لِلْفُقَرَآءِ ٱلَّذِينَ أُحْصِرُوا۟ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ لَا يَسْتَطِيعُونَ ضَرْبًا فِى ٱلْأَرْضِ يَحْسَبُهُمُ ٱلْجَاهِلُ أَغْنِيَآءَ مِنَ ٱلتَّعَفُّفِ تَعْرِفُهُم بِسِيمَٰهُمْ لَا يَسْـَٔلُونَ ٱلنَّاسَ إِلْحَافًا وَمَا تُنفِقُوا۟ مِنْ خَيْرٍ فَإِنَّ ٱللَّهَ بِهِۦ عَلِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Ẹ tọrẹ) fún àwọn aláìní tí wọ́n sé (ara wọn mọ́nú mọ́sálásí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nítorí kí wọ́n lè máa jagun) sí ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ààbò ẹ̀sìn). Wọn kò sì lágbára lílọ-bíbọ̀ lórí ilẹ̀ (fún òkòwò ṣíṣe). Ẹni tí kò mọ̀ wọ́n máa kà wọ́n kún ọlọ́rọ̀ látara àìṣagbe. O máa mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Wọn kò níí tọrọ n̄ǹkan lọ́wọ́ ènìyàn lemọ́lemọ́.[1] Ohunkóhun tí ẹ bá ná ní ohun rere, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀.