caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-A'raaf, ẹsẹ 155

Mecca · revelation order 39 · 7:155

وَٱخْتَارَ مُوسَىٰ قَوْمَهُۥ سَبْعِينَ رَجُلًا لِّمِيقَٰتِنَا فَلَمَّآ أَخَذَتْهُمُ ٱلرَّجْفَةُ قَالَ رَبِّ لَوْ شِئْتَ أَهْلَكْتَهُم مِّن قَبْلُ وَإِيَّٰىَ أَتُهْلِكُنَا بِمَا فَعَلَ ٱلسُّفَهَآءُ مِنَّآ إِنْ هِىَ إِلَّا فِتْنَتُكَ تُضِلُّ بِهَا مَن تَشَآءُ وَتَهْدِى مَن تَشَآءُ أَنتَ وَلِيُّنَا فَٱغْفِرْ لَنَا وَٱرْحَمْنَا وَأَنتَ خَيْرُ ٱلْغَٰفِرِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ànábì) Mūsā sì yan àádọ́rin ọkùnrin nínú ìjọ rẹ̀ fún àkókò tí A fún un (láti wá tọrọ àforíjìn fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ibi àpáta Sīnā’), ohùn igbe líle tó mi ilẹ̀ tìtì sì gbá wọn mú, ó sọ pé: “Olúwa mi, tí O bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, Ìwọ ìbá ti pa àwọn àti èmi rẹ́ ṣíwájú (kí á tó wá síbí); ṣé Ìwọ yóò pa wá rẹ́ nítorí ohun tí àwọn òmùgọ̀ nínú wa ṣe ni? Kí ni ohun (tí wọ́n ṣe) bí kò ṣe àdánwò Rẹ; Ò ń fi ṣi ẹni tí O bá fẹ́ lọ́nà, O sì ń tọ́ ẹni tí O bá fẹ́ sọ́nà. Ìwọ ni Aláàbò wa. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn aláforíjìn.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70