وَلْيَسْتَعْفِفِ ٱلَّذِينَ لَا يَجِدُونَ نِكَاحًا حَتَّىٰ يُغْنِيَهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضْلِهِۦ وَٱلَّذِينَ يَبْتَغُونَ ٱلْكِتَٰبَ مِمَّا مَلَكَتْ أَيْمَٰنُكُمْ فَكَاتِبُوهُمْ إِنْ عَلِمْتُمْ فِيهِمْ خَيْرًا وَءَاتُوهُم مِّن مَّالِ ٱللَّهِ ٱلَّذِىٓ ءَاتَىٰكُمْ وَلَا تُكْرِهُوا۟ فَتَيَٰتِكُمْ عَلَى ٱلْبِغَآءِ إِنْ أَرَدْنَ تَحَصُّنًا لِّتَبْتَغُوا۟ عَرَضَ ٱلْحَيَوٰةِ ٱلدُّنْيَا وَمَن يُكْرِههُّنَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ مِنۢ بَعْدِ إِكْرَٰهِهِنَّ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelKí àwọn tí kò ní (ìkápá) ìgbéyàwó mú ojú wọn kúrò níbi ìṣekúṣe títí Allāhu yóò fi rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.[1] Àwọn tó ń wá ìwé òmìnira nínú àwọn ẹrú yín, ẹ kọ ìwé òmìnira fún wọn tí ẹ bá mọ ohun rere nípa wọn. Kí ẹ sì fún wọn nínú dúkìá Allāhu tí Ó fún yín. (Nítorí dúkìá ayé tí ẹ̀ ń wá), ẹ má ṣe jẹ àwọn ẹrúbìnrin yín nípá láti lọ ṣe sìná, tí wọ́n bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ wọn níbi ìṣekúṣe.² Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ wọ́n nípá, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ wọ́n nípá.³