أَوْ كَظُلُمَٰتٍ فِى بَحْرٍ لُّجِّىٍّ يَغْشَىٰهُ مَوْجٌ مِّن فَوْقِهِۦ مَوْجٌ مِّن فَوْقِهِۦ سَحَابٌ ظُلُمَٰتٌۢ بَعْضُهَا فَوْقَ بَعْضٍ إِذَآ أَخْرَجَ يَدَهُۥ لَمْ يَكَدْ يَرَىٰهَا وَمَن لَّمْ يَجْعَلِ ٱللَّهُ لَهُۥ نُورًا فَمَا لَهُۥ مِن نُّورٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí (iṣẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́) dà bí àwọn òkùnkùn kan nínú ibúdò jíjìn, tí ìgbì omi ń bò ó mọ́lẹ̀, tí ìgbì omi mìíràn tún wà ní òkè rẹ̀, tí ẹ̀ṣújò sì wà ní òkè rẹ̀; àwọn òkùnkùn biribiri tí apá kan wọ́n wà lórí apá kan (nìyí). Nígbà tí ó bá nawọ́ ara rẹ̀ jáde, kò ní fẹ́ẹ̀ rí i. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu kò bá fún ní ìmọ́lẹ̀, kò lè sí ìmọ́lẹ̀ kan fún un.