قَالَ فَإِنَّهَا مُحَرَّمَةٌ عَلَيْهِمْ أَرْبَعِينَ سَنَةً يَتِيهُونَ فِى ٱلْأَرْضِ فَلَا تَأْسَ عَلَى ٱلْقَوْمِ ٱلْفَٰسِقِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ó ti di èèwọ̀ fún wọn (láti wọnú ìlú náà) fún ogójì ọdún tí wọn yóò fi rin àrìnnù lórí ilẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”[1]