tàbí ẹnì kan nínú yín dé láti ibi ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí ẹ súnmọ́ obínrin (yín), tí ẹ kò rí omi, ẹ fi erùpẹ̀ tó dára ṣe táyàmọ́mù; ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámòójúkúrò, Aláforíjìn.

See all translations of this verse →

أَلَمْ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ نَصِيبًا مِّنَ ٱلْكِتَٰبِ يَشْتَرُونَ ٱلضَّلَٰلَةَ وَيُرِيدُونَ أَن تَضِلُّوا۟ ٱلسَّبِيلَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú tírà, tí wọ́n ń ra ìṣìnà, tí wọ́n sì fẹ́ kí ẹ ṣìnà lójú-ọ̀nà?

See all translations of this verse →

وَٱللَّهُ أَعْلَمُ بِأَعْدَآئِكُمْ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَلِيًّا وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ نَصِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn ọ̀tá yín. Allāhu tó ní Aláàbò. Allāhu sì tó ní Alárànṣe.

See all translations of this verse →

مِّنَ ٱلَّذِينَ هَادُوا۟ يُحَرِّفُونَ ٱلْكَلِمَ عَن مَّوَاضِعِهِۦ وَيَقُولُونَ سَمِعْنَا وَعَصَيْنَا وَٱسْمَعْ غَيْرَ مُسْمَعٍ وَرَٰعِنَا لَيًّۢا بِأَلْسِنَتِهِمْ وَطَعْنًا فِى ٱلدِّينِ وَلَوْ أَنَّهُمْ قَالُوا۟ سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا وَٱسْمَعْ وَٱنظُرْنَا لَكَانَ خَيْرًا لَّهُمْ وَأَقْوَمَ وَلَٰكِن لَّعَنَهُمُ ٱللَّهُ بِكُفْرِهِمْ فَلَا يُؤْمِنُونَ إِلَّا قَلِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ ń bẹ nínú àwọn yẹhudi, àwọn tó ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “A gbọ́, a sì yapa. Gbọ́rọ̀ bí ẹni tí etí rẹ̀ ti di, òmùgọ̀ wa.”[1] Wọ́n ń fi ahọ́n wọn yí ọ̀rọ̀ sódì àti pé wọ́n ń bu ẹnu-àtẹ́ lu ẹ̀sìn. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n sọ pé: “A gbọ́, a sì tẹ̀lé e. Gbọ́, kí o sì kíyè sí wa”, ìbá dára fún wọn, ìbá sì tọ̀nà jùlọ. Ṣùgbọ́n Allāhu fi wọ́n gégùn-ún nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn).

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَٰبَ ءَامِنُوا۟ بِمَا نَزَّلْنَا مُصَدِّقًا لِّمَا مَعَكُم مِّن قَبْلِ أَن نَّطْمِسَ وُجُوهًا فَنَرُدَّهَا عَلَىٰٓ أَدْبَارِهَآ أَوْ نَلْعَنَهُمْ كَمَا لَعَنَّآ أَصْحَٰبَ ٱلسَّبْتِ وَكَانَ أَمْرُ ٱللَّهِ مَفْعُولًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí A fún ní tírà, ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín, ṣíwájú kí Á tó fọ́ àwọn ojú kan, A sì máa dá a padà sí (ìpàkọ́) lẹ́yìn wọn, tàbí kí Á ṣẹ́bi lé wọn gẹ́gẹ́ bí A ṣe ṣẹ́bi lé ìjọ Sabt. Àti pé àṣẹ Allāhu máa ṣẹ.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَغْفِرُ أَن يُشْرَكَ بِهِۦ وَيَغْفِرُ مَا دُونَ ذَٰلِكَ لِمَن يَشَآءُ وَمَن يُشْرِكْ بِٱللَّهِ فَقَدِ ٱفْتَرَىٰٓ إِثْمًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I.[1] Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti dá àdápa irọ́ (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

See all translations of this verse →

أَلَمْ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ يُزَكُّونَ أَنفُسَهُم بَلِ ٱللَّهُ يُزَكِّى مَن يَشَآءُ وَلَا يُظْلَمُونَ فَتِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ìwọ kò wòye sí àwọn tó ń ṣàfọ̀mọ́ ara wọn ni? Kò sì rí bẹ́ẹ̀, Allāhu l’Ó ń ṣàfọ̀mọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Wọn kò sì níí fi (ohun tó tó) ìbójú kóró èso dàbínù ṣàbòsí sí wọn.[1]

See all translations of this verse →

ٱنظُرْ كَيْفَ يَفْتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلْكَذِبَ وَكَفَىٰ بِهِۦٓ إِثْمًا مُّبِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWo bí wọ́n ṣe ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Ó sì tó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé.

See all translations of this verse →

أَلَمْ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ نَصِيبًا مِّنَ ٱلْكِتَٰبِ يُؤْمِنُونَ بِٱلْجِبْتِ وَٱلطَّٰغُوتِ وَيَقُولُونَ لِلَّذِينَ كَفَرُوا۟ هَٰٓؤُلَآءِ أَهْدَىٰ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ سَبِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú tírà, tí wọ́n ń gbàgbọ́ nínú idán àti òrìṣà, wọ́n sì ń wí fún àwọn aláìgbàgbọ́ pé: “Àwọn (ọ̀ṣẹbọ) wọ̀nyí mọ̀nà ju àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”

See all translations of this verse →

أُو۟لَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَعَنَهُمُ ٱللَّهُ وَمَن يَلْعَنِ ٱللَّهُ فَلَن تَجِدَ لَهُۥ نَصِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣẹ́bi lé. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá sì ṣẹ́bi lé, o ò níí rí alárànṣe kan fún un.

See all translations of this verse →

أَمْ لَهُمْ نَصِيبٌ مِّنَ ٱلْمُلْكِ فَإِذًا لَّا يُؤْتُونَ ٱلنَّاسَ نَقِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí ìpín kan ń bẹ fún wọn nínú ìjọba (Wa) ni? Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀ wọn kò níí fún àwọn ènìyàn ní (òdiwọ̀n) àmì ẹ̀yìn kóró èso dàbínú (ní ibi tí wọ́n máa yahun dé).

See all translations of this verse →

أَمْ يَحْسُدُونَ ٱلنَّاسَ عَلَىٰ مَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضْلِهِۦ فَقَدْ ءَاتَيْنَآ ءَالَ إِبْرَٰهِيمَ ٱلْكِتَٰبَ وَٱلْحِكْمَةَ وَءَاتَيْنَٰهُم مُّلْكًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí wọ́n ń ṣe ìlara àwọn ènìyàn lórí ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ ni? Dájúdájú A fún àwọn ẹbí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní Tírà àti òye ìjìnlẹ̀ (sunnah). A sì fún wọn ní ìjọba ńlá.

See all translations of this verse →

فَمِنْهُم مَّنْ ءَامَنَ بِهِۦ وَمِنْهُم مَّن صَدَّ عَنْهُ وَكَفَىٰ بِجَهَنَّمَ سَعِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, ó ń bẹ nínú wọn ẹni tó gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni tó ṣẹ́rí kúrò níbẹ̀. Jahanamọ sì tó ní iná tó ń jo.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِـَٔايَٰتِنَا سَوْفَ نُصْلِيهِمْ نَارًا كُلَّمَا نَضِجَتْ جُلُودُهُم بَدَّلْنَٰهُمْ جُلُودًا غَيْرَهَا لِيَذُوقُوا۟ ٱلْعَذَابَ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَزِيزًا حَكِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, láìpẹ́ A máa mú wọn wọ inú Iná. Ìgbàkígbà tí awọ ara wọn bá jóná, A óò máa pààrọ̀ awọ ara mìíràn fún wọn kí wọ́n lè máa tọ́ ìyà wò lọ. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ سَنُدْخِلُهُمْ جَنَّٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدًا لَّهُمْ فِيهَآ أَزْوَٰجٌ مُّطَهَّرَةٌ وَنُدْخِلُهُمْ ظِلًّا ظَلِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, A óò mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Àwọn ìyàwó mímọ́ ń bẹ fún wọn nínú rẹ̀. A sì máa fi wọ́n sí abẹ́ ibòji tó máa ṣíji bò wọ́n dáradára.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱللَّهَ يَأْمُرُكُمْ أَن تُؤَدُّوا۟ ٱلْأَمَٰنَٰتِ إِلَىٰٓ أَهْلِهَا وَإِذَا حَكَمْتُم بَيْنَ ٱلنَّاسِ أَن تَحْكُمُوا۟ بِٱلْعَدْلِ إِنَّ ٱللَّهَ نِعِمَّا يَعِظُكُم بِهِۦٓ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ سَمِيعًۢا بَصِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Allāhu ń pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ dá àgbàfipamọ́ padà fún àwọn olówó wọn. Àti pé nígbà tí ẹ bá ń dájọ́ láààrin àwọn ènìyàn, ẹ dájọ́ pẹ̀lú déédé. Dájúdájú Allāhu ń fi n̄ǹkan tó dára ṣe wáàsí fún yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgbọ́, Olùríran.

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ أَطِيعُوا۟ ٱللَّهَ وَأَطِيعُوا۟ ٱلرَّسُولَ وَأُو۟لِى ٱلْأَمْرِ مِنكُمْ فَإِن تَنَٰزَعْتُمْ فِى شَىْءٍ فَرُدُّوهُ إِلَى ٱللَّهِ وَٱلرَّسُولِ إِن كُنتُمْ تُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ ذَٰلِكَ خَيْرٌ وَأَحْسَنُ تَأْوِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu, ẹ tẹ̀lé (àṣẹ) Òjíṣẹ́ náà àti àwọn aláṣẹ nínú yín. Nítorí náà, tí ẹ bá yapa-ẹnu lórí kiní kan, ẹ ṣẹ́rí rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -,[1] tí ẹ bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ fún ìkángun ọ̀rọ̀ (ìyọrísí).

See all translations of this verse →

أَلَمْ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ يَزْعُمُونَ أَنَّهُمْ ءَامَنُوا۟ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيْكَ وَمَآ أُنزِلَ مِن قَبْلِكَ يُرِيدُونَ أَن يَتَحَاكَمُوٓا۟ إِلَى ٱلطَّٰغُوتِ وَقَدْ أُمِرُوٓا۟ أَن يَكْفُرُوا۟ بِهِۦ وَيُرِيدُ ٱلشَّيْطَٰنُ أَن يُضِلَّهُمْ ضَلَٰلًۢا بَعِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ìwọ kò wòye sí àwọn tó ń sọ̀rọ̀ (tí kò sì rí bẹ́ẹ̀) pé dájúdájú àwọn gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, tí wọ́n sì ń gbèrò láti gbé ẹjọ́ lọ bá òrìṣà, A sì ti pa wọ́n láṣẹ pé kí wọ́n lòdì sí i. Aṣ-ṣaetọ̄n sì fẹ́ ṣì wọ́n lọ́nà ní ìṣìnà tó jìnnà.

See all translations of this verse →

وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا۟ إِلَىٰ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ وَإِلَى ٱلرَّسُولِ رَأَيْتَ ٱلْمُنَٰفِقِينَ يَصُدُّونَ عَنكَ صُدُودًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ wá síbi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, ẹ wá bá Òjíṣẹ́.”, o máa rí àwọn mùnááfìkí tí wọn yóò máa ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ rẹ tààrà.

See all translations of this verse →

فَكَيْفَ إِذَآ أَصَٰبَتْهُم مُّصِيبَةٌۢ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ ثُمَّ جَآءُوكَ يَحْلِفُونَ بِٱللَّهِ إِنْ أَرَدْنَآ إِلَّآ إِحْسَٰنًا وَتَوْفِيقًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáwo ni ó ṣe jẹ́ pé nígbà tí àdánwò kan bá kàn wọ́n nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ wọ́n tì síwájú, lẹ́yìn náà wọ́n máa wá bá ọ, wọ́n yó sì máa fi Allāhu búra pé kò sí ohun tí a gbàlérò bí kò ṣe dáadáa àti ìrẹ́pọ̀.

