وَكَتَبْنَا لَهُۥ فِى ٱلْأَلْوَاحِ مِن كُلِّ شَىْءٍ مَّوْعِظَةً وَتَفْصِيلًا لِّكُلِّ شَىْءٍ فَخُذْهَا بِقُوَّةٍ وَأْمُرْ قَوْمَكَ يَأْخُذُوا۟ بِأَحْسَنِهَا سَأُو۟رِيكُمْ دَارَ ٱلْفَٰسِقِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì kọ gbogbo n̄ǹkan fún un sínú àwọn wàláà. (Ó jẹ́) wáàsí àti àlàyé ọ̀rọ̀ fún gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ṣàmúlò rẹ̀ dáradára. Kí o sì pa ìjọ rẹ láṣẹ pé kí wọ́n ṣàmúlò n̄ǹkan tó dára jùlọ nínú rẹ̀. Èmi yóò fi ilé àwọn arúfin hàn yín.[1]