قَدِ ٱفْتَرَيْنَا عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا إِنْ عُدْنَا فِى مِلَّتِكُم بَعْدَ إِذْ نَجَّىٰنَا ٱللَّهُ مِنْهَا وَمَا يَكُونُ لَنَآ أَن نَّعُودَ فِيهَآ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ رَبُّنَا وَسِعَ رَبُّنَا كُلَّ شَىْءٍ عِلْمًا عَلَى ٱللَّهِ تَوَكَّلْنَا رَبَّنَا ٱفْتَحْ بَيْنَنَا وَبَيْنَ قَوْمِنَا بِٱلْحَقِّ وَأَنتَ خَيْرُ ٱلْفَٰتِحِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelDájúdájú a ti dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tí a bá fi lè padà sínú ẹ̀sìn yín lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu ti yọ wá kúrò nínú rẹ̀. Àti pé kò lẹ́tọ̀ọ́ fún wa láti padà sínú rẹ̀ àfi tí Allāhu Olúwa wa bá fẹ́. Olúwa wa fi ìmọ̀ rọkiriká gbogbo n̄ǹkan. Allāhu l’a gbáralé. Olúwa wa, ṣe ìdájọ́ láààrin àwa àti ìjọ wa pẹ̀lú òdodo, Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.”