وَمِنَ ٱلْأَعْرَابِ مَن يُؤْمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ وَيَتَّخِذُ مَا يُنفِقُ قُرُبَٰتٍ عِندَ ٱللَّهِ وَصَلَوَٰتِ ٱلرَّسُولِ أَلَآ إِنَّهَا قُرْبَةٌ لَّهُمْ سَيُدْخِلُهُمُ ٱللَّهُ فِى رَحْمَتِهِۦٓ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ tún wà nínú àwọn Lárúbáwá oko, ẹni tí ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì sọ ìnáwó tó ń ná (fún ẹ̀sìn) di ohun tí ó máa mú wọn súnmọ́ Allāhu àti ohun tí ó máa mú wọn gba àdùá lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́. Kíyè sí i, dájúdájú ó máa mú wọn súnmọ́ Allāhu. Allāhu yó sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.