caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-A'raaf, ẹsẹ 156

Mecca · revelation order 39 · 7:156

وَٱكْتُبْ لَنَا فِى هَٰذِهِ ٱلدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِى ٱلْـَٔاخِرَةِ إِنَّا هُدْنَآ إِلَيْكَ قَالَ عَذَابِىٓ أُصِيبُ بِهِۦ مَنْ أَشَآءُ وَرَحْمَتِى وَسِعَتْ كُلَّ شَىْءٍ فَسَأَكْتُبُهَا لِلَّذِينَ يَتَّقُونَ وَيُؤْتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱلَّذِينَ هُم بِـَٔايَٰتِنَا يُؤْمِنُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí O sì kọ àkọsílẹ̀ rere fún wa ní ayé yìí àti ní ọ̀run. Dájúdájú àwa ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ.” (Allāhu) sọ pé: “Ìyà Mi, Mo ń fi jẹ ẹni tí Mo bá fẹ́. Àti pé ìkẹ́ Mi gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan. Èmi yó sì kọ (ìkẹ́ Mi) mọ́ àwọn tó ń bẹ̀rù (Mi), tí wọ́n sì ń yọ Zakāh àti àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú àwọn āyah Wa.”
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70