caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-A'raaf, ẹsẹ 158

Mecca · revelation order 39 · 7:158

قُلْ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنِّى رَسُولُ ٱللَّهِ إِلَيْكُمْ جَمِيعًا ٱلَّذِى لَهُۥ مُلْكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ يُحْىِۦ وَيُمِيتُ فَـَٔامِنُوا۟ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِ ٱلنَّبِىِّ ٱلْأُمِّىِّ ٱلَّذِى يُؤْمِنُ بِٱللَّهِ وَكَلِمَٰتِهِۦ وَٱتَّبِعُوهُ لَعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelSọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu sí gbogbo yín pátápátá. (Allāhu) Ẹni tó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ẹ tẹ̀lé e nítorí kí ẹ lè mọ̀nà.”
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70