caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Baqara, ẹsẹ 144

Medina · revelation order 87 · 2:144

قَدْ نَرَىٰ تَقَلُّبَ وَجْهِكَ فِى ٱلسَّمَآءِ فَلَنُوَلِّيَنَّكَ قِبْلَةً تَرْضَىٰهَا فَوَلِّ وَجْهَكَ شَطْرَ ٱلْمَسْجِدِ ٱلْحَرَامِ وَحَيْثُ مَا كُنتُمْ فَوَلُّوا۟ وُجُوهَكُمْ شَطْرَهُۥ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَٰبَ لَيَعْلَمُونَ أَنَّهُ ٱلْحَقُّ مِن رَّبِّهِمْ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا يَعْمَلُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA kúkú rí yíyí tí ò ń yí ojú rẹ sí sánmọ̀. Nítorí náà, dájúdájú A óò dojú rẹ kọ Ƙiblah kan tí o yọ́nú sí; nítorí náà, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram (ní Mọkkah). Ibikíbi tí ẹ bá tún wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀. Dájúdájú àwọn tí A fún ní Tírà kúkú mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni (àṣẹ Ƙiblah) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70