وَإِذْ يَمْكُرُ بِكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لِيُثْبِتُوكَ أَوْ يَقْتُلُوكَ أَوْ يُخْرِجُوكَ وَيَمْكُرُونَ وَيَمْكُرُ ٱللَّهُ وَٱللَّهُ خَيْرُ ٱلْمَٰكِرِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(Rántí) nígbà tí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń déte sí ọ láti dè ọ́ mọ́lẹ̀ tàbí láti pa ọ́ tàbí láti yọ ọ́ kúrò nínú ìlú; wọ́n ń déte, Allāhu sì ń déte. Allāhu sì lóore jùlọ nínú àwọn adéte.[1]