caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-A'raaf, ẹsẹ 176

Mecca · revelation order 39 · 7:176

وَلَوْ شِئْنَا لَرَفَعْنَٰهُ بِهَا وَلَٰكِنَّهُۥٓ أَخْلَدَ إِلَى ٱلْأَرْضِ وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ فَمَثَلُهُۥ كَمَثَلِ ٱلْكَلْبِ إِن تَحْمِلْ عَلَيْهِ يَلْهَثْ أَوْ تَتْرُكْهُ يَلْهَث ذَّٰلِكَ مَثَلُ ٱلْقَوْمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُوا۟ بِـَٔايَٰتِنَا فَٱقْصُصِ ٱلْقَصَصَ لَعَلَّهُمْ يَتَفَكَّرُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀti pé tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fi (ìmọ̀ nípa àwọn āyah Wa) ṣàgbéga fún un. Ṣùgbọ́n ó wayé mọ́yà. Ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀. Nítorí náà, àfiwé rẹ̀ dà bí ajá. Tí o bá lé e síwájú, ó máa yọ ahọ́n síta. Tí o bá sì fi sílẹ̀, ó tún máa yọ ahọ́n síta. Ìyẹn ni àfiwé ìjọ tó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Sọ ìtàn náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70