See all translations of this verse →

أُو۟لَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ يَعْلَمُ ٱللَّهُ مَا فِى قُلُوبِهِمْ فَأَعْرِضْ عَنْهُمْ وَعِظْهُمْ وَقُل لَّهُمْ فِىٓ أَنفُسِهِمْ قَوْلًۢا بَلِيغًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn. Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ṣe wáàsí fún wọn, kí o sì bá wọn sọ ọ̀rọ̀ tó máa mì wọ́n lọ́kàn nípa ọ̀rọ̀ ara wọn.

See all translations of this verse →

وَمَآ أَرْسَلْنَا مِن رَّسُولٍ إِلَّا لِيُطَاعَ بِإِذْنِ ٱللَّهِ وَلَوْ أَنَّهُمْ إِذ ظَّلَمُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ جَآءُوكَ فَٱسْتَغْفَرُوا۟ ٱللَّهَ وَٱسْتَغْفَرَ لَهُمُ ٱلرَّسُولُ لَوَجَدُوا۟ ٱللَّهَ تَوَّابًا رَّحِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi nítorí kí wọ́n lè tẹ̀lé e pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n wá bá ọ,[1] wọ́n sì tọrọ àforíjìn Allāhu, tí Òjíṣẹ́ sì tún bá wọn tọrọ àforíjìn, wọn ìbá kúkú rí Allāhu ní Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

فَلَا وَرَبِّكَ لَا يُؤْمِنُونَ حَتَّىٰ يُحَكِّمُوكَ فِيمَا شَجَرَ بَيْنَهُمْ ثُمَّ لَا يَجِدُوا۟ فِىٓ أَنفُسِهِمْ حَرَجًا مِّمَّا قَضَيْتَ وَيُسَلِّمُوا۟ تَسْلِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelRárá, Èmi fi Olúwa rẹ búra pé wọn kò tí ì gbàgbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi gbà ọ́ ní olùdájọ́ lórí ohun tí ó bá dá yánpọnyánrin sílẹ̀ láààrin wọn. Lẹ́yìn náà, wọn kò níí ní ẹ̀hónú kan sí ìdájọ́ tí o bá dá. Wọ́n sì máa gbà pátápátá.

See all translations of this verse →

وَلَوْ أَنَّا كَتَبْنَا عَلَيْهِمْ أَنِ ٱقْتُلُوٓا۟ أَنفُسَكُمْ أَوِ ٱخْرُجُوا۟ مِن دِيَٰرِكُم مَّا فَعَلُوهُ إِلَّا قَلِيلٌ مِّنْهُمْ وَلَوْ أَنَّهُمْ فَعَلُوا۟ مَا يُوعَظُونَ بِهِۦ لَكَانَ خَيْرًا لَّهُمْ وَأَشَدَّ تَثْبِيتًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ó bá jẹ́ pé A ṣe é ní ọ̀ran- anyàn fún wọn pé: "Ẹ pa ara yín tàbí ẹ jáde kúrò nínú ìlú yín," wọn kò níí ṣe é àfi díẹ̀ nínú wọn. Tí ó bá tún jẹ́ pé wọ́n ṣe ohun tí A fi ń ṣe wáàsí fún wọn ni, ìbá jẹ́ oore àti ìdúróṣinṣin tó lágbára jùlọ fún wọn.

See all translations of this verse →

وَإِذًا لَّـَٔاتَيْنَٰهُم مِّن لَّدُنَّآ أَجْرًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà náà, dájúdájú Àwa ìbá fún wọn ní ẹ̀san ńlá láti ọ̀dọ̀ Wa.

See all translations of this verse →

وَلَهَدَيْنَٰهُمْ صِرَٰطًا مُّسْتَقِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé dájúdájú Àwa ìbá tọ́ wọn sí ọ̀nà tààrà.

See all translations of this verse →

وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَٱلرَّسُولَ فَأُو۟لَٰٓئِكَ مَعَ ٱلَّذِينَ أَنْعَمَ ٱللَّهُ عَلَيْهِم مِّنَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ وَٱلصِّدِّيقِينَ وَٱلشُّهَدَآءِ وَٱلصَّٰلِحِينَ وَحَسُنَ أُو۟لَٰٓئِكَ رَفِيقًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ náà, àwọn wọ̀nyẹn máa wà (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn tí Allāhu ṣèdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, àwọn olódodo, àwọn tó kú ikú ṣẹhīdi[1] àti àwọn ẹni rere. Àwọn wọ̀nyẹn sì dára ní alábàárìn.

See all translations of this verse →

ذَٰلِكَ ٱلْفَضْلُ مِنَ ٱللَّهِ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ عَلِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOore àjùlọ yẹn máa wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu; Allāhu sì tó ní Onímọ̀.

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ خُذُوا۟ حِذْرَكُمْ فَٱنفِرُوا۟ ثُبَاتٍ أَوِ ٱنفِرُوا۟ جَمِيعًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú ohun ìṣọ́ra yín lọ́wọ́, kí ẹ sì tú jáde s’ójú ogun ẹ̀sìn níkọ̀níkọ̀ tàbí kí ẹ tú jáde ní àpapọ̀.[1]

See all translations of this verse →

وَإِنَّ مِنكُمْ لَمَن لَّيُبَطِّئَنَّ فَإِنْ أَصَٰبَتْكُم مُّصِيبَةٌ قَالَ قَدْ أَنْعَمَ ٱللَّهُ عَلَىَّ إِذْ لَمْ أَكُن مَّعَهُمْ شَهِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ó ń bẹ nínú yín ẹni tó ń fà sẹ́yìn. Tí àdánwó kan bá kàn yín, ó máa wí pé: “Allāhu kúkú ti ṣe ìdẹ̀ra fún mi nítorí pé èmi kò sí níbẹ̀ pẹ̀lú wọn (wọn kò sì rí mi pa pẹ̀lú àwọn tó kú ikú ṣẹhīdi).”

See all translations of this verse →

وَلَئِنْ أَصَٰبَكُمْ فَضْلٌ مِّنَ ٱللَّهِ لَيَقُولَنَّ كَأَن لَّمْ تَكُنۢ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُۥ مَوَدَّةٌ يَٰلَيْتَنِى كُنتُ مَعَهُمْ فَأَفُوزَ فَوْزًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú tí oore àjùlọ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu bá sì tẹ̀ yín lọ́wọ́, dájúdájú ó máa sọ̀rọ̀ - bí ẹni pé kò sí ìfẹ́ láààrin ẹ̀yin àti òun (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) - pé: “Yéè! Èmi ìbá wà pẹ̀lú wọn, èmi ìbá jẹ èrè ńlá.”

See all translations of this verse →

فَلْيُقَٰتِلْ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ ٱلَّذِينَ يَشْرُونَ ٱلْحَيَوٰةَ ٱلدُّنْيَا بِٱلْـَٔاخِرَةِ وَمَن يُقَٰتِلْ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ فَيُقْتَلْ أَوْ يَغْلِبْ فَسَوْفَ نُؤْتِيهِ أَجْرًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, kí àwọn tó ń fi ayé ra ọ̀run máa jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu, yálà wọ́n pa á tàbí ó ṣẹ́gun, láìpẹ́ A máa fún un ní ẹ̀san ńlá.

See all translations of this verse →

وَمَا لَكُمْ لَا تُقَٰتِلُونَ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلْمُسْتَضْعَفِينَ مِنَ ٱلرِّجَالِ وَٱلنِّسَآءِ وَٱلْوِلْدَٰنِ ٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَآ أَخْرِجْنَا مِنْ هَٰذِهِ ٱلْقَرْيَةِ ٱلظَّالِمِ أَهْلُهَا وَٱجْعَل لَّنَا مِن لَّدُنكَ وَلِيًّا وَٱجْعَل لَّنَا مِن لَّدُنكَ نَصِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí l’ó ṣe yín tí ẹ kò níí jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ààbò ẹ̀sìn Rẹ̀) àti (fún ààbò) àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú ìlú yìí, ìlú àwọn alábòsí. Fún wa ní aláàbò kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ́. Kí Ó sì fún wa ní alárànṣe kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ.”

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ يُقَٰتِلُونَ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ يُقَٰتِلُونَ فِى سَبِيلِ ٱلطَّٰغُوتِ فَقَٰتِلُوٓا۟ أَوْلِيَآءَ ٱلشَّيْطَٰنِ إِنَّ كَيْدَ ٱلشَّيْطَٰنِ كَانَ ضَعِيفًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń jagun sí ojú-ọ̀nà òrìṣà. Nítorí náà, ẹ ja àwọn ọ̀rẹ́ aṣ-Ṣaetọ̄n lógun. Dájúdájú ète aṣ-Ṣaetọ̄n, ó jẹ́ ohun tí ó lẹ.

See all translations of this verse →

أَلَمْ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ قِيلَ لَهُمْ كُفُّوٓا۟ أَيْدِيَكُمْ وَأَقِيمُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُوا۟ ٱلزَّكَوٰةَ فَلَمَّا كُتِبَ عَلَيْهِمُ ٱلْقِتَالُ إِذَا فَرِيقٌ مِّنْهُمْ يَخْشَوْنَ ٱلنَّاسَ كَخَشْيَةِ ٱللَّهِ أَوْ أَشَدَّ خَشْيَةً وَقَالُوا۟ رَبَّنَا لِمَ كَتَبْتَ عَلَيْنَا ٱلْقِتَالَ لَوْلَآ أَخَّرْتَنَآ إِلَىٰٓ أَجَلٍ قَرِيبٍ قُلْ مَتَٰعُ ٱلدُّنْيَا قَلِيلٌ وَٱلْـَٔاخِرَةُ خَيْرٌ لِّمَنِ ٱتَّقَىٰ وَلَا تُظْلَمُونَ فَتِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A sọ fún pé: “Ẹ káwọ́ ró (ẹ má ì jagun ẹ̀sìn, àmọ́) ẹ máa kírun, kí ẹ sì máa yọ Zakāh.” Ṣùgbọ́n nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí, ìgbà náà ni apá kan nínú wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn bí ẹni tí ń bẹ̀rù Allāhu tàbí tí ìbẹ̀rù rẹ̀ le koko jùlọ. Wọ́n sì wí pé: “Olúwa wa, nítorí kí ni O fi ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wa lórí? Kúkú lọ́ wa lára di ìgbà díẹ̀ sí i.[1]” Sọ pé: “Bín-íntín ní ìgbádùn ayé, ọ̀run lóore jùlọ fún ẹni tó bá bẹ̀rù Allāhu. Wọn kò sì níí fi (ohun tó tó) ìbójú kóró èso dàbínù ṣàbòsí sí yín.”²

See all translations of this verse →

أَيْنَمَا تَكُونُوا۟ يُدْرِككُّمُ ٱلْمَوْتُ وَلَوْ كُنتُمْ فِى بُرُوجٍ مُّشَيَّدَةٍ وَإِن تُصِبْهُمْ حَسَنَةٌ يَقُولُوا۟ هَٰذِهِۦ مِنْ عِندِ ٱللَّهِ وَإِن تُصِبْهُمْ سَيِّئَةٌ يَقُولُوا۟ هَٰذِهِۦ مِنْ عِندِكَ قُلْ كُلٌّ مِّنْ عِندِ ٱللَّهِ فَمَالِ هَٰٓؤُلَآءِ ٱلْقَوْمِ لَا يَكَادُونَ يَفْقَهُونَ حَدِيثًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelIbikíbi tí ẹ bá wà, ikú yóò pàdé yín, ẹ̀yin ìbáà wà nínú odi ilé orí òkè ilé gíga fíofío. Tí oore (ìkógun) kan bá tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Tí aburú (ìfọ́gun) kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.” Sọ pé: “Gbogbo rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kí ló ń ṣe àwọn ènìyàn wọ̀nyí ná, tí wọn kò fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan.

