caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Baqara, ẹsẹ 285

Medina · revelation order 87 · 2:285

ءَامَنَ ٱلرَّسُولُ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيْهِ مِن رَّبِّهِۦ وَٱلْمُؤْمِنُونَ كُلٌّ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَمَلَٰٓئِكَتِهِۦ وَكُتُبِهِۦ وَرُسُلِهِۦ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِّن رُّسُلِهِۦ وَقَالُوا۟ سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا غُفْرَانَكَ رَبَّنَا وَإِلَيْكَ ٱلْمَصِيرُ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÒjíṣẹ́ náà - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a - gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (gbàgbọ́ nínú rẹ̀). Ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀.[1] A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ). À ń tọrọ àforíjìn Rẹ, Olúwa wa. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.”
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70