وَلَقَدْ جِئْتُمُونَا فُرَٰدَىٰ كَمَا خَلَقْنَٰكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ وَتَرَكْتُم مَّا خَوَّلْنَٰكُمْ وَرَآءَ ظُهُورِكُمْ وَمَا نَرَىٰ مَعَكُمْ شُفَعَآءَكُمُ ٱلَّذِينَ زَعَمْتُمْ أَنَّهُمْ فِيكُمْ شُرَكَٰٓؤُا۟ لَقَد تَّقَطَّعَ بَيْنَكُمْ وَضَلَّ عَنكُم مَّا كُنتُمْ تَزْعُمُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú ẹ ti wá bá wa ní ìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí A ṣe ṣẹ̀dá yín nígbà àkọ́kọ́. Ẹ sì ti fi ohun tí A fún yín (nínú ọrọ̀ ayé) sílẹ̀ sí ẹ̀yìn yín. A ò mà rí àwọn olùṣìpẹ̀ yín pẹ̀lú yín, àwọn tí ẹ sọ láì ní ẹ̀rí pé dájúdájú láààrin yín àwọn ni akẹgbẹ́ (fún Allāhu). Dájúdájú àṣepọ̀ ààrin yín ti já pátápátá. Àti pé ohun tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn (láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ lórí ìṣìpẹ̀ wọn) sì di òfo mọ yín lọ́wọ́.[1]