caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-A'raaf, ẹsẹ 85

Mecca · revelation order 39 · 7:85

وَإِلَىٰ مَدْيَنَ أَخَاهُمْ شُعَيْبًا قَالَ يَٰقَوْمِ ٱعْبُدُوا۟ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُۥ قَدْ جَآءَتْكُم بَيِّنَةٌ مِّن رَّبِّكُمْ فَأَوْفُوا۟ ٱلْكَيْلَ وَٱلْمِيزَانَ وَلَا تَبْخَسُوا۟ ٱلنَّاسَ أَشْيَآءَهُمْ وَلَا تُفْسِدُوا۟ فِى ٱلْأَرْضِ بَعْدَ إِصْلَٰحِهَا ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael(A tún rán ẹnì kan) sí àwọn ará Mọdyan, arákùnrin wọn, Ṣu‘aeb. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú ẹ̀rí tó yanjú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Ẹ sì má ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ lẹ́yìn àtúnṣe rẹ̀. Ìyẹn sì lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70