See all translations of this verse →

مَّآ أَصَابَكَ مِنْ حَسَنَةٍ فَمِنَ ٱللَّهِ وَمَآ أَصَابَكَ مِن سَيِّئَةٍ فَمِن نَّفْسِكَ وَأَرْسَلْنَٰكَ لِلنَّاسِ رَسُولًا وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelOhunkóhun tó bá tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ nínú oore, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Ohunkóhun tí ó bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ nínú aburú, láti ọ̀dọ̀ ara rẹ ni. A rán ọ níṣẹ́ pé kí o jẹ́ Òjíṣẹ́ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.[1]

See all translations of this verse →

مَّن يُطِعِ ٱلرَّسُولَ فَقَدْ أَطَاعَ ٱللَّهَ وَمَن تَوَلَّىٰ فَمَآ أَرْسَلْنَٰكَ عَلَيْهِمْ حَفِيظًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tó bá tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, ó ti tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu. Ẹnikẹ́ni tó bá sì pẹ̀yìndà, A kò rán ọ níṣẹ́ olùṣọ́ lórí wọn.

See all translations of this verse →

وَيَقُولُونَ طَاعَةٌ فَإِذَا بَرَزُوا۟ مِنْ عِندِكَ بَيَّتَ طَآئِفَةٌ مِّنْهُمْ غَيْرَ ٱلَّذِى تَقُولُ وَٱللَّهُ يَكْتُبُ مَا يُبَيِّتُونَ فَأَعْرِضْ عَنْهُمْ وَتَوَكَّلْ عَلَى ٱللَّهِ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń wí pé: “A tẹ̀lé àṣẹ rẹ.” Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ, igun kan nínú wọn máa pètepèrò ní òru n̄ǹkan mìíràn tí ó yàtọ̀ sí èyí tí ó ń sọ (ní ọ̀sán). Allāhu sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n ń pètepèrò rẹ̀ ní òru. Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùgbáralé.

See all translations of this verse →

أَفَلَا يَتَدَبَّرُونَ ٱلْقُرْءَانَ وَلَوْ كَانَ مِنْ عِندِ غَيْرِ ٱللَّهِ لَوَجَدُوا۟ فِيهِ ٱخْتِلَٰفًا كَثِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé wọn kò ronú nípa al-Ƙur’ān ni? Tí ó bá jẹ́ pé ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn yàtọ̀ sí Allāhu, wọn ìbá rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìtakora nínú rẹ̀.[1]

See all translations of this verse →

وَإِذَا جَآءَهُمْ أَمْرٌ مِّنَ ٱلْأَمْنِ أَوِ ٱلْخَوْفِ أَذَاعُوا۟ بِهِۦ وَلَوْ رَدُّوهُ إِلَى ٱلرَّسُولِ وَإِلَىٰٓ أُو۟لِى ٱلْأَمْرِ مِنْهُمْ لَعَلِمَهُ ٱلَّذِينَ يَسْتَنۢبِطُونَهُۥ مِنْهُمْ وَلَوْلَا فَضْلُ ٱللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُۥ لَٱتَّبَعْتُمُ ٱلشَّيْطَٰنَ إِلَّا قَلِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ọ̀rọ̀ ìfàyàbalẹ̀ tàbí ìpáyà kan bá dé bá wọn, wọ́n sì máa tàn án kálẹ̀. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ṣẹ́rí rẹ̀ sí (ọ̀rọ̀) Òjíṣẹ́ àti àwọn aláṣẹ (ìyẹn, àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn) nínú wọn, àwọn tó ń yọ òdodo jáde nínú ọ̀rọ̀ nínú wọn ìbá mọ̀ ọ́n. Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ lórí yín ni, ẹ̀yin ìbá tẹ̀lé aṣ-Ṣaetọ̄n àfi ìba díẹ̀ (nínú yín).[1]

See all translations of this verse →

فَقَٰتِلْ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ لَا تُكَلَّفُ إِلَّا نَفْسَكَ وَحَرِّضِ ٱلْمُؤْمِنِينَ عَسَى ٱللَّهُ أَن يَكُفَّ بَأْسَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَٱللَّهُ أَشَدُّ بَأْسًا وَأَشَدُّ تَنكِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Wọn kò là á bọ ẹnì kan lọ́rùn àfi ìwọ. Kí o sì gbẹ àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóǹgbẹ ogun ẹ̀sìn. Ó ṣeé ṣe kí Allāhu ká ọwọ́ ìjà àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ró. Àti pé Allāhu le jùlọ ní ogun. Ó sì le jùlọ níbi ìjẹni-níyà.

See all translations of this verse →

مَّن يَشْفَعْ شَفَٰعَةً حَسَنَةً يَكُن لَّهُۥ نَصِيبٌ مِّنْهَا وَمَن يَشْفَعْ شَفَٰعَةً سَيِّئَةً يَكُن لَّهُۥ كِفْلٌ مِّنْهَا وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ مُّقِيتًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá ṣìpẹ̀ ìṣìpẹ̀ rere, ó máa ní ìpín kan nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìpẹ̀ ìṣìpẹ̀ aburú, ó máa ní ìpín kan nínú rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan[1].

See all translations of this verse →

وَإِذَا حُيِّيتُم بِتَحِيَّةٍ فَحَيُّوا۟ بِأَحْسَنَ مِنْهَآ أَوْ رُدُّوهَآ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍ حَسِيبًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael86. Nígbà tí wọ́n bá ki yín ní kíkí kan, ẹ kí wọn (padà) pẹ̀lú èyí tó dára jù ú lọ tàbí kí ẹ dá a padà (pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ki yín). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣírò lórí gbogbo n̄ǹkan.

See all translations of this verse →

ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ لَيَجْمَعَنَّكُمْ إِلَىٰ يَوْمِ ٱلْقِيَٰمَةِ لَا رَيْبَ فِيهِ وَمَنْ أَصْدَقُ مِنَ ٱللَّهِ حَدِيثًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Dájúdájú Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ta ló sọ̀dodo ọ̀rọ̀ ju Allāhu?

See all translations of this verse →

فَمَا لَكُمْ فِى ٱلْمُنَٰفِقِينَ فِئَتَيْنِ وَٱللَّهُ أَرْكَسَهُم بِمَا كَسَبُوٓا۟ أَتُرِيدُونَ أَن تَهْدُوا۟ مَنْ أَضَلَّ ٱللَّهُ وَمَن يُضْلِلِ ٱللَّهُ فَلَن تَجِدَ لَهُۥ سَبِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ni ó máa mu yín pín sí ìjọ méjì nípa àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí! Ṣebí Allāhu l’Ó dá wọn padà sẹ́yìn[1] nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ṣé ẹ fẹ́ fi ẹni tí Allāhu ṣì lọ́nà mọ̀nà ni? Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, o ò níí rí ọ̀nà kan fún un.

See all translations of this verse →

وَدُّوا۟ لَوْ تَكْفُرُونَ كَمَا كَفَرُوا۟ فَتَكُونُونَ سَوَآءً فَلَا تَتَّخِذُوا۟ مِنْهُمْ أَوْلِيَآءَ حَتَّىٰ يُهَاجِرُوا۟ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ فَإِن تَوَلَّوْا۟ فَخُذُوهُمْ وَٱقْتُلُوهُمْ حَيْثُ وَجَدتُّمُوهُمْ وَلَا تَتَّخِذُوا۟ مِنْهُمْ وَلِيًّا وَلَا نَصِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n fẹ́ kí ẹ ṣàì gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣàì gbàgbọ́, kí ẹ lè jọ di ẹgbẹ́ kan náà. Nítorí náà, ẹ má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò nínú wọn títí wọ́n fi máa kúrò nínú ìlú ẹbọ wá sí ìlú ’Islām nítorí ẹ̀sìn Allāhu. Tí wọ́n bá kẹ̀yìn (sí ìgbàgbọ́ òdodo), ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ẹ bá ti bá wọn. Kí ẹ sì má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò àti olùrànlọ́wọ́ kan nínú wọn.

See all translations of this verse →

إِلَّا ٱلَّذِينَ يَصِلُونَ إِلَىٰ قَوْمٍۭ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُم مِّيثَٰقٌ أَوْ جَآءُوكُمْ حَصِرَتْ صُدُورُهُمْ أَن يُقَٰتِلُوكُمْ أَوْ يُقَٰتِلُوا۟ قَوْمَهُمْ وَلَوْ شَآءَ ٱللَّهُ لَسَلَّطَهُمْ عَلَيْكُمْ فَلَقَٰتَلُوكُمْ فَإِنِ ٱعْتَزَلُوكُمْ فَلَمْ يُقَٰتِلُوكُمْ وَأَلْقَوْا۟ إِلَيْكُمُ ٱلسَّلَمَ فَمَا جَعَلَ ٱللَّهُ لَكُمْ عَلَيْهِمْ سَبِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀyàfi àwọn tó bá darapọ̀ mọ́ ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Tàbí wọ́n wá ba yín, tí ọkàn wọn ti pami láti ba yín jà tàbí láti bá àwọn ènìyàn wọn jà. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá fún wọn lágbára (ọkàn-akin) lórí yín, wọn ìbá sì jà yín lógun. Nítorí náà, tí wọ́n bá yẹra fún yín, tí wọn kò sì jà yín lógun, tí wọ́n sì juwọ́ sílẹ̀ fún yín, nígbà náà Allāhu kò fún yín ní ọ̀nà lórí wọn (láti jà wọ́n lógun).

See all translations of this verse →

سَتَجِدُونَ ءَاخَرِينَ يُرِيدُونَ أَن يَأْمَنُوكُمْ وَيَأْمَنُوا۟ قَوْمَهُمْ كُلَّ مَا رُدُّوٓا۟ إِلَى ٱلْفِتْنَةِ أُرْكِسُوا۟ فِيهَا فَإِن لَّمْ يَعْتَزِلُوكُمْ وَيُلْقُوٓا۟ إِلَيْكُمُ ٱلسَّلَمَ وَيَكُفُّوٓا۟ أَيْدِيَهُمْ فَخُذُوهُمْ وَٱقْتُلُوهُمْ حَيْثُ ثَقِفْتُمُوهُمْ وَأُو۟لَٰٓئِكُمْ جَعَلْنَا لَكُمْ عَلَيْهِمْ سُلْطَٰنًا مُّبِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ máa rí àwọn ẹlòmíìràn tí wọ́n ń fẹ́ ààbò lọ́dọ̀ yín (wọ́n bá ní àwọn gba ’Islām), wọ́n tún ń fẹ́ ààbò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọn (wọ́n tún ń bá wọn ṣẹbọ), ìgbàkígbà tí wọ́n bá dá wọn padà sínú ìfòòró (ìbọ̀rìṣà), wọ́n sì ń padà sínú rẹ̀. Tí wọn kò bá yẹra fún yín, tí wọn kò juwọ́ sílẹ̀ fún yín, tí wọn kò sì dáwọ́ jíjà yín lógun dúró, nígbà náà ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu sì fún yín ní agbára tó yanjú lórí wọn (láti jà wọ́n lógun).

