وَلَا تَأْكُلُوا۟ مِمَّا لَمْ يُذْكَرِ ٱسْمُ ٱللَّهِ عَلَيْهِ وَإِنَّهُۥ لَفِسْقٌ وَإِنَّ ٱلشَّيَٰطِينَ لَيُوحُونَ إِلَىٰٓ أَوْلِيَآئِهِمْ لِيُجَٰدِلُوكُمْ وَإِنْ أَطَعْتُمُوهُمْ إِنَّكُمْ لَمُشْرِكُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelẸ̀yin kò sì gbọdọ̀ jẹ nínú ohun tí wọn kò fi orúkọ Allāhu pa.[1] Dájúdájú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Àti pé dájúdájú àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n, wọn yóò máa fi ọ̀rọ̀ irọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ẹni wọn, nítorí kí wọ́n lè takò yín. Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé wọn, dájúdájú ẹ ti di ọ̀ṣẹbọ.