وَمِنْهُمُ ٱلَّذِينَ يُؤْذُونَ ٱلنَّبِىَّ وَيَقُولُونَ هُوَ أُذُنٌ قُلْ أُذُنُ خَيْرٍ لَّكُمْ يُؤْمِنُ بِٱللَّهِ وَيُؤْمِنُ لِلْمُؤْمِنِينَ وَرَحْمَةٌ لِّلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مِنكُمْ وَٱلَّذِينَ يُؤْذُونَ رَسُولَ ٱللَّهِ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn tó ń kó ìnira bá Ànábì wà nínú wọn, tí wọ́n sì ń wí pé: “Elétí-ọfẹ ni.” Sọ pé: “Elétí-ọfẹ rere ni fún yín; ó gbàgbọ́ nínú Allāhu. Ó sì gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbọ́. Ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nínú yín. Àti pé àwọn tó ń kó ìnira bá Òjíṣẹ́ Allāhu, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn.”