See all translations of this verse →

وَمَا كَانَ لِمُؤْمِنٍ أَن يَقْتُلَ مُؤْمِنًا إِلَّا خَطَـًٔا وَمَن قَتَلَ مُؤْمِنًا خَطَـًٔا فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُّؤْمِنَةٍ وَدِيَةٌ مُّسَلَّمَةٌ إِلَىٰٓ أَهْلِهِۦٓ إِلَّآ أَن يَصَّدَّقُوا۟ فَإِن كَانَ مِن قَوْمٍ عَدُوٍّ لَّكُمْ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُّؤْمِنَةٍ وَإِن كَانَ مِن قَوْمٍۭ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَهُم مِّيثَٰقٌ فَدِيَةٌ مُّسَلَّمَةٌ إِلَىٰٓ أَهْلِهِۦ وَتَحْرِيرُ رَقَبَةٍ مُّؤْمِنَةٍ فَمَن لَّمْ يَجِدْ فَصِيَامُ شَهْرَيْنِ مُتَتَابِعَيْنِ تَوْبَةً مِّنَ ٱللَّهِ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò lẹ́tọ̀ọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo kan láti pa onígbàgbọ́ òdodo kan àyàfi tí ó bá ṣèèsì. Ẹni tí ó bá sì ṣèèsì pa onígbàgbọ́ òdodo kan, ó máa tú ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ó tún máa san owó ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn òkú àfi tí wọ́n bá fi tọrẹ (fún un, tí wọ́n bá yọ̀ǹda rẹ̀ fún un). Tí ó bá sì wà nínú àwọn ènìyàn kan tí ó jẹ́ ọ̀tá fún yín, onígbàgbọ́ sì ni (ẹni tí wọ́n ṣèèsì pa), ó máa tú ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Tí ó bá jẹ́ ìjọ tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn (ni ẹni tí wọ́n ṣèèsì pa), ó máa san owó ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó tún máa tú ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹni tí kò bá rí (ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo), ó máa gba ààwẹ̀ oṣù méjì ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. (Ọ̀nà) ìronúpìwàdà kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (nìyí). Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

وَمَن يَقْتُلْ مُؤْمِنًا مُّتَعَمِّدًا فَجَزَآؤُهُۥ جَهَنَّمُ خَٰلِدًا فِيهَا وَغَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيْهِ وَلَعَنَهُۥ وَأَعَدَّ لَهُۥ عَذَابًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ pa onígbàgbọ́ òdodo kan, iná Jahanamọ ni ẹ̀san rẹ̀. Olùṣegbére ni nínú rẹ̀. Allāhu yóò bínú sí i. Ó máa ṣẹ́bilé e. Ó sì ti pèsè ìyà ńlá sílẹ̀ dè é.

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِذَا ضَرَبْتُمْ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ فَتَبَيَّنُوا۟ وَلَا تَقُولُوا۟ لِمَنْ أَلْقَىٰٓ إِلَيْكُمُ ٱلسَّلَٰمَ لَسْتَ مُؤْمِنًا تَبْتَغُونَ عَرَضَ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا فَعِندَ ٱللَّهِ مَغَانِمُ كَثِيرَةٌ كَذَٰلِكَ كُنتُم مِّن قَبْلُ فَمَنَّ ٱللَّهُ عَلَيْكُمْ فَتَبَيَّنُوٓا۟ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá wà lórí ìrìn-àjò ní ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ogun ẹ̀sìn), ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí ẹ fi mọ òdodo (nípa àwọn ènìyàn). Ẹ sì má ṣe sọ fún ẹni tí ó bá sálámọ̀ si yín pé kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo látara pé ẹ̀yin ń wá dúkìá ìṣẹ̀mí ayé. Ní ọ̀dọ̀ Allāhu kúkú ni ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọrọ̀ ogun wà. Báyẹn ni ẹ̀yin náà ṣe wà tẹ́lẹ̀, Allāhu sì ṣe ìdẹ̀ra (ẹ̀sìn) fún yín. Nítorí náà, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí ẹ fi mọ òdodo (nípa àwọn ènìyàn náà). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

See all translations of this verse →

لَّا يَسْتَوِى ٱلْقَٰعِدُونَ مِنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ غَيْرُ أُو۟لِى ٱلضَّرَرِ وَٱلْمُجَٰهِدُونَ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ بِأَمْوَٰلِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ فَضَّلَ ٱللَّهُ ٱلْمُجَٰهِدِينَ بِأَمْوَٰلِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ عَلَى ٱلْقَٰعِدِينَ دَرَجَةً وَكُلًّا وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلْحُسْنَىٰ وَفَضَّلَ ٱللَّهُ ٱلْمُجَٰهِدِينَ عَلَى ٱلْقَٰعِدِينَ أَجْرًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn olùjókòó sínú ilé nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, yàtọ̀ sí àwọn aláìlera, àti àwọn olùjagun ní ojú-ọ̀nà Allāhu pẹ̀lú dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn, wọn kò dọ́gba. Allāhu fi ipò kan ṣoore àjùlọ fún àwọn olùjagun ní ojú-ọ̀nà Allāhu pẹ̀lú dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn lórí àwọn olùjókòó sínú ilé. Olúkùlùkù (wọn) ni Allāhu ṣe àdéhùn ohun rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) fún. Allāhu gbọ́lá fún àwọn olùjagun ẹ̀sìn lórí àwọn olùjókòó sínú ilé pẹ̀lú ẹ̀san ńlá;

See all translations of this verse →

دَرَجَٰتٍ مِّنْهُ وَمَغْفِرَةً وَرَحْمَةً وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelàwọn ipò kan àti àforíjìn àti àánú láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ تَوَفَّىٰهُمُ ٱلْمَلَٰٓئِكَةُ ظَالِمِىٓ أَنفُسِهِمْ قَالُوا۟ فِيمَ كُنتُمْ قَالُوا۟ كُنَّا مُسْتَضْعَفِينَ فِى ٱلْأَرْضِ قَالُوٓا۟ أَلَمْ تَكُنْ أَرْضُ ٱللَّهِ وَٰسِعَةً فَتُهَاجِرُوا۟ فِيهَا فَأُو۟لَٰٓئِكَ مَأْوَىٰهُمْ جَهَنَّمُ وَسَآءَتْ مَصِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tí mọlāika gba ẹ̀mí wọn, (lásìkò) tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, (àwọn mọlāika) sọ pé: “Kí ni ẹ̀ ń ṣe (nínú ẹ̀sìn)?[1]” Wọ́n wí pé: “Wọ́n dá wa lágara lórí ilẹ̀ ni.” (Àwọn mọlāika) sọ pé: “Ṣé ilẹ̀ Allāhu kò fẹ̀ tó (fún yín) láti gbé ẹ̀sìn yín sá lórí ilẹ̀?” Àwọn wọ̀nyẹn, iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ó sì burú ní ìkángun.

See all translations of this verse →

إِلَّا ٱلْمُسْتَضْعَفِينَ مِنَ ٱلرِّجَالِ وَٱلنِّسَآءِ وَٱلْوِلْدَٰنِ لَا يَسْتَطِيعُونَ حِيلَةً وَلَا يَهْتَدُونَ سَبِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀyàfi àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tí kò ní ìkápá ọgbọ́n kan, wọn kò sì dá ọ̀nà mọ̀ (dé ìlú Mọdīnah).

See all translations of this verse →

فَأُو۟لَٰٓئِكَ عَسَى ٱللَّهُ أَن يَعْفُوَ عَنْهُمْ وَكَانَ ٱللَّهُ عَفُوًّا غَفُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn, ó súnmọ́ kí Allāhu ṣàmójúkúrò fún wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Alámòjúúkúrò, Aláforíjìn.

See all translations of this verse →

وَمَن يُهَاجِرْ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ يَجِدْ فِى ٱلْأَرْضِ مُرَٰغَمًا كَثِيرًا وَسَعَةً وَمَن يَخْرُجْ مِنۢ بَيْتِهِۦ مُهَاجِرًا إِلَى ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ ثُمَّ يُدْرِكْهُ ٱلْمَوْتُ فَقَدْ وَقَعَ أَجْرُهُۥ عَلَى ٱللَّهِ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá gbé ìlú rẹ̀ jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu, ó máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ibùsásí àti ìgbàláyè lórí ilẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde kúrò nínú ilé rẹ̀ (tí ó jẹ́) olùfìlú-sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà tí ikú bá a (lójú ọ̀nà), ẹ̀san rẹ̀ kúkú ti dúró lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.[1]

See all translations of this verse →

وَإِذَا ضَرَبْتُمْ فِى ٱلْأَرْضِ فَلَيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ أَن تَقْصُرُوا۟ مِنَ ٱلصَّلَوٰةِ إِنْ خِفْتُمْ أَن يَفْتِنَكُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓا۟ إِنَّ ٱلْكَٰفِرِينَ كَانُوا۟ لَكُمْ عَدُوًّا مُّبِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ẹ bá ṣe ìrìn-àjò lórí ilẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín láti dín ìrun kù,[1] tí ẹ̀yin bá ń bẹ̀rù pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò fòòró yín. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́, wọ́n jẹ́ ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.

See all translations of this verse →

وَإِذَا كُنتَ فِيهِمْ فَأَقَمْتَ لَهُمُ ٱلصَّلَوٰةَ فَلْتَقُمْ طَآئِفَةٌ مِّنْهُم مَّعَكَ وَلْيَأْخُذُوٓا۟ أَسْلِحَتَهُمْ فَإِذَا سَجَدُوا۟ فَلْيَكُونُوا۟ مِن وَرَآئِكُمْ وَلْتَأْتِ طَآئِفَةٌ أُخْرَىٰ لَمْ يُصَلُّوا۟ فَلْيُصَلُّوا۟ مَعَكَ وَلْيَأْخُذُوا۟ حِذْرَهُمْ وَأَسْلِحَتَهُمْ وَدَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لَوْ تَغْفُلُونَ عَنْ أَسْلِحَتِكُمْ وَأَمْتِعَتِكُمْ فَيَمِيلُونَ عَلَيْكُم مَّيْلَةً وَٰحِدَةً وَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ إِن كَانَ بِكُمْ أَذًى مِّن مَّطَرٍ أَوْ كُنتُم مَّرْضَىٰٓ أَن تَضَعُوٓا۟ أَسْلِحَتَكُمْ وَخُذُوا۟ حِذْرَكُمْ إِنَّ ٱللَّهَ أَعَدَّ لِلْكَٰفِرِينَ عَذَابًا مُّهِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí o bá wà láààrin wọn, gbé ìrun dúró fún wọn. Kí igun kan nínú wọn kírun pẹ̀lú rẹ, kí wọ́n mú n̄ǹkan ìjagun wọn lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n bá sì forí kanlẹ̀ (tí wọ́n parí ìrun), kí wọn bọ́ sẹ́yìn yín, kí igun mìíràn tí kò tí ì kírun wá kírun pẹ̀lú rẹ. Kí wọ́n mú ìṣọ́ra wọn[1] àti n̄ǹkan ìjagun wọn lọ́wọ́. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ kí ẹ gbàgbé àwọn n̄ǹkan ìjagun yín àti n̄ǹkan ìgbádùn yín (ẹrù oúnjẹ yín), kí wọ́n lè kọlù yín ní ẹ̀ẹ̀ kan náà. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín tí ó bá jẹ́ pé ìpalára kan ń bẹ fún yín látara òjò tàbí (pé) ẹ jẹ́ aláìsàn, pé kí ẹ fi n̄ǹkan ìjagun yín sílẹ̀ (lórí ìrun). Ẹ mú n̄ǹkan ìṣọ́ra yín lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu ti pèsè ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

See all translations of this verse →

فَإِذَا قَضَيْتُمُ ٱلصَّلَوٰةَ فَٱذْكُرُوا۟ ٱللَّهَ قِيَٰمًا وَقُعُودًا وَعَلَىٰ جُنُوبِكُمْ فَإِذَا ٱطْمَأْنَنتُمْ فَأَقِيمُوا۟ ٱلصَّلَوٰةَ إِنَّ ٱلصَّلَوٰةَ كَانَتْ عَلَى ٱلْمُؤْمِنِينَ كِتَٰبًا مَّوْقُوتًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ẹ bá parí ìrun, kí ẹ ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu ní ìdúró, ìjókòó àti ìdùbúlẹ̀ yín. Nígbà tí ẹ bá sì fọkàn balẹ̀, kí ẹ kírun (ní pípé). Dájúdájú ìrun kíkí jẹ́ ọ̀ran-anyàn tí A fi àkókò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

