caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Baqara, ẹsẹ 264

Medina · revelation order 87 · 2:264

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تُبْطِلُوا۟ صَدَقَٰتِكُم بِٱلْمَنِّ وَٱلْأَذَىٰ كَٱلَّذِى يُنفِقُ مَالَهُۥ رِئَآءَ ٱلنَّاسِ وَلَا يُؤْمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ فَمَثَلُهُۥ كَمَثَلِ صَفْوَانٍ عَلَيْهِ تُرَابٌ فَأَصَابَهُۥ وَابِلٌ فَتَرَكَهُۥ صَلْدًا لَّا يَقْدِرُونَ عَلَىٰ شَىْءٍ مِّمَّا كَسَبُوا۟ وَٱللَّهُ لَا يَهْدِى ٱلْقَوْمَ ٱلْكَٰفِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe fi ìrègún àti ìpalára ba àwọn sàráà yín jẹ́, bí ẹni tí ó ń ná dúkìá rẹ̀ pẹ̀lú ṣekárími, kò sì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Àpèjúwe rẹ̀ dà bí àpèjúwe àpáta kan tí erùpẹ̀ ń bẹ lórí rẹ̀. Òjò ńlá rọ̀ sí i, ó sì kó erùpẹ̀ kúrò lórí rẹ̀ pátápátá. Wọn kò ní agbára lórí kiní kan nínú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70