caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Baqara, ẹsẹ 246

Medina · revelation order 87 · 2:246

أَلَمْ تَرَ إِلَى ٱلْمَلَإِ مِنۢ بَنِىٓ إِسْرَٰٓءِيلَ مِنۢ بَعْدِ مُوسَىٰٓ إِذْ قَالُوا۟ لِنَبِىٍّ لَّهُمُ ٱبْعَثْ لَنَا مَلِكًا نُّقَٰتِلْ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ قَالَ هَلْ عَسَيْتُمْ إِن كُتِبَ عَلَيْكُمُ ٱلْقِتَالُ أَلَّا تُقَٰتِلُوا۟ قَالُوا۟ وَمَا لَنَآ أَلَّا نُقَٰتِلَ فِى سَبِيلِ ٱللَّهِ وَقَدْ أُخْرِجْنَا مِن دِيَٰرِنَا وَأَبْنَآئِنَا فَلَمَّا كُتِبَ عَلَيْهِمُ ٱلْقِتَالُ تَوَلَّوْا۟ إِلَّا قَلِيلًا مِّنْهُمْ وَٱللَّهُ عَلِيمٌۢ بِٱلظَّٰلِمِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelṢé ìwọ kò wòye sí àwọn aṣíwájú nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl, lẹ́yìn (ìgbà Ànábì) Mūsā? Nígbà tí wọ́n sọ fún Ànábì tiwọn pé: “Yan ọba kan fún wa, kí á lọ jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu.” Ó sọ pé: “Ṣebí ó ṣeé ṣe pé tí wọ́n bá ṣe ogun jíjà ní ọ̀ran-anyàn le yín lórí tán, ẹ ò kúkú níí jagun?” Wọ́n wí pé: “Kí ni ó máa dí wa lọ́wọ́ láti jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu? Wọ́n kúkú ti lé àwa àti àwọn ọmọ wa jáde kúrò nínú ilé wa!” Àmọ́ nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí tán, wọ́n pẹ̀yìn dà àfi díẹ̀ nínú wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70