وَلَا تَهِنُوا۟ فِى ٱبْتِغَآءِ ٱلْقَوْمِ إِن تَكُونُوا۟ تَأْلَمُونَ فَإِنَّهُمْ يَأْلَمُونَ كَمَا تَأْلَمُونَ وَتَرْجُونَ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا يَرْجُونَ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ má ṣe káàárẹ̀ nípa wíwá àwọn ènìyàn náà (láti jà wọ́n lógun). Tí ẹ̀yin bá ń jẹ ìrora (ọgbẹ́), dájúdájú àwọn náà ń jẹ ìrora (ọgbẹ́) gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe ń jẹ ìrora rẹ̀. Ẹ̀yin sì ń retí ohun tí àwọn kò retí lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

إِنَّآ أَنزَلْنَآ إِلَيْكَ ٱلْكِتَٰبَ بِٱلْحَقِّ لِتَحْكُمَ بَيْنَ ٱلنَّاسِ بِمَآ أَرَىٰكَ ٱللَّهُ وَلَا تَكُن لِّلْخَآئِنِينَ خَصِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo nítorí kí o lè máa ṣèdájọ́ láààrin àwọn ènìyàn pẹ̀lú ohun tí Allāhu fi hàn ọ́. Má ṣe jẹ́ olùgbèjà fún àwọn oníjàǹbá.[1]

See all translations of this verse →

وَٱسْتَغْفِرِ ٱللَّهَ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورًا رَّحِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu,[1] dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

وَلَا تُجَٰدِلْ عَنِ ٱلَّذِينَ يَخْتَانُونَ أَنفُسَهُمْ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ مَن كَانَ خَوَّانًا أَثِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMá ṣe bá àwọn tó ń jàǹbá ẹ̀mí ara wọn wá àwíjàre. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ oníjàǹbá, ẹlẹ́ṣẹ̀.[1]

See all translations of this verse →

يَسْتَخْفُونَ مِنَ ٱلنَّاسِ وَلَا يَسْتَخْفُونَ مِنَ ٱللَّهِ وَهُوَ مَعَهُمْ إِذْ يُبَيِّتُونَ مَا لَا يَرْضَىٰ مِنَ ٱلْقَوْلِ وَكَانَ ٱللَّهُ بِمَا يَعْمَلُونَ مُحِيطًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń fi ara pamọ́ fún àwọn ènìyàn, wọn kò sì lè fara pamọ́ fún Allāhu (nítorí pé) Ó wà pẹ̀lú wọn (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀) nígbà tí wọ́n ń pètepèrò lórí ohun tí (Allāhu) kò yọ́nú sí nínú ọ̀rọ̀ sísọ.[1] Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

See all translations of this verse →

هَٰٓأَنتُمْ هَٰٓؤُلَآءِ جَٰدَلْتُمْ عَنْهُمْ فِى ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا فَمَن يُجَٰدِلُ ٱللَّهَ عَنْهُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ أَم مَّن يَكُونُ عَلَيْهِمْ وَكِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKíyè sí i, ẹ̀yin wọ̀nyí ni ẹ̀ ń bá wọn mú àwíjàre wá nílé ayé. Ta ni ó máa bá wọn mú àwíjàre wá ní ọ̀dọ̀ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde? Tàbí ta ni ó máa jẹ́ aláàbò fún wọn?

See all translations of this verse →

وَمَن يَعْمَلْ سُوٓءًا أَوْ يَظْلِمْ نَفْسَهُۥ ثُمَّ يَسْتَغْفِرِ ٱللَّهَ يَجِدِ ٱللَّهَ غَفُورًا رَّحِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ aburú kan tàbí tí ó ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀, lẹ́yìn náà tí ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu, ó máa bá Allāhu ní Aláforíjìn, Aláàánú.

See all translations of this verse →

وَمَن يَكْسِبْ إِثْمًا فَإِنَّمَا يَكْسِبُهُۥ عَلَىٰ نَفْسِهِۦ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, ó dá a fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

وَمَن يَكْسِبْ خَطِيٓـَٔةً أَوْ إِثْمًا ثُمَّ يَرْمِ بِهِۦ بَرِيٓـًٔا فَقَدِ ٱحْتَمَلَ بُهْتَٰنًا وَإِثْمًا مُّبِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá ṣe àṣìṣe kan tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kan, lẹ́yìn náà, ó dì í ru aláìmọwọ́-mẹsẹ̀, ó ti dá ọ̀ràn ìparọ́mọ́ni àti ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé.

See all translations of this verse →

وَلَوْلَا فَضْلُ ٱللَّهِ عَلَيْكَ وَرَحْمَتُهُۥ لَهَمَّت طَّآئِفَةٌ مِّنْهُمْ أَن يُضِلُّوكَ وَمَا يُضِلُّونَ إِلَّآ أَنفُسَهُمْ وَمَا يَضُرُّونَكَ مِن شَىْءٍ وَأَنزَلَ ٱللَّهُ عَلَيْكَ ٱلْكِتَٰبَ وَٱلْحِكْمَةَ وَعَلَّمَكَ مَا لَمْ تَكُن تَعْلَمُ وَكَانَ فَضْلُ ٱللَّهِ عَلَيْكَ عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí kì í bá ṣe ti oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ tí ń bẹ lórí rẹ ni, igun kan nínú wọn ìbá ti gbèrò láti ṣì ọ́ lọ́nà. Wọn kò sì níí ṣi ẹnì kan lọ́nà àfi ẹ̀mí ara wọn. Wọn kò sì lè fi n̄ǹkan kan kó ìnira bá ọ. Allāhu sì sọ Tírà àti òye ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah) kalẹ̀ fún ọ. Ó tún fi ohun tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ mọ̀ ọ́;[1] oore àjùlọ Allāhu lórí rẹ jẹ́ ohun tó tóbi.

See all translations of this verse →

لَّا خَيْرَ فِى كَثِيرٍ مِّن نَّجْوَىٰهُمْ إِلَّا مَنْ أَمَرَ بِصَدَقَةٍ أَوْ مَعْرُوفٍ أَوْ إِصْلَٰحٍۭ بَيْنَ ٱلنَّاسِ وَمَن يَفْعَلْ ذَٰلِكَ ٱبْتِغَآءَ مَرْضَاتِ ٱللَّهِ فَسَوْفَ نُؤْتِيهِ أَجْرًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sí oore kan nínú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn àfi ẹni tí ó bá pàṣẹ ọrẹ títa tàbí iṣẹ́ rere tàbí àtúnṣe láààrin àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn láti fi wá ìyọ́nú Allāhu, láìpẹ́ A máa fún un ní ẹ̀san ńlá.

See all translations of this verse →

وَمَن يُشَاقِقِ ٱلرَّسُولَ مِنۢ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُ ٱلْهُدَىٰ وَيَتَّبِعْ غَيْرَ سَبِيلِ ٱلْمُؤْمِنِينَ نُوَلِّهِۦ مَا تَوَلَّىٰ وَنُصْلِهِۦ جَهَنَّمَ وَسَآءَتْ مَصِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá yapa Òjíṣẹ́ náà lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú han sí i kedere, tí ó tún tẹ̀lé ọ̀nà tó yàtọ̀ sí ti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, A óò dojú rẹ̀ kọ ohun tí ó dojú ara rẹ̀ kọ (nínú ìṣìnà),A sì máa mú un wọ inú iná Jahanamọ. Ó sì burú ní ìkángun.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَغْفِرُ أَن يُشْرَكَ بِهِۦ وَيَغْفِرُ مَا دُونَ ذَٰلِكَ لِمَن يَشَآءُ وَمَن يُشْرِكْ بِٱللَّهِ فَقَدْ ضَلَّ ضَلَٰلًۢا بَعِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. Ó sì máa ṣàforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́.[1] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà tó jìnnà.

See all translations of this verse →

إِن يَدْعُونَ مِن دُونِهِۦٓ إِلَّآ إِنَٰثًا وَإِن يَدْعُونَ إِلَّا شَيْطَٰنًا مَّرِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọn kò pe kiní kan lẹ́yìn Allāhu bí kò ṣe àwọn abo òrìṣà.[1] Wọn kò sì pe kiní kan bí kò ṣe ṣaetọ̄n olùyapa.

See all translations of this verse →

لَّعَنَهُ ٱللَّهُ وَقَالَ لَأَتَّخِذَنَّ مِنْ عِبَادِكَ نَصِيبًا مَّفْرُوضًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu ṣẹ́bilé e. Ó sì wí pé: “Dájúdájú mo máa mú ìpín tí wọ́n pín fún mi nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ.

See all translations of this verse →

وَلَأُضِلَّنَّهُمْ وَلَأُمَنِّيَنَّهُمْ وَلَـَٔامُرَنَّهُمْ فَلَيُبَتِّكُنَّ ءَاذَانَ ٱلْأَنْعَٰمِ وَلَـَٔامُرَنَّهُمْ فَلَيُغَيِّرُنَّ خَلْقَ ٱللَّهِ وَمَن يَتَّخِذِ ٱلشَّيْطَٰنَ وَلِيًّا مِّن دُونِ ٱللَّهِ فَقَدْ خَسِرَ خُسْرَانًا مُّبِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú mo máa ṣì wọ́n lọ́nà. Dájúdájú mo máa tàn wọ́n jẹ. Dájúdájú mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa gé etí ẹran-ọ̀sìn (láti yà á sọ́tọ̀ fún òrìṣà). Dájúdájú mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa yí ẹ̀sìn Allāhu padà.”[1] Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú aṣ-Ṣaetọ̄n ní ọ̀rẹ́ lẹ́yìn Allāhu, dájúdájú ó ti ṣòfò ní òfò pọ́nńbélé.

See all translations of this verse →

يَعِدُهُمْ وَيُمَنِّيهِمْ وَمَا يَعِدُهُمُ ٱلشَّيْطَٰنُ إِلَّا غُرُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ ń ṣàdéhùn fún wọn, ó sì ń tàn wọ́n jẹ. Aṣ-Ṣaetọ̄n kò sì ṣàdéhùn kan fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn.

See all translations of this verse →

أُو۟لَٰٓئِكَ مَأْوَىٰهُمْ جَهَنَّمُ وَلَا يَجِدُونَ عَنْهَا مَحِيصًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn wọ̀nyẹn, iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn; wọn kò níí rí ibùsásí kan (wọn kò níí rí ọ̀nà láti sá jàde kúrò nínú rẹ̀).

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ سَنُدْخِلُهُمْ جَنَّٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدًا وَعْدَ ٱللَّهِ حَقًّا وَمَنْ أَصْدَقُ مِنَ ٱللَّهِ قِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere, A máa mú wọn wọ inu àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọn nínú rẹ̀ títí láéláé. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní ti òdodo. Ta sì ni ó sọ òdodo ju Allāhu?

See all translations of this verse →

لَّيْسَ بِأَمَانِيِّكُمْ وَلَآ أَمَانِىِّ أَهْلِ ٱلْكِتَٰبِ مَن يَعْمَلْ سُوٓءًا يُجْزَ بِهِۦ وَلَا يَجِدْ لَهُۥ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيًّا وَلَا نَصِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKì í ṣe ìfẹ́-ọkàn yín, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìfẹ́-ọkàn àwọn onítírà (ni òṣùwọ̀n ìdájọ́ ọ̀run. Àmọ́,) ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ aburú kan, A óò san án ní ẹ̀san rẹ̀; kò sì níí rí aláfẹ̀yìntì tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu.[1]

See all translations of this verse →

وَمَن يَعْمَلْ مِنَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ مِن ذَكَرٍ أَوْ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَأُو۟لَٰٓئِكَ يَدْخُلُونَ ٱلْجَنَّةَ وَلَا يُظْلَمُونَ نَقِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ rere, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, onígbàgbọ́ òdodo sì ni, àwọn wọ̀nyẹn máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí fi (òdiwọ̀n) àmì ẹ̀yìn kóró èso dàbínú ṣàbòsí sí wọn.

