caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Baqara, ẹsẹ 232

Medina · revelation order 87 · 2:232

وَإِذَا طَلَّقْتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَبَلَغْنَ أَجَلَهُنَّ فَلَا تَعْضُلُوهُنَّ أَن يَنكِحْنَ أَزْوَٰجَهُنَّ إِذَا تَرَٰضَوْا۟ بَيْنَهُم بِٱلْمَعْرُوفِ ذَٰلِكَ يُوعَظُ بِهِۦ مَن كَانَ مِنكُمْ يُؤْمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلْيَوْمِ ٱلْـَٔاخِرِ ذَٰلِكُمْ أَزْكَىٰ لَكُمْ وَأَطْهَرُ وَٱللَّهُ يَعْلَمُ وَأَنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelNígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí wọ́n sì parí àsìkò (opó) wọn, ẹ má ṣe dí wọn lọ́wọ́ láti fẹ́ ọkọ wọn (padà), nígbà tí wọ́n bá jọ yọ́nú síra wọn (tí wọ́n sì gba) ọ̀nà tó dára. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni nínú yín, tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn l’ó fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Ó sì tún ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn yín) jùlọ. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.[1]
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70