caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Baqara, ẹsẹ 248

Medina · revelation order 87 · 2:248

وَقَالَ لَهُمْ نَبِيُّهُمْ إِنَّ ءَايَةَ مُلْكِهِۦٓ أَن يَأْتِيَكُمُ ٱلتَّابُوتُ فِيهِ سَكِينَةٌ مِّن رَّبِّكُمْ وَبَقِيَّةٌ مِّمَّا تَرَكَ ءَالُ مُوسَىٰ وَءَالُ هَٰرُونَ تَحْمِلُهُ ٱلْمَلَٰٓئِكَةُ إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَـَٔايَةً لَّكُمْ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÀnábì wọn tún sọ fún wọn pé: “Dájúdájú àmì ìjọba rẹ̀ ni pé, àpótí yóò wá ba yín. N̄ǹkan ìfàyàbalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti ohun tó ṣẹ́kù nínú ohun tí àwọn ènìyàn (Ànábì) Mūsā àti ènìyàn (Ànábì) Hārūn fi sílẹ̀ ń bẹ nínú àpótí náà. Àwọn mọlāika máa rù ú wá (ba yín). Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún yín, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70