See all translations of this verse →

وَمَنْ أَحْسَنُ دِينًا مِّمَّنْ أَسْلَمَ وَجْهَهُۥ لِلَّهِ وَهُوَ مُحْسِنٌ وَٱتَّبَعَ مِلَّةَ إِبْرَٰهِيمَ حَنِيفًا وَٱتَّخَذَ ٱللَّهُ إِبْرَٰهِيمَ خَلِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTa l’ó dára ní ẹ̀sìn ju ẹni tí ó jura rẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu, olùṣe-rere sì tún ni, ó tún tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-’Islām? Allāhu sì mú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní àyànfẹ́.

See all translations of this verse →

وَلِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ وَكَانَ ٱللَّهُ بِكُلِّ شَىْءٍ مُّحِيطًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTi Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa gbogbo n̄ǹkan.

See all translations of this verse →

وَيَسْتَفْتُونَكَ فِى ٱلنِّسَآءِ قُلِ ٱللَّهُ يُفْتِيكُمْ فِيهِنَّ وَمَا يُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ فِى ٱلْكِتَٰبِ فِى يَتَٰمَى ٱلنِّسَآءِ ٱلَّٰتِى لَا تُؤْتُونَهُنَّ مَا كُتِبَ لَهُنَّ وَتَرْغَبُونَ أَن تَنكِحُوهُنَّ وَٱلْمُسْتَضْعَفِينَ مِنَ ٱلْوِلْدَٰنِ وَأَن تَقُومُوا۟ لِلْيَتَٰمَىٰ بِٱلْقِسْطِ وَمَا تَفْعَلُوا۟ مِنْ خَيْرٍ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِهِۦ عَلِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń bi ọ́ léèrè ìdájọ́ nípa àwọn obìnrin. Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń sọ ìdájọ́ wọn fún yín. Ohun tí wọ́n ń ké fún yín nínú Tírà (al-Ƙur’ān náà ń sọ ìdájọ́ fún yín) nípa àwọn ọmọ-òrukàn lóbìnrin tí ẹ kì í fún ní ohun tí wọ́n kọ fún wọn (nínú ogún), tí ẹ tún ń ṣojú-kòkòrò pé ẹ fẹ́ fẹ́ wọn àti nípa àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọmọdé (tí ẹ̀ ń jẹ ogún wọn mọ́lẹ̀.) àti nípa pé kí ẹ dúró ti àwọn ọmọ òrukàn pẹ̀lú déédé. Ohunkóhun tí ẹ bá sì ṣe ní rere, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀.

See all translations of this verse →

وَإِنِ ٱمْرَأَةٌ خَافَتْ مِنۢ بَعْلِهَا نُشُوزًا أَوْ إِعْرَاضًا فَلَا جُنَاحَ عَلَيْهِمَآ أَن يُصْلِحَا بَيْنَهُمَا صُلْحًا وَٱلصُّلْحُ خَيْرٌ وَأُحْضِرَتِ ٱلْأَنفُسُ ٱلشُّحَّ وَإِن تُحْسِنُوا۟ وَتَتَّقُوا۟ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí obìnrin kan bá páyà oríkunkun tàbí ìkẹ̀yìnsí láti ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì pé kí wọ́n ṣe àtúnṣe láààrin ara wọn. Àtúnṣe sì dára júlọ. Wọ́n sì ti fi ahun àti ọ̀kánjúà ṣíṣe sínú ẹ̀mí ènìyàn. Tí ẹ bá ṣe rere, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.[1]

See all translations of this verse →

وَلَن تَسْتَطِيعُوٓا۟ أَن تَعْدِلُوا۟ بَيْنَ ٱلنِّسَآءِ وَلَوْ حَرَصْتُمْ فَلَا تَمِيلُوا۟ كُلَّ ٱلْمَيْلِ فَتَذَرُوهَا كَٱلْمُعَلَّقَةِ وَإِن تُصْلِحُوا۟ وَتَتَّقُوا۟ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورًا رَّحِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ kò lè ṣe déédé (nínú ìfẹ́) láààrin àwọn obìnrin, ẹ ò báà jẹ̀rankàn rẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe fì síbì kan tán pátápátá, kí ẹ wá pa (ẹnì kan) tì bí ohun tí wọ́n gbékọ́ ara ilé. Tí ẹ bá ṣàtúnṣe, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

وَإِن يَتَفَرَّقَا يُغْنِ ٱللَّهُ كُلًّا مِّن سَعَتِهِۦ وَكَانَ ٱللَّهُ وَٰسِعًا حَكِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí àwọn méjèèjì bá sì pínyà, Allāhu yóò rọ ìkíní kejì lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀ tó gbòòrò. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbòòrò (nínú ọrọ̀), Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

وَلِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ وَلَقَدْ وَصَّيْنَا ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَٰبَ مِن قَبْلِكُمْ وَإِيَّاكُمْ أَنِ ٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ وَإِن تَكْفُرُوا۟ فَإِنَّ لِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ وَكَانَ ٱللَّهُ غَنِيًّا حَمِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTi Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Dájúdájú A ti pa á láṣẹ fún àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti ẹ̀yin náa pé kí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Tí ẹ bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn (tí ẹyìn tọ́ sí).

See all translations of this verse →

وَلِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTi Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Olùṣọ́.

See all translations of this verse →

إِن يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ أَيُّهَا ٱلنَّاسُ وَيَأْتِ بِـَٔاخَرِينَ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ ذَٰلِكَ قَدِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí (Allāhu) bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò lórí ilẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn. Ó sì máa mú àwọn mìíràn wá. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí ìyẹn.

See all translations of this verse →

مَّن كَانَ يُرِيدُ ثَوَابَ ٱلدُّنْيَا فَعِندَ ٱللَّهِ ثَوَابُ ٱلدُّنْيَا وَٱلْـَٔاخِرَةِ وَكَانَ ٱللَّهُ سَمِيعًۢا بَصِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ẹ̀san nílé ayé, ṣebí lọ́dọ̀ Allāhu ní ẹ̀san ti ayé àti ti ọ̀run wà. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbọ́, Olùríran.

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ كُونُوا۟ قَوَّٰمِينَ بِٱلْقِسْطِ شُهَدَآءَ لِلَّهِ وَلَوْ عَلَىٰٓ أَنفُسِكُمْ أَوِ ٱلْوَٰلِدَيْنِ وَٱلْأَقْرَبِينَ إِن يَكُنْ غَنِيًّا أَوْ فَقِيرًا فَٱللَّهُ أَوْلَىٰ بِهِمَا فَلَا تَتَّبِعُوا۟ ٱلْهَوَىٰٓ أَن تَعْدِلُوا۟ وَإِن تَلْوُۥٓا۟ أَوْ تُعْرِضُوا۟ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ olùdúró ṣinṣin lórí déédé nítorí ti Allāhu nígbà tí ẹ bá ń jẹ́rìí, kódà kí (ẹ̀rí jíjẹ́ náà) tako ẹ̀yin fúnra yín tàbí àwọn òbí méjèèjì àti àwọn ẹbí; yálà ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí aláìní, Allāhu súnmọ́ (yín) ju àwọn méjèèjì. Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú láti má ṣe déédé. Tí ẹ bá yí ojú-ọ̀rọ̀ sódì tàbí tí ẹ bá gbúnrí kúrò (níbi déédé), dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.[1]

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ ءَامِنُوا۟ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَٱلْكِتَٰبِ ٱلَّذِى نَزَّلَ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ وَٱلْكِتَٰبِ ٱلَّذِىٓ أَنزَلَ مِن قَبْلُ وَمَن يَكْفُرْ بِٱللَّهِ وَمَلَٰٓئِكَتِهِۦ وَكُتُبِهِۦ وَرُسُلِهِۦ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ فَقَدْ ضَلَّ ضَلَٰلًۢا بَعِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbàgbọ́ dáadáa nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí (Allāhu) sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí Ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà tó jìnnà tefétefé.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ ثُمَّ كَفَرُوا۟ ثُمَّ ءَامَنُوا۟ ثُمَّ كَفَرُوا۟ ثُمَّ ٱزْدَادُوا۟ كُفْرًا لَّمْ يَكُنِ ٱللَّهُ لِيَغْفِرَ لَهُمْ وَلَا لِيَهْدِيَهُمْ سَبِيلًۢا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n sì lékún sí i nínú àìgbàgbọ́, Allāhu kò níí forí jìn wọ́n, kò sì níí fí ọ̀nà mọ̀ wọ́n.[1]

See all translations of this verse →

بَشِّرِ ٱلْمُنَٰفِقِينَ بِأَنَّ لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelFún àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ní ìró pé dájúdájú ìyà ẹlẹ́ta eléro ń bẹ fún wọn.

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ يَتَّخِذُونَ ٱلْكَٰفِرِينَ أَوْلِيَآءَ مِن دُونِ ٱلْمُؤْمِنِينَ أَيَبْتَغُونَ عِندَهُمُ ٱلْعِزَّةَ فَإِنَّ ٱلْعِزَّةَ لِلَّهِ جَمِيعًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àwọn ni) àwọn tó ń mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ṣé ẹ̀ ń wá agbára lọ́dọ̀ wọn ni? Dájúdájú ti Allāhu ni gbogbo agbára pátápátá.

See all translations of this verse →

وَقَدْ نَزَّلَ عَلَيْكُمْ فِى ٱلْكِتَٰبِ أَنْ إِذَا سَمِعْتُمْ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ يُكْفَرُ بِهَا وَيُسْتَهْزَأُ بِهَا فَلَا تَقْعُدُوا۟ مَعَهُمْ حَتَّىٰ يَخُوضُوا۟ فِى حَدِيثٍ غَيْرِهِۦٓ إِنَّكُمْ إِذًا مِّثْلُهُمْ إِنَّ ٱللَّهَ جَامِعُ ٱلْمُنَٰفِقِينَ وَٱلْكَٰفِرِينَ فِى جَهَنَّمَ جَمِيعًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) kúkú ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún yín nínú Tírà pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn āyah Allāhu pé wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, wọ́n sì ń fi ṣe ẹ̀fẹ̀, ẹ má ṣe jókòó tì wọ́n nígbà náà títí wọn yóò fi bọ́ sínú ọ̀rọ̀ mìíràn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ dájúdájú bí irú wọn ni ẹ̀yin náà. Dájúdájú Allāhu yóò pa àwọn ṣòbẹ-ṣèlu mùsùlùmí pọ̀ mọ́ gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ nínú iná Jahanamọ.

