وَٱلْبُدْنَ جَعَلْنَٰهَا لَكُم مِّن شَعَٰٓئِرِ ٱللَّهِ لَكُمْ فِيهَا خَيْرٌ فَٱذْكُرُوا۟ ٱسْمَ ٱللَّهِ عَلَيْهَا صَوَآفَّ فَإِذَا وَجَبَتْ جُنُوبُهَا فَكُلُوا۟ مِنْهَا وَأَطْعِمُوا۟ ٱلْقَانِعَ وَٱلْمُعْتَرَّ كَذَٰلِكَ سَخَّرْنَٰهَا لَكُمْ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀwọn ràkúnmí, A ṣe wọ́n nínú àwọn n̄ǹkan àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu fún yín. Oore wà lára wọn fún yín. Nítorí náà, ẹ dárúkọ Allāhu lé wọn lórí (kí ẹ sì gún wọn) ní ìdúró. Nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, ẹ jẹ nínú rẹ̀. Ẹ fi bọ́ ẹni tó ní ìtẹ́lọ́rùn àti atọrọjẹ. Báyẹn ni A ṣe rọ̀ wọ́n fún yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).