قُلْ أَنَدْعُوا۟ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُنَا وَلَا يَضُرُّنَا وَنُرَدُّ عَلَىٰٓ أَعْقَابِنَا بَعْدَ إِذْ هَدَىٰنَا ٱللَّهُ كَٱلَّذِى ٱسْتَهْوَتْهُ ٱلشَّيَٰطِينُ فِى ٱلْأَرْضِ حَيْرَانَ لَهُۥٓ أَصْحَٰبٌ يَدْعُونَهُۥٓ إِلَى ٱلْهُدَى ٱئْتِنَا قُلْ إِنَّ هُدَى ٱللَّهِ هُوَ ٱلْهُدَىٰ وَأُمِرْنَا لِنُسْلِمَ لِرَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ṣé a óò máa pè lẹ́yìn Allāhu, ohun tí kò lè ṣe wá ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá wa; (ṣé) kí wọ́n tún dá wa padà sí ẹsẹ̀-àárọ̀ wa lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu ti fi ọ̀nà mọ̀ wá (kí á lè dà) bí ẹni tí àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n tàn lọ (sínú igbó), ó sì ń dààmú kiri lórí ilẹ̀, ó sì kúkú ní àwọn ọ̀rẹ́ (alábàárìn) kan tí wọ́n ń pè é sí ọ̀nà (ilé) pé, “Máa bọ̀ wá bá wa.” (àmọ́ kò gbọ́ mọ́). Sọ pé: “Dájúdájú ìmọ̀nà ti Allāhu (’Islām), òhun ni ìmọ̀nà. Wọ́n sì pa wá láṣẹ pé kí á gba ẹ̀sìn ’Islām nítorí ti Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”