caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Maaida, ẹsẹ 2

Medina · revelation order 112 · 5:2

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تُحِلُّوا۟ شَعَٰٓئِرَ ٱللَّهِ وَلَا ٱلشَّهْرَ ٱلْحَرَامَ وَلَا ٱلْهَدْىَ وَلَا ٱلْقَلَٰٓئِدَ وَلَآ ءَآمِّينَ ٱلْبَيْتَ ٱلْحَرَامَ يَبْتَغُونَ فَضْلًا مِّن رَّبِّهِمْ وَرِضْوَٰنًا وَإِذَا حَلَلْتُمْ فَٱصْطَادُوا۟ وَلَا يَجْرِمَنَّكُمْ شَنَـَٔانُ قَوْمٍ أَن صَدُّوكُمْ عَنِ ٱلْمَسْجِدِ ٱلْحَرَامِ أَن تَعْتَدُوا۟ وَتَعَاوَنُوا۟ عَلَى ٱلْبِرِّ وَٱلتَّقْوَىٰ وَلَا تَعَاوَنُوا۟ عَلَى ٱلْإِثْمِ وَٱلْعُدْوَٰنِ وَٱتَّقُوا۟ ٱللَّهَ إِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلْعِقَابِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe rú òfin àwọn n̄ǹkan àríṣàmì tí Allāhu gbékalẹ̀ fún ẹ̀sìn Rẹ̀ (nínú iṣẹ́ hajj). Ẹ má ṣe rú òfin oṣù ọ̀wọ̀, àti ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ẹ má ṣe ìdíwọ́ fún àwọn tó ń gbèrò láti lọ sí Ilé Haram, tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Tí ẹ bá sì ti túra sílẹ̀ nínú aṣọ hurumi, nígbà náà ẹ (lè) dọdẹ (ẹranko). Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti tayọ ẹnu-ààlà nítorí pé, wọ́n ṣe yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ ran ara yín lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ má ṣe ran ara yín lọ́wọ́ lórí (ìwà) ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtayọ ẹnu-ààlà. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70