caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Ibrahim, ẹsẹ 22

Mecca · revelation order 72 · 14:22

وَقَالَ ٱلشَّيْطَٰنُ لَمَّا قُضِىَ ٱلْأَمْرُ إِنَّ ٱللَّهَ وَعَدَكُمْ وَعْدَ ٱلْحَقِّ وَوَعَدتُّكُمْ فَأَخْلَفْتُكُمْ وَمَا كَانَ لِىَ عَلَيْكُم مِّن سُلْطَٰنٍ إِلَّآ أَن دَعَوْتُكُمْ فَٱسْتَجَبْتُمْ لِى فَلَا تَلُومُونِى وَلُومُوٓا۟ أَنفُسَكُم مَّآ أَنَا۠ بِمُصْرِخِكُمْ وَمَآ أَنتُم بِمُصْرِخِىَّ إِنِّى كَفَرْتُ بِمَآ أَشْرَكْتُمُونِ مِن قَبْلُ إِنَّ ٱلظَّٰلِمِينَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikaelaṣ-Ṣaetọ̄n yó sì wí nígbà tí A bá ṣèdájọ́ (ẹ̀dá) tán, pé: “Dájúdájú Allāhu ṣe àdéhùn fún yín ní àdéhùn òdodo. Èmi náà ṣe àdéhùn fún yín. Mo sì yapa àdéhùn tí mo ṣe fún yín. Èmi kò sì ní agbára kan lórí yín bí kò ṣe pé mo pè yín ẹ sì jẹ́pè mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe bú mi; ara yín ni kí ẹ bú. Èmi kò lè gbà yín là (nínú ìyà), Ẹ̀yin náà kò sì lè gbà mí là (nínú ìyà). Dájúdájú èmi ti lòdì sí ohun tí ẹ fi sọ mí di akẹgbẹ́ Allāhu ṣíwájú.” Dájúdájú àwọn alábòsí, ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70