See all translations of this verse →

ٱلَّذِينَ يَتَرَبَّصُونَ بِكُمْ فَإِن كَانَ لَكُمْ فَتْحٌ مِّنَ ٱللَّهِ قَالُوٓا۟ أَلَمْ نَكُن مَّعَكُمْ وَإِن كَانَ لِلْكَٰفِرِينَ نَصِيبٌ قَالُوٓا۟ أَلَمْ نَسْتَحْوِذْ عَلَيْكُمْ وَنَمْنَعْكُم مِّنَ ٱلْمُؤْمِنِينَ فَٱللَّهُ يَحْكُمُ بَيْنَكُمْ يَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ وَلَن يَجْعَلَ ٱللَّهُ لِلْكَٰفِرِينَ عَلَى ٱلْمُؤْمِنِينَ سَبِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Àwọn ni) àwọn tó fẹ́ yọ̀ yín; tí ìṣẹ́gun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu bá jẹ́ tiyín, wọ́n á wí pé: “Ṣé àwa kò wà pẹ̀lú yín bí?” Tí ìpín kan bá sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́, (àwọn mùnááfìkí) á wí pé: “Ṣé àwa kò ti ní ìkápá láti jẹ gàba le yín lórí (àmọ́ tí àwa kò ṣe bẹ́ẹ̀), ṣé àwa kò sì dáàbò bò yín tó lọ́wọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo (títí ọwọ́ yín fi ba ọrọ̀-ogun, nítorí náà kí ni ìpín tiwa tí ẹ fẹ́ fún wa?)”[1] Nítorí náà, Allāhu yóò ṣèdájọ́ láààrin yín ní Ọjọ́ Àjíǹde. Allāhu kò sì níí fún àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀nà (ìṣẹ́gun) kan lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلْمُنَٰفِقِينَ يُخَٰدِعُونَ ٱللَّهَ وَهُوَ خَٰدِعُهُمْ وَإِذَا قَامُوٓا۟ إِلَى ٱلصَّلَوٰةِ قَامُوا۟ كُسَالَىٰ يُرَآءُونَ ٱلنَّاسَ وَلَا يَذْكُرُونَ ٱللَّهَ إِلَّا قَلِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń tan Allāhu, Òun náà sì máa tàn wọ́n. Nígbà tí wọ́n bá dúró láti kírun, wọ́n á dúró (ní ìdúró) òròjú, wọn yó sì máa ṣe ṣekárími (lórí ìrun). Wọn kò sì níí ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu (lórí ìrun) àfi díẹ̀.

See all translations of this verse →

مُّذَبْذَبِينَ بَيْنَ ذَٰلِكَ لَآ إِلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِ وَلَآ إِلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِ وَمَن يُضْلِلِ ٱللَّهُ فَلَن تَجِدَ لَهُۥ سَبِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń ṣe bàlàbàlà síhìn-ín sọ́hùn-ún, wọn kò jẹ́ ti àwọn wọ̀nyí, wọn kò sì jẹ́ ti àwọn wọ̀nyí. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, o ò sì níí rí ọ̀nà kan fún un.

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تَتَّخِذُوا۟ ٱلْكَٰفِرِينَ أَوْلِيَآءَ مِن دُونِ ٱلْمُؤْمِنِينَ أَتُرِيدُونَ أَن تَجْعَلُوا۟ لِلَّهِ عَلَيْكُمْ سُلْطَٰنًا مُّبِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ yín). Ṣé ẹ fẹ́ ṣe n̄ǹkan tí Allāhu yóò fi ní ẹ̀rí pọ́nńbélé lọ́wọ́ láti jẹ yín níyà ni?

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلْمُنَٰفِقِينَ فِى ٱلدَّرْكِ ٱلْأَسْفَلِ مِنَ ٱلنَّارِ وَلَن تَجِدَ لَهُمْ نَصِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn ṣọ̀be-ṣèlu mùsùlùmí yóò wà nínú àjà ìsàlẹ̀ pátápátá nínú Iná. O ò sì níí rí alárànṣe kan fún wọn.

See all translations of this verse →

إِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُوا۟ وَأَصْلَحُوا۟ وَٱعْتَصَمُوا۟ بِٱللَّهِ وَأَخْلَصُوا۟ دِينَهُمْ لِلَّهِ فَأُو۟لَٰٓئِكَ مَعَ ٱلْمُؤْمِنِينَ وَسَوْفَ يُؤْتِ ٱللَّهُ ٱلْمُؤْمِنِينَ أَجْرًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀyàfi àwọn tó ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe, tí wọ́n dúró ṣinṣin ti Allāhu, tí wọ́n sì ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn wọn fún Allāhu. Nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn máa wà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Láìpẹ́ Allāhu máa fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ẹ̀san ńlá.

See all translations of this verse →

مَّا يَفْعَلُ ٱللَّهُ بِعَذَابِكُمْ إِن شَكَرْتُمْ وَءَامَنتُمْ وَكَانَ ٱللَّهُ شَاكِرًا عَلِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ni Allāhu máa fi jíjẹ yín níyà ṣe, tí ẹ bá dúpẹ́, tí ẹ sì gbàgbọ́ ní òdodo? Allāhu sì ń jẹ́ Ọlọ́pẹ́,[1] Onímọ̀.

See all translations of this verse →

لَّا يُحِبُّ ٱللَّهُ ٱلْجَهْرَ بِٱلسُّوٓءِ مِنَ ٱلْقَوْلِ إِلَّا مَن ظُلِمَ وَكَانَ ٱللَّهُ سَمِيعًا عَلِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelAllāhu kò nífẹ̀ẹ́ sí ariwo ọ̀rọ̀ burúkú (láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni)[1] àyàfi ẹni tí wọ́n bá ṣe àbòsí sí. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbọ́, Onímọ̀.

See all translations of this verse →

إِن تُبْدُوا۟ خَيْرًا أَوْ تُخْفُوهُ أَوْ تَعْفُوا۟ عَن سُوٓءٍ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَفُوًّا قَدِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTí ẹ bá ṣàfi hàn rere tàbí ẹ fi pamọ́ tàbí ẹ ṣàmójú kúrò níbi aburú, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámòjúúkúrò, Alágbára.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ يَكْفُرُونَ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦ وَيُرِيدُونَ أَن يُفَرِّقُوا۟ بَيْنَ ٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦ وَيَقُولُونَ نُؤْمِنُ بِبَعْضٍ وَنَكْفُرُ بِبَعْضٍ وَيُرِيدُونَ أَن يَتَّخِذُوا۟ بَيْنَ ذَٰلِكَ سَبِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, wọ́n sì fẹ́ máa ṣòpínyà láààrin Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú apá kan, a sì ṣàì gbàgbọ́ nínú apá kan,” wọ́n sì fẹ́ mú ọ̀nà kan tọ̀ (lẹ́sìn) láààrin ìyẹn.

See all translations of this verse →

أُو۟لَٰٓئِكَ هُمُ ٱلْكَٰفِرُونَ حَقًّا وَأَعْتَدْنَا لِلْكَٰفِرِينَ عَذَابًا مُّهِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́. A sì ti pèsè Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

See all translations of this verse →

وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦ وَلَمْ يُفَرِّقُوا۟ بَيْنَ أَحَدٍ مِّنْهُمْ أُو۟لَٰٓئِكَ سَوْفَ يُؤْتِيهِمْ أُجُورَهُمْ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọn kò sì ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn, láìpẹ́ àwọn wọ̀nyẹn, (Allāhu) máa fún wọn ní ẹ̀san wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

See all translations of this verse →

يَسْـَٔلُكَ أَهْلُ ٱلْكِتَٰبِ أَن تُنَزِّلَ عَلَيْهِمْ كِتَٰبًا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ فَقَدْ سَأَلُوا۟ مُوسَىٰٓ أَكْبَرَ مِن ذَٰلِكَ فَقَالُوٓا۟ أَرِنَا ٱللَّهَ جَهْرَةً فَأَخَذَتْهُمُ ٱلصَّٰعِقَةُ بِظُلْمِهِمْ ثُمَّ ٱتَّخَذُوا۟ ٱلْعِجْلَ مِنۢ بَعْدِ مَا جَآءَتْهُمُ ٱلْبَيِّنَٰتُ فَعَفَوْنَا عَن ذَٰلِكَ وَءَاتَيْنَا مُوسَىٰ سُلْطَٰنًا مُّبِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn onítírà ń bi ọ́ léèrè pé kí o sọ tírà kan kalẹ̀ láti inú sánmọ̀. Wọ́n kúkú bi (Ànábì) Mūsā ní ohun tí ó tóbi ju ìyẹn lọ. Wọ́n wí pé: “Fi Allāhu hàn wá ní ojúkojú.” Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gbá wọn mú nítorí àbòsí ọwọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù di n̄ǹkan tí wọ́n jọ́sìn fún lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá wọn. A tún ṣàmójú kúrò níbi ìyẹn. A sì fún (Ànábì) Mūsā ní ẹ̀rí pọ́nńbélé.

See all translations of this verse →

وَرَفَعْنَا فَوْقَهُمُ ٱلطُّورَ بِمِيثَٰقِهِمْ وَقُلْنَا لَهُمُ ٱدْخُلُوا۟ ٱلْبَابَ سُجَّدًا وَقُلْنَا لَهُمْ لَا تَعْدُوا۟ فِى ٱلسَّبْتِ وَأَخَذْنَا مِنْهُم مِّيثَٰقًا غَلِيظًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA gbé àpáta sókè orí wọn nítorí májẹ̀mu wọn. A sì sọ fún wọn pé: “Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà ìlú wọlé ní olùdáwọ́tẹ-orúnkún.” A tún sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà ní ọjọ́ Sabt.” A sì gba àdéhùn tó nípọn lọ́wọ́ wọn.

See all translations of this verse →

فَبِمَا نَقْضِهِم مِّيثَٰقَهُمْ وَكُفْرِهِم بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَقَتْلِهِمُ ٱلْأَنۢبِيَآءَ بِغَيْرِ حَقٍّ وَقَوْلِهِمْ قُلُوبُنَا غُلْفٌۢ بَلْ طَبَعَ ٱللَّهُ عَلَيْهَا بِكُفْرِهِمْ فَلَا يُؤْمِنُونَ إِلَّا قَلِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí yíyẹ̀ tí wọ́n fúnra wọn yẹ àdéhùn wọn, àti ṣíṣàìgbàgbọ́ wọn nínú àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu, àti pípa tí wọ́n ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́ àti wíwí tí wọ́n ń wí pé: “Ọkàn wa ti di.” - rárá, Allāhu ti fi èdídí dí ọkàn wọn ni nítorí àìgbàgbọ́ wọn. - Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn).

See all translations of this verse →

وَبِكُفْرِهِمْ وَقَوْلِهِمْ عَلَىٰ مَرْيَمَ بُهْتَٰنًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti nítorí àìgbàgbọ́ wọn àti ọ̀rọ̀ wọn lórí Mọryam ní ti ìbànilórúkọjẹ́ ńlá (Allāhu tún fi èdídí dí ọkàn wọn).

See all translations of this verse →

وَقَوْلِهِمْ إِنَّا قَتَلْنَا ٱلْمَسِيحَ عِيسَى ٱبْنَ مَرْيَمَ رَسُولَ ٱللَّهِ وَمَا قَتَلُوهُ وَمَا صَلَبُوهُ وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمْ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ ٱخْتَلَفُوا۟ فِيهِ لَفِى شَكٍّ مِّنْهُ مَا لَهُم بِهِۦ مِنْ عِلْمٍ إِلَّا ٱتِّبَاعَ ٱلظَّنِّ وَمَا قَتَلُوهُ يَقِينًۢا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti nítorí ọ̀rọ̀ wọn (yìí): “Dájúdájú àwa pa Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam Òjíṣẹ́ Allāhu.” Wọn kò pa á, wọn kò sì kàn án mọ́ igi àgbélébùú, ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni.[1] Dájúdájú àwọn tó yapa-ẹnu lórí rẹ̀, kúkú wà nínú iyèméjì lórí rẹ̀; kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀ àfi títẹ̀lé àbá dídá. Wọn kò pa á ní ti àmọ̀dájú.

See all translations of this verse →

بَل رَّفَعَهُ ٱللَّهُ إِلَيْهِ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelbí kò ṣe pé Allāhu gbé e wá sókè lọ́dọ̀ Rẹ̀ ni. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.[1]

See all translations of this verse →

وَإِن مِّنْ أَهْلِ ٱلْكِتَٰبِ إِلَّا لَيُؤْمِنَنَّ بِهِۦ قَبْلَ مَوْتِهِۦ وَيَوْمَ ٱلْقِيَٰمَةِ يَكُونُ عَلَيْهِمْ شَهِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKò sì níí sí ẹnì kan nínú àwọn onítírà (láyé nígbà tí ‘Īsā ọmọ Mọryam bá sọ̀kalẹ̀ padà láti ojú sánmọ̀) àfi kí ó gbà á gbọ́ ní òdodo ṣíwájú ikú rẹ̀.[1]Ní Ọjọ́ Àjíǹde, ó sì máa jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí wọn.

