caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Qasas, ẹsẹ 15

Mecca · revelation order 49 · 28:15

وَدَخَلَ ٱلْمَدِينَةَ عَلَىٰ حِينِ غَفْلَةٍ مِّنْ أَهْلِهَا فَوَجَدَ فِيهَا رَجُلَيْنِ يَقْتَتِلَانِ هَٰذَا مِن شِيعَتِهِۦ وَهَٰذَا مِنْ عَدُوِّهِۦ فَٱسْتَغَٰثَهُ ٱلَّذِى مِن شِيعَتِهِۦ عَلَى ٱلَّذِى مِنْ عَدُوِّهِۦ فَوَكَزَهُۥ مُوسَىٰ فَقَضَىٰ عَلَيْهِ قَالَ هَٰذَا مِنْ عَمَلِ ٱلشَّيْطَٰنِ إِنَّهُۥ عَدُوٌّ مُّضِلٌّ مُّبِينٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ wọ inú ìlú nígbà tí àwọn ará ìlú ti gbàgbé (nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀).[1] Ó rí àwọn ọkùnrin méjì kan tí wọ́n ń bara wọn jà. Èyí wá láti inú ìran rẹ̀. Èyí sì wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Èyí tí ó wá láti inú ìran rẹ̀ wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ lórí èyí tí ó wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Mūsā kàn án ní ẹ̀ṣẹ́. Ó sì pa á. Ó sọ pé: “Èyí wà nínú iṣẹ́ aṣ-ṣaetọ̄n. Dájúdájú (aṣ-ṣaetọ̄n) ni ọ̀tá aṣini-lọ́nà pọ́nńbélé.”
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70