وَكَذَٰلِكَ أَعْثَرْنَا عَلَيْهِمْ لِيَعْلَمُوٓا۟ أَنَّ وَعْدَ ٱللَّهِ حَقٌّ وَأَنَّ ٱلسَّاعَةَ لَا رَيْبَ فِيهَآ إِذْ يَتَنَٰزَعُونَ بَيْنَهُمْ أَمْرَهُمْ فَقَالُوا۟ ٱبْنُوا۟ عَلَيْهِم بُنْيَٰنًا رَّبُّهُمْ أَعْلَمُ بِهِمْ قَالَ ٱلَّذِينَ غَلَبُوا۟ عَلَىٰٓ أَمْرِهِمْ لَنَتَّخِذَنَّ عَلَيْهِم مَّسْجِدًا
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelBáyẹn ni A ṣe jẹ́ kí àwọn ènìyàn rí wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Àti pé dájúdájú Àkókò náà kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Rántí (nígbà tí àwọn ènìyàn) ń ṣe àríyànjiyàn láààrin ara wọn nípa ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n sọ pé: “Ẹ mọ ilé kan lé wọn lórí. Olúwa wọn lÓ nímọ̀ jùlọ nípa wọn.” Àwọn tó borí lórí ọ̀rọ̀ wọn sì wí pé: “Dájúdájú a máa sọ orí àpáta wọn di mọ́sálásí.”[1]