caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-A'raaf, ẹsẹ 160

Mecca · revelation order 39 · 7:160

وَقَطَّعْنَٰهُمُ ٱثْنَتَىْ عَشْرَةَ أَسْبَاطًا أُمَمًا وَأَوْحَيْنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ إِذِ ٱسْتَسْقَىٰهُ قَوْمُهُۥٓ أَنِ ٱضْرِب بِّعَصَاكَ ٱلْحَجَرَ فَٱنۢبَجَسَتْ مِنْهُ ٱثْنَتَا عَشْرَةَ عَيْنًا قَدْ عَلِمَ كُلُّ أُنَاسٍ مَّشْرَبَهُمْ وَظَلَّلْنَا عَلَيْهِمُ ٱلْغَمَٰمَ وَأَنزَلْنَا عَلَيْهِمُ ٱلْمَنَّ وَٱلسَّلْوَىٰ كُلُوا۟ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقْنَٰكُمْ وَمَا ظَلَمُونَا وَلَٰكِن كَانُوٓا۟ أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelA sì pín wọn sí igun méjìlá (igun kọ̀ọ̀kan sì ní) ìran àti ìjọ. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ wá omi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Fi ọ̀pá rẹ na àpáta.” (Ó ṣe bẹ́ẹ̀) orísun omi méjìlá sì ṣẹ́yọ lára rẹ̀. Àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan sì ti dá ibùmu wọn mọ̀. A tún fi ẹ̀ṣújò ṣe ibòji fún wọn. A sọ (ohun mímu) mọ́nnù[1] àti (ohun jíjẹ) salwā² kalẹ̀ fun wọ́n. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fún yín. Wọn kò sì ṣe àbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70