caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-A'raaf, ẹsẹ 54

Mecca · revelation order 39 · 7:54

إِنَّ رَبَّكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضَ فِى سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ ٱسْتَوَىٰ عَلَى ٱلْعَرْشِ يُغْشِى ٱلَّيْلَ ٱلنَّهَارَ يَطْلُبُهُۥ حَثِيثًا وَٱلشَّمْسَ وَٱلْقَمَرَ وَٱلنُّجُومَ مُسَخَّرَٰتٍۭ بِأَمْرِهِۦٓ أَلَا لَهُ ٱلْخَلْقُ وَٱلْأَمْرُ تَبَارَكَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلْعَٰلَمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú, tí òru ń wá ọ̀sán ní kíákíá.[1] Òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ni wọ́n ti rọ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Gbọ́! TiRẹ̀ ni ẹ̀dá àti àṣẹ. Ìbùkún ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70