وَإِذَا جَآءَتْهُمْ ءَايَةٌ قَالُوا۟ لَن نُّؤْمِنَ حَتَّىٰ نُؤْتَىٰ مِثْلَ مَآ أُوتِىَ رُسُلُ ٱللَّهِ ٱللَّهُ أَعْلَمُ حَيْثُ يَجْعَلُ رِسَالَتَهُۥ سَيُصِيبُ ٱلَّذِينَ أَجْرَمُوا۟ صَغَارٌ عِندَ ٱللَّهِ وَعَذَابٌ شَدِيدٌۢ بِمَا كَانُوا۟ يَمْكُرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí āyah kan bá sì dé bá wọn, wọ́n á wí pé: “Àwa kò níí gbà á gbọ́ títí di ìgbà tí wọ́n bá tó fún àwa náà ní irú ohun tí wọ́n fún àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu.” Allāhu ló nímọ̀ jùlọ nípa ibi tí Ó ń fí iṣẹ́-rírán Rẹ̀ sí.[1] Láìpẹ́ ìyẹpẹrẹ àti ìyà líle láti ọ̀dọ̀ Allāhu yóò dé bá àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ nítorí ohun tí wọ́n ń dá léte.