هَلْ يَنظُرُونَ إِلَّا تَأْوِيلَهُۥ يَوْمَ يَأْتِى تَأْوِيلُهُۥ يَقُولُ ٱلَّذِينَ نَسُوهُ مِن قَبْلُ قَدْ جَآءَتْ رُسُلُ رَبِّنَا بِٱلْحَقِّ فَهَل لَّنَا مِن شُفَعَآءَ فَيَشْفَعُوا۟ لَنَآ أَوْ نُرَدُّ فَنَعْمَلَ غَيْرَ ٱلَّذِى كُنَّا نَعْمَلُ قَدْ خَسِرُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُوا۟ يَفْتَرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí ni wọ́n ń retí bí kò ṣe ẹ̀san Rẹ̀?[1] Lọ́jọ́ tí ẹ̀san Rẹ̀ bá dé, àwọn tó gbàgbé rẹ̀ ṣíwájú yóò wí pé: “Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá. Nítorí náà, ǹjẹ́ a lè rí àwọn olùṣìpẹ̀, kí wọ́n wá ṣìpẹ̀ fún wa tàbí kí wọ́n dá wa padà sílé ayé, kí á lè ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe?” Dájúdájú wọ́n ti ṣe ẹ̀mí wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.²