caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Ahzaab, ẹsẹ 37

Medina · revelation order 90 · 33:37

وَإِذْ تَقُولُ لِلَّذِىٓ أَنْعَمَ ٱللَّهُ عَلَيْهِ وَأَنْعَمْتَ عَلَيْهِ أَمْسِكْ عَلَيْكَ زَوْجَكَ وَٱتَّقِ ٱللَّهَ وَتُخْفِى فِى نَفْسِكَ مَا ٱللَّهُ مُبْدِيهِ وَتَخْشَى ٱلنَّاسَ وَٱللَّهُ أَحَقُّ أَن تَخْشَىٰهُ فَلَمَّا قَضَىٰ زَيْدٌ مِّنْهَا وَطَرًا زَوَّجْنَٰكَهَا لِكَىْ لَا يَكُونَ عَلَى ٱلْمُؤْمِنِينَ حَرَجٌ فِىٓ أَزْوَٰجِ أَدْعِيَآئِهِمْ إِذَا قَضَوْا۟ مِنْهُنَّ وَطَرًا وَكَانَ أَمْرُ ٱللَّهِ مَفْعُولًا

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí ò ń sọ fún ẹni tí Allāhu ṣèdẹ̀ra fún, tí ìwọ náà ṣèdẹ̀ra fún[1] pé: “Mú ìyàwó rẹ dání, kí o sì bẹ̀rù Allāhu.” O sì ń fi pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ ohun tí Allāhu yó ṣàfi hàn rẹ̀. Àti pé ò ń páyà àwọn ènìyàn. Allāhu l’Ó sì lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o páyà Rẹ̀. Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ nítorí kí ó má baà jẹ́ láìfí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti fẹ́ ìyàwó ọmọ-ọlọ́mọ tí wọ́n ń pè ní ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá ti parí bùkátà wọn lọ́dọ̀ wọn (tí wọ́n sì ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀). Àṣẹ Allāhu sì gbọ́dọ̀ ṣẹ.²
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70