قَالَ لَا يَأْتِيكُمَا طَعَامٌ تُرْزَقَانِهِۦٓ إِلَّا نَبَّأْتُكُمَا بِتَأْوِيلِهِۦ قَبْلَ أَن يَأْتِيَكُمَا ذَٰلِكُمَا مِمَّا عَلَّمَنِى رَبِّىٓ إِنِّى تَرَكْتُ مِلَّةَ قَوْمٍ لَّا يُؤْمِنُونَ بِٱللَّهِ وَهُم بِٱلْـَٔاخِرَةِ هُمْ كَٰفِرُونَ
Yoruba Translation - Abu Rahimah MikaelÓ sọ pé: “Oúnjẹ tí wọ́n ń pèsè fún ẹ̀yin méjèèjì kò ní tí ì dé ba yín, àfi kí èmi ti sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún ẹ̀yin méjèèjì ṣíwájú kí ó tó dé ba yín. Ìyẹn wà nínú n̄ǹkan tí Olúwa mi fi mọ̀ mí. Dájúdájú èmi fi ẹ̀sìn àwọn ènìyàn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu sílẹ̀. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.