caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Maaida, ẹsẹ 12

Medina · revelation order 112 · 5:12

وَلَقَدْ أَخَذَ ٱللَّهُ مِيثَٰقَ بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ وَبَعَثْنَا مِنْهُمُ ٱثْنَىْ عَشَرَ نَقِيبًا وَقَالَ ٱللَّهُ إِنِّى مَعَكُمْ لَئِنْ أَقَمْتُمُ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَيْتُمُ ٱلزَّكَوٰةَ وَءَامَنتُم بِرُسُلِى وَعَزَّرْتُمُوهُمْ وَأَقْرَضْتُمُ ٱللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا لَّأُكَفِّرَنَّ عَنكُمْ سَيِّـَٔاتِكُمْ وَلَأُدْخِلَنَّكُمْ جَنَّٰتٍ تَجْرِى مِن تَحْتِهَا ٱلْأَنْهَٰرُ فَمَن كَفَرَ بَعْدَ ذَٰلِكَ مِنكُمْ فَقَدْ ضَلَّ سَوَآءَ ٱلسَّبِيلِ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. A sì gbé ìjòyè méjìlá dìde nínú wọn. Allāhu sì sọ (fún wọn) pé: “Dájúdájú Mò ń bẹ pẹ̀lú yín, tí ẹ bá ń kírun, tí ẹ̀ bá ń yọ Zakāh, tí ẹ bá gba àwọn Òjíṣẹ́ Mi gbọ́, tí ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́, tí ẹ sì yá Allāhu ní dúkìá tó dára. Dájúdájú Mo máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́. Dájúdájú Mo máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìyẹn nínú yín, ó kúkú ti ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà tààrà.”
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70