وَلَا تَطْرُدِ ٱلَّذِينَ يَدْعُونَ رَبَّهُم بِٱلْغَدَوٰةِ وَٱلْعَشِىِّ يُرِيدُونَ وَجْهَهُۥ مَا عَلَيْكَ مِنْ حِسَابِهِم مِّن شَىْءٍ وَمَا مِنْ حِسَابِكَ عَلَيْهِم مِّن شَىْءٍ فَتَطْرُدَهُمْ فَتَكُونَ مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelMá ṣe lé àwọn tó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́ dànù; wọ́n ń fẹ́ Ojú rere Rẹ̀ ni. Ìṣirò-iṣẹ́ wọn kò sí ní ọrùn rẹ ní ọ̀nà kan kan. Kò sì sí ìṣirò-iṣẹ́ tìrẹ náà ní ọrùn wọn ní ọ̀nà kan kan. Tí o bá lé wọn dànù, o sì máa wà nínú àwọn alábòsí.[1]