caseriqÌwádìí ìtumọ̀ nínú Al-Ƙur'ān

Súrà Al-Baqara, ẹsẹ 133

Medina · revelation order 87 · 2:133

أَمْ كُنتُمْ شُهَدَآءَ إِذْ حَضَرَ يَعْقُوبَ ٱلْمَوْتُ إِذْ قَالَ لِبَنِيهِ مَا تَعْبُدُونَ مِنۢ بَعْدِى قَالُوا۟ نَعْبُدُ إِلَٰهَكَ وَإِلَٰهَ ءَابَآئِكَ إِبْرَٰهِـۧمَ وَإِسْمَٰعِيلَ وَإِسْحَٰقَ إِلَٰهًا وَٰحِدًا وَنَحْنُ لَهُۥ مُسْلِمُونَ

Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelTàbí ẹ̀yín jẹ́ ẹlẹ́rìí nígbà tí ikú dé bá (Ànábì) Ya‘ƙūb? Nígbà tí ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Kí ni ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn (ikú) mi?” Wọ́n sọ pé: “Àwa yó máa jọ́sìn fún Ọlọ́hun rẹ àti Ọlọ́hun àwọn bàbá rẹ, (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl àti ’Ishāƙ, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
Looking for a topic? Try the meaning search — your question is scanned across all 6,236 verses.
Èdè — 70