وَكَذَٰلِكَ أَوْحَيْنَآ إِلَيْكَ رُوحًا مِّنْ أَمْرِنَا مَا كُنتَ تَدْرِى مَا ٱلْكِتَٰبُ وَلَا ٱلْإِيمَٰنُ وَلَٰكِن جَعَلْنَٰهُ نُورًا نَّهْدِى بِهِۦ مَن نَّشَآءُ مِنْ عِبَادِنَا وَإِنَّكَ لَتَهْدِىٓ إِلَىٰ صِرَٰطٍ مُّسْتَقِيمٍ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáyẹn sì ni A ṣe fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ nínú àṣẹ Wa. Ìwọ kò mọ kí ni Tírà àti ìgbàgbọ́ òdodo tẹ́lẹ̀ (ṣíwájú ìmísí náà),[1] ṣùgbọ́n A ṣe ìmísí náà ní ìmọ́lẹ̀ kan tí À ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí A bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Dájúdájú ìwọ ń pèpè sí ọ̀nà tààrà (’Islām).²