See all translations of this verse →

فَبِظُلْمٍ مِّنَ ٱلَّذِينَ هَادُوا۟ حَرَّمْنَا عَلَيْهِمْ طَيِّبَٰتٍ أُحِلَّتْ لَهُمْ وَبِصَدِّهِمْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ كَثِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNítorí àbòsí láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n di yẹhudi, A ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa kan ní èèwọ̀ fún wọn, èyí tí wọ́n ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn (tẹ́lẹ̀. A ṣe é ní èèwọ̀ fún wọn sẹ́) nípa bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu.

See all translations of this verse →

وَأَخْذِهِمُ ٱلرِّبَوٰا۟ وَقَدْ نُهُوا۟ عَنْهُ وَأَكْلِهِمْ أَمْوَٰلَ ٱلنَّاسِ بِٱلْبَٰطِلِ وَأَعْتَدْنَا لِلْكَٰفِرِينَ مِنْهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti gbígbà tí wọ́n ń gba owó èlé, tí A sì ti kọ̀ ọ́ fún wọn, àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ dúkìá àwọn ènìyàn lọ́nà èrú. A sì ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

See all translations of this verse →

لَّٰكِنِ ٱلرَّٰسِخُونَ فِى ٱلْعِلْمِ مِنْهُمْ وَٱلْمُؤْمِنُونَ يُؤْمِنُونَ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيْكَ وَمَآ أُنزِلَ مِن قَبْلِكَ وَٱلْمُقِيمِينَ ٱلصَّلَوٰةَ وَٱلْمُؤْتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱلْمُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ أُو۟لَٰٓئِكَ سَنُؤْتِيهِمْ أَجْرًا عَظِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢùgbọ́n àwọn tó jindò nínú ìmọ̀ nínú wọn àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, wọ́n gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, àwọn tó ń kírun àtí àwọn tó ń yọ Zakāh àti àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún ní ẹ̀san ńlá.

See all translations of this verse →

إِنَّآ أَوْحَيْنَآ إِلَيْكَ كَمَآ أَوْحَيْنَآ إِلَىٰ نُوحٍ وَٱلنَّبِيِّـۧنَ مِنۢ بَعْدِهِۦ وَأَوْحَيْنَآ إِلَىٰٓ إِبْرَٰهِيمَ وَإِسْمَٰعِيلَ وَإِسْحَٰقَ وَيَعْقُوبَ وَٱلْأَسْبَاطِ وَعِيسَىٰ وَأَيُّوبَ وَيُونُسَ وَهَٰرُونَ وَسُلَيْمَٰنَ وَءَاتَيْنَا دَاوُۥدَ زَبُورًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Àwa (fi ìmísí) ránṣẹ́ sí ọ gẹ́gẹ́ bí A ṣe fi ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh àti àwọn Ànábì (mìíràn) lẹ́yìn rẹ̀. A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀), àti (Ànábì) ‘Īsā, ’Ayyūb, Yūnus, Hārūn àti Sulaemọ̄n. A sì fún (Ànábì) Dāwūd ní Zabūr.

See all translations of this verse →

وَرُسُلًا قَدْ قَصَصْنَٰهُمْ عَلَيْكَ مِن قَبْلُ وَرُسُلًا لَّمْ نَقْصُصْهُمْ عَلَيْكَ وَكَلَّمَ ٱللَّهُ مُوسَىٰ تَكْلِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A ti sọ ìtàn wọn fún ọ ṣíwájú pẹ̀lú àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ. Allāhu sì bá (Ànábì) Mūsā sọ̀rọ̀ tààrà.

See all translations of this verse →

رُّسُلًا مُّبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَى ٱللَّهِ حُجَّةٌۢ بَعْدَ ٱلرُّسُلِ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(A ṣe wọ́n ní) Òjíṣẹ́, oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí kí àwíjàre má lè wà fún àwọn ènìyàn lọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn (tí) àwọn Òjíṣẹ́ (ti jíṣẹ́). Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

لَّٰكِنِ ٱللَّهُ يَشْهَدُ بِمَآ أَنزَلَ إِلَيْكَ أَنزَلَهُۥ بِعِلْمِهِۦ وَٱلْمَلَٰٓئِكَةُ يَشْهَدُونَ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢùgbọ́n Allāhu ń jẹ́rìí sí ohun tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àwọn mọlāika náà ń jẹ́rìí (sí i). Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَصَدُّوا۟ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ قَدْ ضَلُّوا۟ ضَلَٰلًۢا بَعِيدًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n kúkú ti ṣìnà ní ìṣìnà tó jìnnà.

See all translations of this verse →

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَظَلَمُوا۟ لَمْ يَكُنِ ٱللَّهُ لِيَغْفِرَ لَهُمْ وَلَا لِيَهْدِيَهُمْ طَرِيقًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún ṣàbòsí, Allāhu kò níí forí jìn wọ́n, kò sì níí fi ojú-ọ̀nà kan mọ̀ wọ́n.

See all translations of this verse →

إِلَّا طَرِيقَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدًا وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀyàfi ojú-ọ̀nà iná Jahanamọ. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.[1]

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدْ جَآءَكُمُ ٱلرَّسُولُ بِٱلْحَقِّ مِن رَّبِّكُمْ فَـَٔامِنُوا۟ خَيْرًا لَّكُمْ وَإِن تَكْفُرُوا۟ فَإِنَّ لِلَّهِ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin ènìyàn, dájúdájú Òjíṣẹ́ náà ti dé ba yín pẹ̀lú òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, kí ẹ gbà á gbọ́ l’ó dára jùlọ fún yín. Tí ẹ bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

See all translations of this verse →

يَٰٓأَهْلَ ٱلْكِتَٰبِ لَا تَغْلُوا۟ فِى دِينِكُمْ وَلَا تَقُولُوا۟ عَلَى ٱللَّهِ إِلَّا ٱلْحَقَّ إِنَّمَا ٱلْمَسِيحُ عِيسَى ٱبْنُ مَرْيَمَ رَسُولُ ٱللَّهِ وَكَلِمَتُهُۥٓ أَلْقَىٰهَآ إِلَىٰ مَرْيَمَ وَرُوحٌ مِّنْهُ فَـَٔامِنُوا۟ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦ وَلَا تَقُولُوا۟ ثَلَٰثَةٌ ٱنتَهُوا۟ خَيْرًا لَّكُمْ إِنَّمَا ٱللَّهُ إِلَٰهٌ وَٰحِدٌ سُبْحَٰنَهُۥٓ أَن يَكُونَ لَهُۥ وَلَدٌ لَّهُۥ مَا فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِى ٱلْأَرْضِ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin onítírà, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà nínú ẹ̀sìn yín, kí ẹ sì má sọ ohun kan nípa Allāhu àfi òdodo. Òjíṣẹ́ Allāhu ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni (Ó fi dá Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam). Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ yé sọ mẹ́ta (lọ́kan) mọ́. Kí ẹ jáwọ́ níbẹ̀ ló jẹ́ oore fún yín. Allāhu nìkan ni Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Ó mọ́ tayọ kí Ó ní ọmọ. TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Alámòjúútó.[1]

See all translations of this verse →

لَّن يَسْتَنكِفَ ٱلْمَسِيحُ أَن يَكُونَ عَبْدًا لِّلَّهِ وَلَا ٱلْمَلَٰٓئِكَةُ ٱلْمُقَرَّبُونَ وَمَن يَسْتَنكِفْ عَنْ عِبَادَتِهِۦ وَيَسْتَكْبِرْ فَسَيَحْشُرُهُمْ إِلَيْهِ جَمِيعًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMọsīh kò kọ̀ láti jẹ́ ẹrú fún Allāhu. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn mọlāika tí wọ́n súnmọ́ Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti jọ́sìn fún Un, tí ó tún ṣègbéraga, (Allāhu) yóò kó wọn jọ papọ̀ pátápátá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

See all translations of this verse →

فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَيُوَفِّيهِمْ أُجُورَهُمْ وَيَزِيدُهُم مِّن فَضْلِهِۦ وَأَمَّا ٱلَّذِينَ ٱسْتَنكَفُوا۟ وَٱسْتَكْبَرُوا۟ فَيُعَذِّبُهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا وَلَا يَجِدُونَ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيًّا وَلَا نَصِيرًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere, (Allāhu) yóò san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ó sì máa ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Ní ti àwọn tó bá sì kọ̀ (láti jọ́sìn fún Allāhu), tí wọ́n sì ṣègbéraga, (Allāhu) yóò jẹ wọ́n níyà ẹlẹ́ta-eléro. Wọn kò sì níí rí alátìlẹ́yìn tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu.

See all translations of this verse →

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدْ جَآءَكُم بُرْهَٰنٌ مِّن رَّبِّكُمْ وَأَنزَلْنَآ إِلَيْكُمْ نُورًا مُّبِينًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin ènìyàn, dájúdájú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. A sì tún sọ ìmọ́lẹ̀ tó yanjú kalẹ̀ fún yín.

See all translations of this verse →

فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ بِٱللَّهِ وَٱعْتَصَمُوا۟ بِهِۦ فَسَيُدْخِلُهُمْ فِى رَحْمَةٍ مِّنْهُ وَفَضْلٍ وَيَهْدِيهِمْ إِلَيْهِ صِرَٰطًا مُّسْتَقِيمًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNí ti àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu, tí wọ́n sì dúró ṣinṣin tì Í, Ó máa fi wọ́n sínú ìkẹ́ àti ọlá kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó sì máa fi wọ́n mọ ọ̀nà tààrà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

See all translations of this verse →

يَسْتَفْتُونَكَ قُلِ ٱللَّهُ يُفْتِيكُمْ فِى ٱلْكَلَٰلَةِ إِنِ ٱمْرُؤٌا۟ هَلَكَ لَيْسَ لَهُۥ وَلَدٌ وَلَهُۥٓ أُخْتٌ فَلَهَا نِصْفُ مَا تَرَكَ وَهُوَ يَرِثُهَآ إِن لَّمْ يَكُن لَّهَا وَلَدٌ فَإِن كَانَتَا ٱثْنَتَيْنِ فَلَهُمَا ٱلثُّلُثَانِ مِمَّا تَرَكَ وَإِن كَانُوٓا۟ إِخْوَةً رِّجَالًا وَنِسَآءً فَلِلذَّكَرِ مِثْلُ حَظِّ ٱلْأُنثَيَيْنِ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمْ أَن تَضِلُّوا۟ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَىْءٍ عَلِيمٌۢ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelWọ́n ń bi ọ́ léèrè ìbéèrè, sọ pé: “Allāhu ń fún yín ní ìdájọ́ nípa ẹni tí kò ní òbí, kò sì ní ọmọ. Tí ènìyàn kan bá kú, tí kò ní ọmọ láyé, tí ó sì ní arábìnrin kan, ìdajì ni tirẹ̀ nínú ohun tí ó fi sílẹ̀. (Arákùnrin) l’ó máa jẹ gbogbo ogún arábìnrin rẹ̀, tí kò bá ní ọmọ láyé. Tí arábìnrin bá sì jẹ́ méjì, ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ni tiwọn nínú ohun tí ó fi sílẹ̀. Tí wọ́n bá sì jẹ́ ará (púpọ̀) lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ti ọkùnrin kan ni ìpín obìnrin méjì. Allāhu ń ṣe àlàyé fún yín kí ẹ má baà ṣìnà. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

See all translations of this verse →

Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70